Orisabunmi: Ta ni Gbajúgbajà òṣèré tíátà Yorùbá, Orisabunmi tó jáde láyé?

Oríṣun àwòrán, Instagram/toyosiadesanya
Gbajugbaja agba oserebinrin, Folake Orisabunmi ti jade laye.Owurọ Ọjọru ni awọn akẹẹgbẹ rẹ kan bi Toyosi Adesanya bẹrẹ si ni ṣe idaro iku rẹ lori ayelujara Instagram wọn.A kò ti fidi igba to ku tabi nkan to pa a mulẹ lasiko ti a kọ iroyin yii, sugbọn ao ma mu ẹkunrẹrẹ iroyin wa fun yin to ba se n tẹ wa lọwọ.
Iroyin sọ pe ẹni ọgọta ọdun ni Oriṣabunmi ki o to jade laye.
Ta ni Fọlakẹ Arẹmu ti ọpọ mọ si Oriṣabunmi?
Ọjọ Kẹwaa, oṣu Kẹwaa, ọdun 1960 ni wọn bi nilu Ola nipinlẹ Kwara.
Orukọ abisọ rẹ ni Fọlakẹ Arẹmu ṣugbọn Oriṣabunmi ni ọpọ eeyan mọ si.
Iya orisa, tabi ajẹ funfun ni orukọ ti ọpọ miran tun maa n pe e nitori awọn ipa ti o maa n ko ninu ere itage ati sinima.
O lọ si ileewe alakọbẹrẹ ati Girama ni ilu Eruku nijọba ibilẹ Ekiti nipinlẹ Kwara.
Ọkan lara awọn iyawo agba oserekunrin, Jimoh Aliu, to doloogbe lọdun 2020 ni Orisabunmi. Sugbọn, àwọn mejeeji ti kọ ara wọn silẹ saaju iku wọn.
Lati nkan bi ọdun 1980 ni Orisabunmi ti jẹ gbajugbaja fun ipa Yeye Ọsun to ma n ko ninu ere.
Ọkọ rẹ nigba kan, Jimoh Aliu lo sawari rẹ gẹgẹ bi oṣere lasiko to fi n ṣe iṣẹ olukọ nipinlẹ Kwara.
Àwọn ere to jẹ ti Aliu 'Aworo' si lo fi bẹrẹ ere sisẹ ni pataki julọ, ere ori itage 'Ori ma binu' lo fi bẹrẹ isẹ ere ṣíṣe, ṣugbọn ipa Orisabunmi to ko ninu ere Arelu ni nkan bi ọdun 1980 lo sọ ọ di gbajugbaja.
Lootọ, Oloogbe Jimoh Aliu lo kọ nisẹ ere ṣíṣe, sugbọn iroyin sọ pe bo ṣe mọ ọfọ pipa ko sẹyin bi wọn ṣe tọ ọ dagba. Idi ni pe idile eleegun ni wọn ti bi; Iya rẹ si jẹ ọmọ ile Ọlọsun.
Bi ọdun mejilelogoji ni Orisabunmi fi sisẹ ere ṣíṣe ki iku to o mu lọ.
Oun fúnra rẹ gbe awọn sinima bi Atupa Imole, Ase Ilu, ati Tani Ọ jáde.
Yatọ si iṣẹ olukọ, Orisabunmi tun sisẹ akọ̀wé ni ileesẹ Sunny Radio nipinlẹ Kwara.
A n se akojọpọ ẹkunrẹrẹ iroyin yajoyajo lọwọ, a o maa gbe ẹkunrẹrẹ iroyin naa sori atẹ iroyin wa laipẹ. Ẹ jọwọ, ẹ tun oju opo iroyin yi yẹwo, ki ẹ lee ri ẹkunrẹrẹ iroyin ọtun laipẹ.












