Buhari Administration: Ó ti d'èèyàn mẹ́rin t'íjọba Buhari kò bọ́wọ́ fún iìdájọ́ wọn

Oríṣun àwòrán, Facebook/Omoyele Sowore
Yoruba bọ, wọn ni ẹni to buru mọ ṣugbọn o kan n duro de ẹni ti yoo sọ fun un ni, bẹẹ, kosi.
Bayii lọrọ ri pẹlu ẹgbẹ awọn agbẹjọro ni Naijiria, NBA to sọ pe ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari ko bọwọ fun idajọ ileẹjọ, eleyi to lodi si ilana eto ijọba awaarawa.
Ajọ NBA fi aidunnu rẹ han si bi ijọba to wa lori aleefa ti kọ eti ikun sawọn idajọ ileẹjọ kan lorilẹ-ede Naijiria.
Alukoro ẹgbẹ awọn agbẹjọro ni Naijiria, Kunle Edun ijọba n lo ajọ ọtẹlẹmuyẹ lati tapa sofin idajọ ileẹjọ lorilẹede Naijirira.
- Bú ààrẹ láwọn orílẹ̀èdè márùn-ún yìí kí o rugi oyin
- Irọ́ ni, mi ò sọ pé mọ fẹ di Ààrẹ ní 2023- Tunde Bakare
- Osinbajọ: Ọlọrun ṣetán láti mú Nàìjíríà d'élẹ̀ ìlérí, TUC ní Nàìjíríà ti kùnà lẹ́ni ọdún 59
- ‘Omoyele Sowore tí dé ilé ẹjọ́ ní Abuja!’
- Ẹ yéé purọ́ kiri! Ìdí rèé tí Aisha Buhari kò tíì padà sí Nàìjíríà- Iléeṣẹ́ ààrẹ
Wọny ni igba mẹrin ọtọọtọ ti ijọba Aarẹ Buhari ti kọ eti ikun si aṣẹ ileẹjọ lati da awọn ọmọ Naijiria silẹ lahamọ.
Ibrahim El-Zakzaky:
Ibrahim El-Zakzaky jẹ olori ẹgbẹ musulumi Shiite lorilẹ-ede Naijiria, oun ati iyawo rẹ, Zeenat ni ijọba ju si atimọle ajọ DSS lati ọdun 2015 .
Ẹsun onikoko mẹjọ eleyi ti ipaniyan, kiko eeyan jọ lọna aitọ ati dida alaafia awujọ ru wa lara wọn.
Ajọ DSS kọ lati fun El-Zakzaky ati aya rẹ lominira lẹyin ti ileẹjọ giga l'Abuja paṣẹ pe ki wọn tu wọn silẹ lahamọ.
Sambo Dasuki:
Sambo Dasuki to jẹ oludamọran fun ijọba lori ọrọ aabo si wa latimọle ajọ DSS d'onii lẹyin ti ijọba apapọ kọ lati tẹle idajọ ileẹjọ to paṣẹ pe ki wọn gba beeli rẹ.
Ẹsun iṣowo to le ni biliọnu meji dọla ti ijọba ya sọtọ fun rira ohun elo ija ogun fun ileeṣẹ ologun Naijiria lasiko ijọba Aarẹ ana, Goodluck Jonathan kumọkumọ ati nini ohun elo ija ogun lọna aitọ.
Dasuki gbominira lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kejila, ọdun 2015, ṣugbọn ajọ DSS mu pada, wọn si tun ju u satimọle.
Jones Dabiri:
Ọgbẹni Jones Dabiri to jẹ akọroyin ti wa latimọle lati ọjọ kọkanlelogun, oṣu keje, ọdun 2016 lẹyin ti ileẹjọ paṣẹ fun ajọ DSS lati fi i silẹ ati pe ki wọn sanwo kan fun un titinimọle lọna aitọ.
Ajọ DSS ko ti ẹ fawọn ẹbi, ọrẹ ati awọn dokita oniṣegun oyinbo lanfaani lati ṣabẹwo si i lahamọ.
Ẹsun igbesunmọmi ati iwa ọdaran lori ayelujara ni wọn kan an.
Omoyele Sowore
Ajọ DSS kọ lati fi ajijangbara ati akọroyin, Omoyele Sowore silẹ latimọle lẹyin ti ileẹjọ giga ijọba apapọ paṣẹ ominira rẹ.
Ẹsun wi pe o fẹ fipa doju ijọba aarẹ Buhari bo lẹ ni wọn fi kan Sowore.
Ọjọ kẹta, oṣu kẹjọ lawọn ajọ DSS mu Sowore eyi ti i ṣe ọjọ meji si ọjọ ti Sowore fẹ ṣe ifẹhonu han ti wọn ni #RevolutionNow lori bi nnkan ṣe n lọ lorilẹ-ede Naijiria.
Kini SERAP n sọ?
Ẹwẹ, ajọ to n ja fẹtọ ọmọ niyan, SERAP rọ Aarẹ Buhari pe ko ṣatunṣe lori ibọwọ fun ofin nitori awọn ohun to jẹyọ ni bii ọdun mẹrin to kọja nipa ọrọ titẹle ofin kudiẹ kaato.
Ajọ SERAP sọ fun aarẹ Buhari pe iwa aibọwọ f'ofin tako eto igbogun ti iwa ibajẹ ati ajẹbanu ti ijọba Buhari gun le.
Bakan naa, ni ileeṣẹ BBC ede oyinbo fọwọ wa olori ẹka eto idajọ ni Naijiria, Abubakar Malami lori bi ijọba ti kọ eti ikun si bi Sowore si tun fi wa latimọle lẹyin ti ileẹjọ paṣẹ pe ki wọn fi silẹ.












