Olojo festival: Buhari kan sáárá sí Ọọ̀ni, pè fún ìgbélékè àṣà adúláwọ̀

Buhari n sọrọ niwaju Ọọni

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

Aarẹ Buhari ti rọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria ati gbogbo adulawọ lagbaye lati maṣe gbagbe iṣẹṣe ati aṣa wọn.

Aarẹ Buhari ṣalaye ọrọ yii ninu iṣẹ to fi ran minisita fun ọrọ abẹle, rauf Arẹgbẹṣọla lọ sibi ajọdun Ọlọjọ ti ọdun yii nilu Ifẹ.

Aarẹ Buhari ni tipẹtipẹ ni aṣa n lẹ mọ awọn eeyan to ba nii. O ni inu oun dun si bi awọn eeyan Ile ifẹ ko ṣe gba ki ohunkohun ya wọn kuro lara aṣa wọn.

O wa gba adura ki Eleduwa o lọra ẹmi Ọọni ile ifẹ, awọn ijoye rẹ ati gbogbo awọn eeyan ilu Ifẹ.

Ninu ọrs tirẹ, gomina ipinlẹ Ọṣun, Gboyega Oyetọla ki awọn eeyan ilu Ifẹ ku oriire ajọdun naa.

O ni 'Ajọdun Ọlọjọ n ṣe agbeleke aṣa ati iṣẹṣe wa fun gbogbo agbye ni. Ọdun naa ti ṣe afihan aṣa Yoruba fun gbogbo agbye lati ri."

Awọn Ọba alaye to wa nibi ajọdun Ọlọjọ tọdun yii ni Olubadan of Ibadan, Obi Eze Ngwu, Orangun Oke-Ila atawọn eekan miran lawujọ.