Mexican Octogenarian: Kò sígbà táa dá aṣọ, ti a kò rílẹ̀ fiwọ́!

Oríṣun àwòrán, EDUCATION MINISTRY/TWITTER
Arabinrin ẹni ọdun mọkanlelọgọrin ti pari ile iwe alakọbẹrẹ rẹ lorilẹ-ede Mexico.
Ernestina Díaz ti ori rẹ wu lori aseyori naa n gbe ni agbegbe Chihuahua, ti o si gba iwe ẹri rẹ lati ile-ẹkọ agba Adult Education Institute ni agbegbe naa ni Mexico.
Ile ẹkọ agba yii ni awọn igbiyanju bii ti Diaz yii lo n jẹ iwuri lati tẹsiwaju fun awọn ninui ẹkọ awọn agbalagba.
Arabinrin Díaz wa lati agbegbe Tarahumara nibi ti ọpọlọpọ eniyan ko ni imọ kika ati kikọ ninu Ede Ilẹ Spain (Spanish) ati ede abinibi wọn ni Ariwa orilẹ-ede Mexico.
Ohun ijọniloju nibẹ ni pe agbẹ paraku ni Diaz atawọn eniyan agbegbe rẹ ni abule to jẹ pe oju wọn ṣẹṣẹ n la ni.
Ipinlẹ Chihuahua ti setan lati ran awọn eniyan agbegbe naa lọwọ lati ri i wi pe wọn lọ si ile iwe bi wọn tilẹ ti dagba ju bẹẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, @Lance commons
Ni oju opo Twitter wọn, Ijọba ilẹ Mexico to ba obinrin naa yọ sọ wi pe obinrin naa ti setan lati lọ si ile-iwe girama lati pari ẹkọ rẹ.
Eyi fihan pe, ko si igba ti a fẹ ṣe nkan ti a ko ṣì le gbiyanju ẹ wo.
Bakan naa, kii se arabinrin yii nikan lo ti se iru aseyọri yii.
Ọdun to kọja ni arakunrin ẹni ọdun marundinlaadọrun, Sabino Xochipoltecatl Carvente naa pari ile iwe girama rẹ.
Diaz ni ipinnu oun ni lati tẹsiwaju ninu ẹkọ oun, ki o le tubọ kọ awọn ọmọ abule rẹ ni ẹkọ iwe sii.













