BBC World News Komla Dumor award 2018: Waihiga Mwaura ló fakọyọ
Akọ̀ròyìn tó tún jẹ́ atọ́kùn ètò lórí ẹ̀rọ móhùnmáwòrán ní orílẹ̀èdè Kenya Waihiga Mwaura ti gbégbá orókè nínú ìfigagbága láti gba àmì ẹ̀yẹ̀ BBC World News Komla Dumor award ti ọdún 2018.
Arákùnrin náà ló ń ṣe atọ́kùn ìròyìn ìrọ̀lẹ́ èyí tó gbayì jù lórí ẹ̀rọ̀ móhùmáwòrán Kenya, Citizen TV.
Lára àwọn mùdùǹmúdùn àmì ẹ̀yẹ náà, yóò lo oṣù mẹ́ta ní ilé iṣẹ́ BBC London yóò sì tún pada sí ilẹ̀ Áfíríkà láti gbé ìròyìǹ kan síta níbẹ̀.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:
Wọ́n ṣe àgbékalẹ̀ àmì ẹ̀yẹ yìí láti yẹ́ Komlar Dumor tó jẹ́ atọ́kùn pẹ̀lú ilé iṣẹ́ BBC World News sí sùgbọ́n ṣàà dédé ló kú lọ́dún 2014 lọ́mọ ọdún mọ́kànlélógójì.
Ajáwé olúborí yìí ni ẹni ìkẹẹ̀rin tí yóò gba àmì ẹ̀yẹ́ náà lẹ́yìn tí Nancy Kacungira ọmọ oríllèdè Uganda gbà a ní ọdún 2015 lẹ́yìn náà ni àwọn ọmọ Nàìjíríà méjì Didi Akinyulere àti Amina Yuguda gba àmì ẹ̀yẹ náà.
Ajáwé olúborí náà jẹ́ mọ̀lúmọ̀ọ́ka oníròyìn tí wọ́n sí máà ń ṣí fílà fún ojú rẹ̀ lórí afẹ́fẹ́ jákèjádò Kenya pẹ̀lú àwọn ìròyìn rẹ̀ nípa eré ìdárayá títí dóri òṣèlú.
"Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ǹkan ni Komlar Dumor jẹ́ sí mi gẹ́gẹ́ bí oníròyìn àti bí ọlọ́dani". Ó tún sọ wí pé " bí mo bá le ṣe ìdá mẹ́wàá tàbí ogún ohun tó ṣe nígbà ayé rẹ̀, n gó ti ṣe ipa tèmi nínú iṣẹ́ ìròyìn.
Gẹ́gẹ́ bí ọmọ ilẹ̀ adúláwọ̀, mó ní ìyangàn ànfàní tí mo ní láti lè sọ ìtan Áfíríkà fún àwọn ènìyàn káàkiri àgbáyé.
Arákùnrin yìí mú orí àwọn adájọ́ ìdíje wú pẹ̀lú bí ó ṣe máa ń sọ ìròyìn rẹ̀ àti bí ó ṣe máa ń fi ara rẹ̀ hàn lórí afẹ́fẹ́.
Àwọn adájọ́ ìdíje ní ìjẹlọ́kàn rẹ̀ láti gbé ohùn Áfíríkà àti ọ̀nà ìṣèwádìí rẹ̀ ló mú u tayọ àwọn olùdíje tó kù.














