Komla Dumor Award 2019: BBC ń wa ìràwọ̀-oníròyìn tó ṣẹ̀ ń dide l'Áfíríkà

Àkọlé fídíò, Ile iṣẹ BBC fẹ ki o kopa ninu ami ẹyẹ 2019 BBC World News Komla Dumor

Ileeṣẹ BBC n wa awọn irawọ to ṣẹṣẹ n dide ninu iṣẹ iroyin nilẹ Afrika fun ami ẹyẹ 'Komla Dumor' tileeṣẹ BBC lagbaye ní igba ikarun un.

Awọn akọroyin jakejado ilẹ Afrika ni wọn n pe lati kopa ninu ami ẹyẹ yii, eyi ti afojusun rẹ wa lati sawari ati agbelarugẹ awọn irawọ tuntun latilẹ Afrika.

Ẹni to ba yege yoo lo osu mẹta ni olu ileesẹ BBC nilu London, yoo ni ọpọ imọ kikun ati iriri.

Deede aago mejila ku isẹju kan loru ọjọ kẹtalelogun, osu kẹta, ọdun 2018 ni ikọwe beere lati kopa ninu ami ẹyẹ naa yoo wa sopin.

Wọn gbe ami ẹyẹ naa kalẹ lati bu ọla fun Komla Dumor, gbajugbaja agbohunsafẹfẹ to dantọ lati orilẹ-ede Ghana.

O tun jẹ oniroyin fun ikanni iroyin BBC lagbaye. Lojiji lo dagbere faye lọdun 2014 lẹni ọdun mọkanlelogoji.

Ilu Eko ni orilẹ-ede Naijiria ni wọn ti n sefilọlẹ ami ẹyẹ tọdun yii.

Amin iyasọtọ kan
Akọ̀ròyìn Kenya

Oríṣun àwòrán, Joshua Wanyama

Àkọlé àwòrán, Akọ̀ròyìn Kenya to gba tọdun 2018

Ẹni ti yoo jawe olubori fun ami ẹyẹ yii gbudọ jẹ ẹni to tayọ, ti o n gbe ni ọkọkan ninu awọn orilẹ-ede Afrika.

O si tun gbọdọ maa sisẹ nilẹ Afrika, o ni lati ni ọgbọn atinuda fun isẹ akọroyin papọ mọ ẹbun to tayọ lori afẹfẹ ati ẹbun to pegede ninu sisọ awọn itan to jẹ mọ tilẹ Afrika pẹlu ilakaka ati aayan lati di irawọ ọjọ ọla.

Àkọlé fídíò, Waihiga Mwaura ti Kenya gba àmì ẹ̀yẹ Komlar Dumor

Yatọ si pe ẹni to ba yege lati gba ami ẹyẹ naa yoo lọ lo akoko kan ni olu ile iṣẹ BBC nilu London, bakan naa ni onitọun yoo tun se abẹwo si Afrika lati kọ iroyin-ti wọn yoo si se alabapin iroyin naa jakejado ilẹ Afrika ati lagbaye.

Presentational grey line

Awọn eeyan to ti gba ami ẹyẹ Komla Dumor tẹlẹ ni:

2015: Nancy Kacungira lati orilẹ-ede Uganda,

2016: Didi Akinyẹlurẹ lati orilẹ-ede Naijiria,

2017: Amina Yuguda lati orilẹ-ede Naijiria,

2018: Waihiga Mwaura lati orilẹ-ede Kenya.

Presentational grey line

Akọroyin ọmọ orilẹ-ede Kenya, Waihiga Mwaura lo jawe olubori lọdun to kọja o si jabọ iroyin lati ilẹ Togo nipa awọn ọjẹ wẹwẹ to n sọ akisa di ohun to wulo.

Waihiga ni eniyan yoo mọ iru itara ti Komla maa fi n sọ itan Afirika.

Waihiga yoo kopa ninu eto ifilọlẹ ti ọdun 2019 ti yoo si ṣe atọkun lara awọn ipade ita gbangba ile iṣ BBC lagbaye nipa agbara awọn ọdọ Naijiria ninu idibo to m bọ.

Nigba to n sọrọ nibi eto ifilọlẹ naa, Jamie Angus to jẹ oludari apapọ ile iṣẹ BBC lagbaye sọ pe:

"Ninu saa yi ti kikọ iroyin otitọ to si ṣee di mu ko fi bẹẹ fẹsẹ mulẹ, o ṣe pataki lati wo awọn oniroyin to ni imọ to si le ṣalaye itan Afirika faye gbọ ki a le ni imọ kikun nipa ohun to n ṣẹlẹ kaakiri ẹkun naa.

Gbogbo awọn to jawe olubori sẹyin lo ti fi didantọ wọn han ninu iṣẹ iroyin, wọn si ti ni imọ sii nipa ṣiṣe iroyin lẹsẹ kuku."

"Ori wa wu lati tẹsiwaju ninu titọ ipasẹ ọna ti Komla la kalẹ. a si n wa oniroyin miiran to dangajia lati ẹkun Afirika."

  • Lati mọ bi o ba koju osuwọn lati kopa ati lati forukọ silẹ, Tẹ ibi
  • O tun le pin iroyin naa lori ẹrọ ayelujara nipa lilo #BBCKomlaAward.