NIN Registration:Àjọ NIMC sọ pé ọ̀fẹ́ ni gbígba nọ́mbà NIN

Kaadi idanimọ E-Card

Oríṣun àwòrán, Google

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Aimọye igba ni ẹsun ti n jade pe awọn oṣiṣẹ ajọ to n mojuto idanimọ awọn ọmọ Naijiria, National Identity Management Commission, NIMC, ma n gba owo lọwọ awọn to ba fẹ fi orukọ silẹ fun nọmba NIN.

Amọ ni bayii, ajọ NIMC ti fi ikede sita pe ẹṣẹ ni fun ẹnikẹni lati gba iru owo bẹ ẹ, nitori pe ọfẹ ni eto iforukọsilẹ ati gbigba NIN.

Ninu atẹjade kan to fi ori ayelujara Twitter rẹ l'Ọjọbọ, ajọ NIMC sọ pe ẹwọn ọdun meje ni ofin ajọ to n gbogbun ti iwa ibajẹ, ICPC, la kalẹ fun ẹni to ba gba owo lati fi orukọ eeyan silẹ fun nọmba NIN.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Bakan naa ni ajọ naa tun sọ pe araalu le fi ẹjọ iru ẹni bẹ ẹ sun lori nọmba ibaraẹnisọrọ 08157691214 tabi 08157691071.

Yatọ si ipe, o tun le fi imeeli ranṣẹ si [email protected]

Àjọ NIMC ti fún MTN, Glo, 9mobile àti Airtel ní àṣẹ láti bẹ̀rẹ̀ ìforúkọsílẹ̀ fún NIN

Kaadi idanimọ NIN

Oríṣun àwòrán, other

Iroyin tuntun to jade lati ọdọ ajọ to n risi idanimọ lorilẹ-ede Naijiria, NIMC, fi sita ni pe, awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ ti ni aṣẹ lati fi orukọ awọn eeyan silẹ fun nọmba NIN.

Ọga Agba fun bi iṣẹ ṣe n lọ si ni ajọ NIMC, Abdulhamid Umar lo sọ bẹ ẹ fun awọn akọroyin BBC nilu Abuja.

O sọ pe ajọ naa ti kọkọ fun awọn aadọjọ ileeṣẹ aladani ati ti ijọba ni iwe aṣẹ lati ma a fi orukọ awọn eeyan silẹ.

Pẹlu ikede tuntun yii, ẹni to ba fẹ ẹ gba nọmba NIN ti le lọ si ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ MTN, Glo, Airtel, ati 9mobile, lati fi orukọ silẹ, ati gba nọmba naa.

Àjọ NIMC ti gbé ìlànà tuntun jáde fún gbígba NIN lọ́nà ìrọ̀rùn

Kaadi idanimọ NIN ati fọọmu iforukọsilẹ

Oríṣun àwòrán, NIMC

Ajọ to n mojuto eto idanimọ lorilẹede Naijiria, NIMC, tun ti fi awọn ilana tuntun sita lori eto iforukọsilẹ fun gbigba nọmba idanimọ NIN.

Agbẹnusọ ajọ naa, Kayode Adegoke, kede awọn ilana tuntun yii lọjọ Iṣẹgun, ninu atẹjade kan pe ilana kikọkọ fi orukọ silẹ ni ajọ naa yoo ma lo bayii.

O sọ pe ilana tuntun naa jẹ ọna lati ri i pe eto iforukọsilẹ rọrun fun awọn oṣiṣẹ ajọ NIMC ati awọn to fẹ fi orukọ silẹ.

Bawo ni ilana tuntun naa yoo ṣe lọ?

Bẹrẹ lati ọgbọnjọ, oṣu Kejila, ọdun 2020, ẹni to ba fẹ gba nọmba NIN gbọdọ kọkọ lọ si ọfiisi ajọ NIMC to ba sun mọ laarin aago mẹsan owurọ si aago kan ọsan.

Nibẹ ni wọn o ti gba akọsilẹ nipa rẹ, ti wọn o si fun ọ ni ọjọ ti o wa fun iforukọsilẹ fun NIN.

Ajọ NIMC sọ pe nkan ti wọn ba beere ninu iwe akọsilẹ naa nikan ni ki o kọ sibẹ.

Ni kete ti o ba ti de ọfiisi naa, wọn o fun ọ ni nọmba lati to si ori ila, ko ma ba a si idaru-dapọ, ati lati daabo bo awọn eeyan lọwọ Covid-19.

Bakan naa ni wọn tun sọ pe dandan ni wiwọ ibomu fun awọn to fẹ ẹ fi orukọ silẹ.

Wo eyi to súnmọ́ ọ nínú àwọn ibùdó 203 fún ìforúkọsílẹ̀ fún NIN rẹ

Minisita fun ibaraẹnisọrọ ati ọrọ aje ori ayelujara, Ọmọwe Isa Pantami ti buwọlu aṣoju 173, ati ileeṣẹ ijọba ọgbọn lati ma a ṣe iforukọsilẹ gbogbo ẹni to n gbe ni Naijiria lọna to ba ofin mu, fun ajọ National Identity Management Commission (NIMC).

Ikede yii waye lẹyin ti ajọ NIMC fun awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ ni gbedeke ọsẹ meji, lati gbẹsẹ le gbogbo siimu ẹrọ ibaraẹnisọrọ ti ko ba ti ni nọmba NIN ninu akọsilẹ rẹ.

Awọn ibudo ti ijọba fọwọ si fun iforukọ silẹ NIN niyii:

Awọn ileeṣẹ ti NIMC fi ọwọ si

Oríṣun àwòrán, Nimc

Awọn ibudo naa jẹ akojọpọ awọn ileeṣẹ aladani, ti ijọba, ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ, ati awọn ajọ ti kii ṣe ti ijọba.

Awọn ileeṣẹ ti NIMC fi ọwọ si

Oríṣun àwòrán, Nimc

Awọn ileeṣẹ ti NIMC fi ọwọ si

Oríṣun àwòrán, Nimc

Bakan naa ni ko yọ ajọ eleto idibo, INEC silẹ. To fi mọ ajọ adojutofop ilera, National Health Insurance Scheme.

Awọn ileeṣẹ ti NIMC fi ọwọ si

Oríṣun àwòrán, Nimc

Awọn ileeṣẹ ti NIMC fi ọwọ si

Oríṣun àwòrán, Nimc

Koda, ajọ to n ri si owo ifẹhinti, to fi mọ ajọ to n ṣe onka iye eeyan ti wa ni Naijiria, ati ileeṣẹ ifiwe ranṣẹ naa wa lara wn.

Awọn ileeṣẹ ti NIMC fi ọwọ si

Oríṣun àwòrán, Nimc

National Identification Number di dandan fún ìforúkọsílẹ̀ Siimu

Ajọ to n mojuto ibaraẹnisọrọ ni Naijiria, Nigerian Communication Commission (NCC), ti bẹrẹ si ni lo aṣẹ mii lori awọn to fi orukọ siimu foonu alagbeka wọn silẹ.

Lara ilana tuntun naa ni pe wọn gbọdọ ni akọsilẹ pẹlu ajọ National Identification Number (NIN).

Igbesẹ yii jẹ ọna lati le ri pe asẹyọri to ṣe lori ayẹwo iforukọsilẹ siimu to ṣe lọdun to kọja, ati lati mu nkan pada bọ sipo ni ẹka ibaraẹnisọrọ.

Idi si niyii ti ajọ NCC ati awọn eeyan mii ni ẹka ibaraẹnisọrọ ṣe fẹnuko pe o ti di dandan lati mu ki akoyawọ ati ootọ wa ninu eto iforukọsilẹ siimu.

Awọn ilana tuntun naa niyii:

1.NCC yoo ri daju pe gbogbo awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ ti tẹle asẹ to pa pe ki wọn o da iforukọsilẹ siimu duro.

2.Awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ yoo sọ fun gbogbo onibaara wọn lati fi nọmba NIN wọn kun akọsilẹ to wa nilẹ tẹlẹ nipa wọn fun siimu.

3.Laarin ọsẹ meji pere ni awọn onibaara naa gbọdọ fi nọmba NIN wọn ranṣẹ, bẹrẹ lati ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kejila si ọgbọnjọ, oṣu Kejila, ọdun 2020.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa: Mọ̀ síi nípa ìró afárànma àti agbárànmọ́ fáwẹ́ẹ̀lì Yorùbá

4.Lẹyin ọsẹ meji, gbogbo siimu ti ko ba ni nọmba NIN ko ni i ṣiṣẹ mọ.

5.Igbimọ alamojuto (minisita ati awọn Ọga Agba ileeọẹ ibaraẹnisọrọ) yoo mojuto lati ri i pe awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ tẹle aṣẹ yii.

6.O ṣe e ṣe ki ijọba o gba iwe aṣẹ kuro lọwọ ileeṣẹ ti ko ba tẹle ilana yii, tabi ijiya nla miran.

Àkọlé fídíò, Kollington ṣàlàyé bí orin Fuji ṣe bẹ̀rẹ̀ gan an ní Nàiìjíríà

Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kejila,ọdun 2020, ni ajọ NCC kede fun gbogbo araalu lati ri daju pe nọmba NIN wọn wa lara iforukọsilẹ siimu wọn.

Wọn ni ki wọn o ma binu fun gbogbo inira ti eto naa le mu wa.