Komla Dumor: Solomon Serwanjja jáwé olúborí nínú Àmì ẹ̀yẹ BBC

Solomon Serwanjja
Àkọlé àwòrán, Solomon Serwanjja fẹ tẹsiwaju ninu ipasẹ rere ti Komla Dumor ti fi leelẹ nipa yiyi ọna iroyin ti awọn eeyan mọ nipa ilẹ Afirika pada.

Akọroyin ati oniroyin Solomon Serwanjja ti bori idije gbigba ami ẹyẹ BBC World News Komla Dumor Award ti ọdun 2019.

Akaroyin ni Sewanjja lori amohunmaworan NBS ni Uganda nibi to ti n ṣe atọkun awọn eto ile iṣẹ naa to pegede ju.

Bakan naa o ṣe agbejade awọn iroyin to gba ami ẹyẹ eyi ti ọkan lara rẹ han lori akanṣe eto Africa Eye ti ile iṣẹ BBC nipa bi wọn ṣe n ta oogun ti dokita ko kọ lọna aitọ.

Wọn ṣe agbekalẹ eto ami ẹyẹ naa lati maa yẹ Komla Dumor, akaroyin ile iṣẹ BBC kan to ṣaa deede ku lọdun 2014 lẹni ọdun mọkanlelogoji.

Àkọlé fídíò, BBC ṣe'filọlẹ ami ẹyẹ Komlar Dumor

Serwanjja ni ẹni ikaarun ti yoo jawe olubori fun ami ẹyẹ naa lẹyin awọn wọnyi: Waihiga Mwaura, Amina Yuguda, Didi Akinyelure ati ọmọ Uganda mii bii tirẹ, Nancy Kacungira.

Lára àwọn mùdùǹmúdùn àmì ẹ̀yẹ náà, yóò lo oṣù mẹ́ta ní ilé iṣẹ́ BBC London yóò sì tún pada sí ilẹ̀ Áfíríkà láti gbé ìròyìǹ kan síta níbẹ̀.

Ilumọọka akọroyin ni ti iṣẹ iroyin si jẹ ẹ lọkan gidi gan an to n ṣafihan ifẹ to ni lati mu ayipada ba orilẹ-ede Uganda.

"Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ǹkan ni Komla Dumor ṣe. Ọna to n gba ṣe iṣẹ tirẹ a maa tu ni lọkan gẹgẹ bi o ṣe gbagbọ pe ilẹ Afirika ti n dagba to si fẹ ki gbogbo aye ri iyatọ".

Serwanjja ṣalaye pe: "Isọwọ karoyin Komla Dumor maa n ba mi lara mu to si maa n wu mi bakan naa lati ṣe bi o ti n ṣe fun ilẹ Afirika.

Mo fẹ tẹle ipasẹ rere to fi silẹ nipa sisọ iroyin Afirika, kii ṣe lọna awọn nkan ti a n koju nikan ṣugbọn pẹlu awọn ilọsiwaju ati aṣeyọri ti a ti ni".

Àkọlé fídíò, Waihiga Mwaura ti Kenya gba àmì ẹ̀yẹ Komlar Dumor

Kii ṣe bi o ṣe n sọrọ ati bi o ṣe n karoyin nikan ni Serwanjja fi mu ọkan awọn adajọ, bi ko tun ṣe ifarajin rẹ ati igboya lati ṣi aṣọ loju ọrọ to ba kan araalu.

Oludari ile iṣẹ BBC lagbaye, Jamie Angus ni: "Lati mọ riri ati lati ṣe agbega fun awọn oniroyin to ni ẹbun ara ọtọ ni Afirika ṣe pataki si wa lorukọ Komla".

Àkọlé fídíò, Nkan ti awọn eeyan nsọ lori BBC Yoruba

Jamie ni "bi Komla ṣe maa n kọroyin ti ko ipa nla pẹlu awọn ololufẹ wa kaakiri agbaye inu wa si dun lati ni Solomon ni BBC lati fi iṣẹ kun ohun ti Komla ni ifarajin fun nipa sisọ itan Afirika".

Àkọlé fídíò, Iko BBC Yoruba tuntun