Tacha àti BBNaija: Bobrisky fẹ́ fi mílíọ̀nù kan náírà tọrẹ fún Tacha lẹ́yìn tí wọ́n lé e ní BBNaija

Oríṣun àwòrán, DSTV NIGERIA
Lẹyin ti Tacha ti gba idajọ kuro ni sakani mi nile ẹlẹbọn agba lọjọ Ẹti, oniruuru iha ni awọn eeyan ti kọ si ijade rẹ. Bi awọn kan ṣe gboriyin fun un lawọn kan n bu ẹnu atẹ luu.
Amọṣa ni bayii, Bobrisky ti ni oun yoo fun Tacha ni miliọnu kan naira.
Ninu ọrọ to fi si oju opo Instagram rẹ lọjọ Abamẹta, Bobrisky ni o wu oun lati ṣe ju bẹẹ lọ sugbọn agbara ku diẹ kaa to fun oun.
"Ifẹ mi, mi o ni gbogbo aye yii lati gbe le ẹ lọwọ bayii!!! Sugbọn gba mi bi mo ti ri nitori mo nifẹ rẹ. Ni bayii naa, maa reti miliọnu kan ninu aṣuwọn banki rẹ lọjọ Aje lati ọdọ mi."
- 'Èmi àti Toyin Abraham ṣẹ̀ sọ̀rọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ láti ọdún méjì torí ìjà òun àti Lizzy'
- Funke Akindele, oníròyìn, agbẹjọrò àti òṣèré; ohun tí ẹ kò lérò nípa rẹ̀
- Ààrẹ Buhari balẹ̀ bàgẹ̀ s'Abuja lẹ́yìn ìpádé àjọ UNO l'Amẹrika
- Kàyééfì rèé! Kábíyèsì fẹnu ara rẹ̀ tú àṣírí àwọn Fulani Daran daran tó ń ṣọṣẹ́ nílùú rẹ̀
- Ariwo sọ, wọ́n fọwọ́ òsì júwe ilé fún Tacha lórí ètò àgbéléwò BBNaija
- Ọdún Ọlọ́jọ́ ń dùn mọ̀rànìn-mọran-in ní Ilé-ifẹ̀
Tacha: Mo mọ̀ pé ìwà burúkú ló pa mi bí ọtí, ẹ dárí jì mí
Tacha to ti di mọlumọọka bayii tori kikopa rẹ lori eto agbelewo Big Brother Nigeria.
Bii lẹta gbọọrọ tabi episteli gẹgẹ bi awọn to da si ọrọ naa ṣe sọ ọ ni Tacha kọ ranṣẹ si awọn ololufẹ rẹ ati ti BBNaija.
Ninu ọrọ ituba rẹ, o jẹ ko di mimọ pe oun to yẹ ko pari lọna nla fun ohun lo wa pari lojiji tori ori inu oun to tako oun.
"Tọkan tọkan, mo tọrọ aforiji fun gbogbo iwa ti mo ti wu to fi ri bayii mo si gba a lẹbi".
O ni o wu oun ki oun wa lori eto naa di ọjọ ikọkandinlọgọrun ṣugbọn "ẹlẹran ara ni mi, mo ja kulẹ, mo si tun jakulẹ lọpọ igba".

Oríṣun àwòrán, Simply_Tacha
- Èèmọ̀ rèé! Àṣírí ilé tí wọ́n ti ń fipá bá àwọn ọmọdékùnrin lò tú síta
- Ta ni 'Mad Melon' ọ̀kan lára àwọn akọrin Danfo Driver tó d'olóògbé?
- Kàyééfì rèé! Kábíyèsì fẹnu ara rẹ̀ tú àṣírí àwọn Fulani Daran daran tó ń ṣọṣẹ́ nílùú rẹ̀
- Èmi àti Saheed kìí ṣe ọmọdé, a ti jọ ṣe Sinimá papọ̀, èyí túmọ̀ sí pé ìjà ti parí - Fathia Balogun
- Àjẹ́ àti Aṣẹ́wó ní ìyá Rainbow - Òjòpagogo
- Ọ̀pọ̀ èèyàn bẹnu ẹ̀tẹ́ lu Mercy Aigbe lórí bó ṣe ki Adeniyi Johnson
Sibẹ, wuyewuye lori ọrọ Tacha ti wọn ti ṣe fọwọ osi juwe ile fun un kuro lori eto agbelewo BBNaija ko tii tan o.
Olorin takasufe, Peter Okoye lo kọkọ sọ pe oun ko ṣeleri lati fun Tacha lẹbun ọgọta miliọnu naira.
Okoye ni faabada oun ko le fun onijagidijagan eeyan lẹbun owo.
Awọn kan faake kọri lori ayelujara pe Peter n parọ ni, wọn ni o ṣẹ ẹ nitori wọn ti le Tacha kuro ni BBNaija.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Peter ṣalaye pe ohun to sọ ni pe oun yoo ran Tacha lọwọ lati ṣiṣẹ ri owo to to ọgọta miliọnu naira.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Obong Roviel ni ọrọ Peter Okoye ko ya oun lẹnu nitori Peteru ninu Bibeli gan da Jesu.
Koda Okoye sọ pe ẹni to ba ni ẹri to daju, oun ṣetan lati fun ẹni naa lẹbun miliọnu mẹwaa naira.
Olorin takasufe, Zlatan Ibile lo kọkọ gborin jade pe lori awuyewuye to ṣẹlẹ lori ọrọ ara rirun to maa n waye laarin Tacha ati Mercy.
Zlatan sọ ninu orin naa pe "Tacha ko ni pa'yan pẹlu oorun ara rẹ".
Pẹlu ijo ati ilu ni Zlatan fi kọ orin ọhun, koda oun atawọn akẹgbẹ rẹ ni wọn jọ kọ ọ́.
Zlatan Ibile n beere ninu orin naa pe ''ki lo n run, ṣe Tacha ti wọ le?"
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Orin naa ti n mi ori ayelujara titi, o da bi ọrọ ilu gangan to jẹ pe ibi to kọ s'ẹnikan, ẹyin lo kọ si ẹlomiran.
Bawọn kan ṣe faramọ orin ọhun lawọn mii ni o ku diẹ kaato.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3

End of X post, 4

End of X post, 5

End of X post, 6

End of X post, 7

End of X post, 8