Ìfipábọ́mọlòò Kaduna: Ọlọ́ọ̀pá m'áwọn tó ń fipá bá èèyàn 500 àtàwọn ọmọdékùnrin lò pọ̀

Oríṣun àwòrán, Nigerian Police
Eeyan bi ẹẹdẹgbẹta tawọn ọmọde wa lara wọn lo gba ominira lẹyin tawọn ọlọpaa yabo ile kan lagbegbe Rigasa nipinlẹ Kaduna l'Ọjọbọ.
Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Kaduna, Ali Janga ṣalaye fun BBC pe ileeṣẹ ọlọpaa yabo gbọngan naa lẹyin tawọn ara ilu kan ta wọn lolobo lori ohun to n ṣẹlẹ lagbegbe ọhun.
Ileeṣẹ ọlọpaa fidi rẹ mulẹ pe awọn eeyan naa ti gbogbo wọn jẹ ọkunrin wa lati orilẹede Burkina Faso, Mali atawọn orilẹede ile Afirika miiran.
- Fáàbàdà! Peter Okoye lóun ò ṣèlérí N60m fún Tacha, Zlatan gbórin tuntun jáde
- Ariwo sọ, wọ́n fọwọ́ òsì júwe ilé fún Tacha lórí ètò àgbéléwò BBNaija
- Kàyééfì rèé! Kábíyèsì fẹnu ara rẹ̀ tú àṣírí àwọn Fulani Daran daran tó ń ṣọṣẹ́ nílùú rẹ̀
- Èèmọ̀ rèé! Àṣírí ilé tí wọ́n ti ń fipá bá àwọn ọmọdékùnrin lò tú síta
- Ta ni 'Mad Melon' ọ̀kan lára àwọn akọrin Danfo Driver tó d'olóògbé?
Awọn agbofinro sọ pe awọn eeyan yii tawọn ọmọde pọju lara wọn ni wọn ju ṣẹkẹṣẹkẹ si lẹsẹ ninu ahamọ ti wọn wa.

Oríṣun àwòrán, Nigerian Police
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe oniruuru iya ni wọn fi jẹ awọn eeyan ọun.
Ileeṣẹ ọlọpaa yabo gbọngan naa lẹyin tawọn ara ilu kan tawọn lolobo lori ohun to n ṣẹlẹ lagbegbe naa.
Iroyin sọ pe awọn kan n ni ibalopọ tipatipa pẹlu awọn ọmọde to wa nibẹ, bakan naa ni wọn n fiya jẹ wọn lojoojumọ.
Ọpọ ninu wọn lo sọ pe awọn ẹbi awọn lo mu awọn lọ sibẹ nitori wọn ro pe ileewe ẹkọ nipa ẹsin ni.
Ileeṣẹ ọlọọpa ni iwa imunilẹru ati iwa ika si ọmọniyan ni iṣẹlẹ naa jẹ.
Ẹwẹ, awọn afurasi mẹjọ lawọn ọlọpaa ti mu bayii, nigba ti iwadii si n lọ lọwọ












