Oyo state: 615, nọ́mbà tuntun fún ìdáàbòbò àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ̀

Oríṣun àwòrán, @seyiamakinde
Bi ẹ ba n gbọ ariwo Ẹfa, ookan, aarun, 615 ni ipinlẹ Ọyọ, kii ṣe nọmba tẹtẹ tita tabi ti baba ijẹbu o.
Ẹ o pe ki wa ni?
Ẹfa, ookan, aarun, 615 ni nọmba tuntun ti ijọba ipinlẹ Ọyọ nipasẹ ajọṣepọ pẹlu ajọ ibaraẹnisọrọ, NCC gbe kalẹ fun araalu lati maa pe lai ni kete ti wọn ba kọlu ipenija abo ninu irinajo wọn.
- Àwọn ọmọ ilẹ Indonesia ṣe ìwọ́de lóri fífòfin de ìbalòpọ ṣáájú ìgbéyàwó
- Inú mí dùn bí ìpínlẹ̀ Ọyọ se setán láti bẹ̀rẹ̀ ilé-ìwé tí àwọn akẹkọ̀ọ́ ń gbé- Òbí
- Ilé ẹjọ́ kọ̀ láti tú Omoyele Soworẹ sílẹ̀
- Àwọn mẹ́rin t'íjọba Buhari k'etí ikún s'àṣẹ òmìnira iléẹjọ́ lórí wọn rèé
- Kunle Afolayan, òṣìṣẹ́ báńkì tẹ́lẹ̀ kó tó di gbajúgbajà òṣèré
Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde ṣalaye pe nọmba naa ni nọmba fun idaabobo araalu ti wọn yoo ma lo nibẹ.
Nigba to n sọ bi nọmba naa yoo ṣe maa ṣiṣẹ, Gomina Seyi Makinde ni awọn olugbe ipinlẹ Ọyọ to ba n dojukọ ipenija aabo bi idigunjale, rogbodiyan, ijamba ina jijo, tabi awọn ijamba miran lee pe fun iranwọ ajọ gbogbo to ba yẹ ni kiakia.
Gẹgẹ bi o ṣe ṣalaye, lasiko ti awọn aṣoju ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ NCC wa ṣe abẹwo si oun ni ọfiisi gomina to wa ni Agodi nilu Ibadan loṣu Kẹjọ ọdun 2019 ni wọn jiroro lori agbekalẹ nọmba naa.









