Lizzy vs Toyin: Yomi Fabiyi ní òun fa obì yọ lápò láti bá Toyin sọ̀rọ̀ kó parí ìjà pẹ̀lú Lizzy

Lizzy Anjorin, Yomi Fabiyi, Toyin Abraham

Oríṣun àwòrán, @lizzyanjorin, @realyomifabiyi, @toyin_abraham

Bii pe yoo tan yoo tan ni ija aarin awọn gbajugbaja oṣere Yoruba meji, Lizzy Anjorin atin Toyin Abraham ṣùgbọ́n awọn ọrọ bi owe bi owe ṣi n ṣere kiri ilẹ.

Fun aridaju eyi, ko tii si ọ̀kan ninu awọn mejeji tọrọ kan to jade lati ni mo tuba o, tabi mo tọrọ aforiji tabi mo gba kamu.

Bi o tilẹ jẹ wi pe awọn mejeji ko fi bẹẹ́ maa gba a lọwọ ara wọn bi ẹni n gba igba ọti gẹgẹ bi wọn ṣe ṣìmẹ̀dọ̀ lẹyin ti aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere atawọn agbaagba oṣere kẹnu bọ ọrọ naa.

Oju opo ayelujara Yomi Fabiyi

Oríṣun àwòrán, @realyomifabiyi

Sibẹ, awọn akẹgbẹ wọn to ṣi n fi ọrọ ranṣẹ si wọn fi han pe ija ọhun ko tii tan nilẹ gẹgẹ bi wọn ṣi ṣe n lo oniruuru ọna lati pẹtu si aawọ yii.

Yomi fabiyi loju opo instagram ni "lẹẹkan sii, mo rawọ ẹbẹ si Lizy Anjorin ati Toyin Abraham lati wa ọna fi tete yanju ohun to wa larin wọn.

O ni oun o gbe lẹyin ẹnikan o tori iru ọrọ bayii loot a maa da ọgbẹ si ni lọkan ṣugbọn t'oun ti n ri iwosan.

Yomi darukọ pe Iyabo Ojo akẹgbẹ wọn naa ti da si ọrọ naa ṣaaju to ba wọn sọrọ.

Oju opo ayelujara Yomi Fabiyi

Oríṣun àwòrán, @realyomifabiyi

O wa lahun pe ko si aawọ laarin oun ati Toyin o bi o tilẹ jẹ wi pe awọn mejeeji ṣẹṣẹ n sọrọ fun igba akọkọ ni lati nkan bii ọdun meji. "O dara pe a jọ tọrọ aforiji lọwọ ara wa a si dari ji ara wa".

Yomi fi kun un pe "mo fẹran awọn akẹgbẹ mi mi o si ko iyan wọn kere yala lori ayelujara tabi lẹyin ayelujara... mo ṣi bọwọ fun Toyin ati ọgbọn ori to fi n ṣiṣẹ rẹ".

O rọ awọn akẹgbẹ pe ko tọ si ẹnikankan ninu awọn ki ẹnikeji maa dun koko mọ ọ loju opo ayelujara ara wọn. O foya pe ẹlomiran ko tilẹ ni gbe ija rẹ dori ayelujara, wọn lee pete ibi labẹlẹ eyi ko si dara lati padanu ẹnikẹni.

Yomi ni yala awọn ba ara wọn ṣe tabi awọn ko ba ara wọn ṣe, daadaa yoo ya lọdọ onikaluku torinaa o tọrọ aforiji lọwọ to ba ti fi ihuwasi rẹ ṣẹ o si wa alafia.

O ti le loṣu kan ti gbọnmi si i omi o to laarin Toyin Abraham ati Lizzy ti bẹrẹ ni kete ti Toyin bimọ tan tija naa si da lori mo ki ọ tabi mi o ki ọ ku ewu ọmọ lo ba di tọrọ fọn kalẹ.