Aisha Buhari: Iléeṣẹ́ ààrẹ sọ ìdí tí Aisha Buhari kò fi tíì padà sí Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Facebook/Aisha Buhari
Ileeṣẹ aarẹ ti ṣ'aṣọ loju eegun ohun to faa ti aya aarẹ orilẹede Naijiria, Aisha Buhari fi rinrin ajo lọ si ilẹ okere fun bi oṣu meji bayii.
Oluranlọwọ fun Aisha Buhari lori ọrọ to n lọ, Suleiman Haruna sọ pe aya aarẹ orilẹede Naijiria ni ominira lati rinrin ajo lọ si ibi to ba wuu nigba kugba.
Ọpọ lo ti n sọ pe Aisha lọ si ilẹ okere nitori ija tawọn kan lo n waye ni olu ileeṣẹ ijọba l'Abuja ati aiidunnu rẹ si bawọn eeyan kan ṣe n dasi iṣejọba Aarẹ Buhari.
- Ǹ jẹ́ o mọ ọ̀rọ̀ tí Ààrẹ Buhari sọ fún Ọọ̀ni níbi ọdún Ọlọ́jọ́?
- Bàbá ọlọ́mọ méjì kú sínú àgbàrà òjò
- Tacha tọrọ àforíjí, ó da gbogbo ẹ̀bi lé ara rẹ̀ lórí
- Fábàdà! ìlú Eko kọ́ ló léwu jùlọ láti gbé lágbàáyé- Ìjọba Eko
- Àjẹ́ àti Aṣẹ́wó ní ìyá Rainbow - Òjòpagogo
- Kàyééfì rèé! Kábíyèsì fẹnu ara rẹ̀ tú àṣírí àwọn Fulani Daran daran tó ń ṣọṣẹ́ nílùú rẹ̀
Ṣugbọn Ọgbẹni Haruna ni iwọfa lẹnu, ohun to ba si wu ẹlẹnu lo le fẹnu rẹ sọ lọrọ tawọn kan n gbe kiri.
Haruna fi kun ọrọ rẹ pe niwọn igba ti Aisha kii ṣe oṣiṣẹ ijọba, o lanfaani lati rinrin ajo lọ si ibi to fẹ.
Aisha ti fi aidunnu rẹ han tẹlẹ lori iṣejọba Aarẹ Buhari, nigba to sọ pe awọn ti wọn ko gbaruku Buhari ko too wọ le ibo rẹ ni wọn n jẹ gaba ni ijọba rẹ.
Lati igba ti Aisha ti lọ fun iṣẹ Hajj ni Mecca ni iroyin sọ pe iyawo rẹ ko tii pada si orilẹde Naijiria.








