Coronavirus: Bóo ṣe lè sọ iṣẹ́ láti ilé lásìkò "Coro” di ìgbádùn fún ara rẹ

- Author, David Brown
- Role, BBC News
Ọpọlọpọ eeyan lo nilo ọfiisi kan ninu ile wọn fun igba akọkọ lasiko yii.
Awọn mii ti n gọ si ori tabili ile idana tabi ki wọn maa lo ẹrọ ayarabiaṣa lori ibusun wọn eyi ti wọn ti n ṣe fun ọpọlọpọ oṣu bayii.
Amọ koda bi oogun Coronavirus tilẹ yọju, ọpọ ni ko ṣi tii le pada sẹnu iṣẹ wọn lẹkunrẹrẹ.
Ijamba ti arun yii ti ṣe ko ṣee fẹnu sọ, pẹlu iwadii ti Royal Insitute of British Architects ṣe, ọpọlọpọ to n ṣiṣẹ lati ile ni o n fun awọn ni wahala pupọ. Torinaa, ki la le ṣe lati ni inu didun lasiko ṣiṣe iṣẹ lati ile?

- Tan imọlẹ si i -
Lotitọ, ọtọọtọ ni iwa ẹda ṣugbọn onimọ nipa ọpọlọ, Dokita TBS Balamurali ni itansan oorun tohun ti afẹfẹ oloore lati ita ati nini imọlara ohun ti Ọlọrun da dara pupọ fun ilera ọpọlọ rẹ.
Itansan oorun maa mu ọpọlọ ji pepe. O maa n mu ara eeyan balẹ pẹsẹ a si ran ipo ọkan wọn lọwọ.
Architect Ben Channon ni bo ba ṣeeṣe fun ọ, gbe tabili si ẹgbẹ ferese koo si wọ aṣọ oju feree sẹgbẹ kan koo nu ferese rẹ ko mọ tinu tita.

Bakan naa, lo digi lati fi pese iansan imọlẹ sinu yara too wa koo si kun yara naa ni ọda funfun tabi awọ ina ki imọlẹ le pọ.
O lee mu yara ile alaja loke bo ba ṣeeṣe, wọn maa n ni itansan oorun to pọ gẹgẹ bii yara ti orule rẹ ba ga.
Jina si ariwo.
Dokita Rebecca Dewey ti fasiti Nottingham to jẹ onimọ nipa bi ọpọlọ ṣe n gbọ ohun ni ọpọlọ rẹ maa fi gbogbo igba wa bo ṣe lee da ariwo mọ eyi si maa n ṣe idiwọ lasiko iṣẹ.
Awọn ariwo kan wa to maa n mu aarẹ ba ọpọlọ, apa ibi kan ninu ọpọlọ ni yoo mu u.

Eyi ti yoo si tan de inu ẹjẹ ni yoo ba fa ẹjẹ riru. Gbogbo eyi da lori itumọ ti o ba fun ariwo to n gbọ.
Lilo ẹrọ abanigbọrọ ori foonu lee ṣeranwọ nigbamii too ba si fẹ da kun iranwọ yii. aga onifoomu dẹmu dẹmu, rọọgi kiki ati aṣoọ ferese to nipọn ni gbogbo ohun ti yoo ṣiṣẹ yẹn lati gba ariwo sara.
O ni lati ro nkan too nilo gangan.
Bakan naa, iwadi ti fihan pe ere idaraya loorekoore dara lati gbọn irẹra danu.

Dokita Ratcliff ni aiṣe ere idaraya daadaa lee fa ijamba si ara. Lara rẹ ni koo lo tabili giga koo baa le na duro lawọn ọjọ kọọkan, jokoo lawọn ọjọ mii. O si lee gba isinmi koo rin ṣere kiri nigbamii.
Ṣiṣe ere idaraya loorekoore maa n ran awọn to n ṣiṣẹ nile lọwọ.

- Lo tewe tegbo -
Didin ẹjẹ riru ku, ipaya, irẹra ati ironu oju kan ṣe pataki.
Boo ba ko nkan ọgbin bii ewe atawọn aworan tabi nkan ti Ọlọrun da wọ inu ile rẹ too ti n ṣiṣẹ, o lee ko ipa gidi.
Dokita Ratcliff ni beeyan nkankan, o lee fun ọpọlọ rẹ ni isimi. Lojukoroju kii ṣe lori ayelujara nikan o!

"Awọn to n ṣiṣẹ lati ile ti inu wọn o dun ni lati ronu jinlẹ daadaa pe ibo lo ku si ti wọn fi n ṣaaro ọfiisi.
Ọpọlọpọ nkan to maa n ṣẹlẹ lọfiisi lo ti poora lasiko isede. Ati ri ọrẹ, ojulumọ gan nira lasiko yii ṣugbọn dokita dabaa wiwa eeyan mii too le ba ṣe ere idaraya yoo wulo tori "eeyan ẹlẹran ni wa ti wiwo ẹrọ kọmputa ṣaa tabi Zoom ko to fun ni layọ".
Alaye latẹnu Prina Shah ree.
Illustrations by Prina Shah.












