Osun Election Results 2018: Ademola Adeleke ní wọ́n jà wọ́n lólè
Olùdíje tó lé iwájú nínú ìdìbò ìpínlẹ̀ Ọṣun, Sẹ́nétọ̀ Ademola Adeleke ti sapejuwe idibo gomina to waye ni ipinlẹ Ọsun gẹgẹbi eyi to farape ti idibo to waye ni June 12, ọdun 1993.
Adeleke ni wọn ja awọn ara Ọsun ni ole pẹlu bi wọn se sọ wi pe ko si ẹni to jawe olubori ninu idibo naa, bio tilẹ jẹ pẹ oun lo le waju ninu esi idibo naa.
O fi ẹ̀mí ìmore hàn sí àwọn ará ìpínlẹ̀ Ọṣun fún àtilẹ́yìn wọn lasikonigba to n ba BBC Yoruba sọ̀rọ̀ lórí gbogbo awuyewuye tó ń lọ lóde.
Ṣáájú, nínú àtẹ̀jáde kan tí ó buwọ́lù lọ́jọ́ Kẹtàlélógún, Oṣù Kẹ́sàn án, Sẹ́nétọ̀ Adeleke ní àtìlẹ́yìn púpọ̀ tí òun rí jákèjádò ìpínlẹ̀ Ọ̀sun tún fún òun ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ síi.
Ó tún jẹ́ kó di mímọ̀ pé àwọn ará Ọṣun bu iyì kún òun ni tó fi jẹ́ pé òun ló jáwé olùborí káàkiri àwọn ìjọba ìbílẹ̀.