Coronavirus Update: Gomina Sanwo-Olu sún ọjọ́ "ṣiṣẹ́ láti ilé" síwájú fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, Twitter/gbenga omotoso

Ijọba ipinlẹ Eko ti pàṣẹ fawọn oṣiṣẹ ìjọba ti wọn ko to ipele Kẹrinla lati tubọ maa ṣiṣẹ lati ile wọn lọnà ati dẹkùn itankalẹ aarun Covid-19.

Labẹ aṣẹ yi, ile ni gbogbo awọn ti ko ba to ipele yi yoo ti ma ṣiṣe di ọjọ kini oṣu Keji ọdun 2021.

Atẹjade ti olori awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Eko Hakeem Muri Okunnu fi sita salaye pe aṣẹ igbele yi ko kan awọn ti o n ṣiṣẹ to se pataki.

"Gomina Babajide Sanwo-Olu ti buwọlu afikun ọjọ t'awọn oṣiṣẹ ìjọba Eko yoo fi ṣe iṣẹ lati ile fawọn ti ko to ipele Kẹrinla"

"Gomina wa rọ awọn oṣiṣẹ lat da aaboo bo ara wọn nipa bíbọwọ fún ilana idaabobo ti ijọba gbe kalẹ"

Àkọlé fídíò, Florence Onwuasoanya: Mo jẹ́ àsèjẹ, mo mu àgbo tí kò ṣe e fẹnu sọ kí ń lè gbé ọmọ jó ṣùgbọ

Muri-Okunola tun tẹsiwaju pe ki wọn máa tẹlé àtẹ eto iṣẹ tó wà nilẹ ki gbogbo nkan baa le máa lọ ní irọwọrọsẹ lawọn ileesẹ ìjọba nipinlẹ ọhun.

Ìpínlẹ̀ Oyo, Eko àti Ogun fọnmú lórí ìlànà pínpín abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19

Ìpínlẹ̀ Eko, Oyo àti Ogun ní abẹ́rẹ́ covid-19 tí yóò kàn wọ́n kéré, wọ́n fẹ́ ra ti wọn.

Abẹrẹ Ajesara

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Covid-19 vaccine: Ìjọba Oyo, Eko fẹ́ ra abẹ́rẹ́ àjẹsára fún aráàlú

Ijọba ipinlẹ Eko, Ogun ati Oyo wa lara awọn ipinlẹ to bu ẹnu ẹtẹ lu bi ijọba apapọ ṣe pin abẹrẹ ajẹsara Covid-19 fawọn ipinlẹ ni Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Akọsilẹ ajọ NPHCDA to n ri eto abẹrẹ ajẹsara Covid-19 fi sita wa safihan bi yoo se pin abẹrẹ naa fawọn ijọba ipinlẹ.

Abẹrẹ Ajesara

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ilana bi ijọba apapọ se pin abẹrẹajẹsara:

Kano - 3,557 , Lagos - 3,131, Katsina - 2,361, Kaduna - 2,074, Bauchi -1,900, Oyo - 1,848, Rivers - 1,766, Jigawa - 1,712, Niger - 1,558 , Ogun - 1,473.

Sokoto - 1,468, Benue - 1,423, Borno - 1,416, Anambra - 1,379, Kebbi - 1,268, Zamfara - 1,336, Delta - 1,306, Imo - 1,267, Ondo - 1,228, Akwa Ibom -1,161.

Àkọlé fídíò, Africa Eye: Wo ìtàn ìyá kan ìyá kan àtàwọn olè ajọ́mọgbé tó n ta ọmọ ní Kenya

Adamawa - 1,129, Edo - 1,104, Plateau - 1,089, Enugu - 1,088; Osun - 1,032; Kogi - 1,030; Cross River - 1,023; Abia - 955; Gombe - 908; Yobe - 842; Ekiti - 830; Taraba - 830; Kwara - 815; Ebonyi - 747; Bayelsa - 589; FCT - 695, Nasarawa - 661.

Abẹrẹ Ajesara

Ki ni Gomina Seyi Makinde sọ nipa abẹrẹ naa:

Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo sọ pe abẹrẹ ti ijọba apapọ pin fun ipinlẹ Oyo ti kere ju.

Makinde ni ijọba yoo ra abẹrẹ naa fúnra rẹ, ki awọn eeyan ipinlẹ naa le jẹ anfaani abẹrẹ ọhun.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa: Mọ̀ síi nípa ìró afárànma àti agbárànmọ́ fáwẹ́ẹ̀lì Yorùbá

Ipinlẹ Eko iyalẹnu ni ilana pinpin abẹrẹ naa jẹ:

Bakanna, Kọmiṣọna feto iroyin ati aato ni ipinlẹ Eko, Gbenga Omotosho sọ pe, iyalẹnu ni bi ajọ NPHCDA ṣe pin abẹrẹ Coronavirus fawọn ipinlẹ jẹ.

Ọgbẹni Omotosho ni ko si adehun kankan laarin ijọba apapọ ati awọn ipinlẹ lori iye abẹrẹ ti yoo kan ipinlẹ kọọkan, ki ajọ NPHCDA to gbe nọmba ti yoo kan ipinlẹ kọọkan jade.

Kọmiṣọna ni ijọba ipinlẹ yoo ra abẹrẹ ajẹsara Covid-19 tirẹ fawọn eeyan ipinlẹ naa.

Amọ, o ni ipinlẹ Eko ko ní ṣalai gba eyi ti ijọba apapọ pin fun wọn.

Àkọlé fídíò, Nigeria Car Innovator: Olatunde Ibitoye ní ọdún mẹ́ta ní òun fi ṣe ọkọ̀ náà torí ọ̀dá owó

Ipinlẹ Ogun ni ko ye oun bi ijọba se pin iye abẹrẹ to pin fun oun:

Ipinlẹ Ogun ni tiẹ sọ pe, ko gba ibikan ye oun bi ijọba ṣe pin iye abẹrẹ ti yoo kan ipinlẹ kọọkan.

Oludamọran fun Gomina ipinle Ogun lori eto iroyin, Ọgbẹni Remmy Hazzan lo kede bẹẹ.

Hazzan sọ pe ipinlẹ Eko, Ogun ati Olu ilu Naijiria Abuja ti ajakalẹ arun Covid-19 ti ṣọṣẹ julọ, ló yẹ kó lanfaani abẹrẹ ajẹsara Covid-19 ju awọn ipinlẹ to ku lọ.

"Ko tii ye wa nipinlẹ Ogun, idi ti a ko fi gba ju iye abẹrẹ perete ti ajọ NPHCDA pin kan wa lọ," Ọgbẹni Hazzan lo sọ bẹẹ.

Àkọlé fídíò, LASU Best Graduating Student: Wákàtí kan péré ni mo fi ń kàwé lójúmọ́, èmi kìí ṣe igi ìwé

Ẹgbẹ Dokita rọ ijọba lati kọkọ fun awọn osisẹ eleto ilera ni abẹrẹ naa:

Ẹwẹ, ẹgbẹ awọn dokita ni Naijiria, NMA ti rọ ijọba apapọ lati fun awọn oṣiṣẹ eleto ilera lanfaani ati kọkọ gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19.

Aarẹ ẹgbẹ NMA, Ọjọgbọn Innocent Ujah ni, awọn oṣiṣẹ eleto ilera lo n foju wina ajakalẹ arun coronavirus julọ nitori awọn lo n tọju awọn to larun naa nile iwosan.

O fikun ọrọ rẹ pe, ko si ohun to buru níbẹ ti awọn oloṣelu ati awọn to ba ri ọwọ họri ba lọ gba abẹrẹ naa loke okun.

Awọn ero inu bọọsi BRT ni Eko

Oríṣun àwòrán, @didacus_dee

Kii ṣe iroyin tuntun pe itankalẹ arun Covid-19 ti bẹrẹ fun igbakeji ni Naijiria.

Ṣugbọn o seni laanu pe ọpọlọpọ araalu ni ko tẹle ilana idaboobo lọwọ arun naa, bo tilẹ jẹ pe lojoojumọ ni ijọba ati awọn alaṣẹ eto ilera n polongo pe ka tẹle ofin itakete sira ẹni.

Lara awọn akiyesi wa, paapaa nipinlẹ Eko ni pe, awọn ọkọ ero n ko ero kun inu ọkọ wọn lai bọwọ fun ilana arun Coronavirus.

Ṣaaju nigba ti arun naa kọkọ gbalẹ, ijọba paṣẹ fun awakọ ero lati din ero wọn ku, ki wọn o si ri daju pe awọn ero naa wọ ibomu.

Ṣugbọn lasiko yii, ko wọpọ lati ri awọn eero ọkọ to wọ ibomu, bẹẹ ni awọn awakọ naa n ko ọpọ ero laisi titakete sira ẹni.

Àkọlé fídíò, Ṣé lóòtọ́ọ́ ni pé ìtọ̀ àti imí màálù le wo ààrùn coronavirus?

Ta lo ni ẹbi iwa yii, ṣe ijọba ni tabi araalu tabi awọn ọlọkọ ero?

Lori eyi, Kọmisana fun eto iroyin nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Gbenga Omotoso sọ fun BBC pe, gbogbo igba ni ijọba n kilọ fun awọn awakọ yii, to si tun n ba awọn olori wọn ṣe ipade loore-koore, nitori ki wọn o le maa tẹle ilana Covid-19.

O ni "Ọkọ meji ni ọwọ ti tẹ, ti ijọba si ti sọ fun awọn naa pe, o ṣe e ṣe ki wọn o padanu iwe irinna wọn gẹgẹ bi awakọ, ti wọn ba tun kọ lati tẹle ofin ijọba lori Coronavirus."

Awọn ero inu bọọsi BRT ni Eko

Oríṣun àwòrán, @adelajaniyi

O ni awọn awakọ naa lo kọ lati gbọran si aṣẹ ijọba.

O ṣalaye pe ko rọrun fun ijọba lati gbe igbesẹ to le lori ọrọ naa, nitori pe ọpọ eeyan lo tun n bu ijọba fun bi awọn agbofinro ṣe n ko awọn eeyan kan nile ijo.

"Awọn oṣiṣẹ ilu bi LASTMA ti ijọba n ran lati mu iru awọn awakọ bẹ ẹ, n fi ẹmi wọn wewu ni."

"O yẹ ki awọn araalu naa mọ pe ija yii kii ṣe tijọba nikan."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: