BBNaija: Elozonam ṣáájú, Ike tẹ̀lé kúrò nílé ẹlẹ́gbọ̀n àgbà

Oríṣun àwòrán, Instagram/Elozonam
Elozonam ati Ike ti darapọ mọ awọn to dagbere fun ile ẹlẹgbọn BBNaija.
Awọn ni olugbe akọkọ ti iji idagbere yoo gbe kuro lẹyin ti Tacha lọ lalaibojuwẹyin.
Ṣadede ni Ebuka to jẹ atọkun eto naa wọle ẹlẹgbọn lọjọ Aiku ti o si sọ fun awọn olugbe pe ẹgbọn ni ki oun jiṣẹ fun wọn pe idagbere ko ti dopin.
O ni ki awọn ti ẹsẹ wọn n mi jolojolo Elzonam,Mike ati Ike pe ki wọn dide duro-ababọ rẹ ni pe o ni ki Elzonam kẹru rẹ maa lọ.
Ki a to dijuka to la,Ike naa gba ikede idagbere ki oun naa ma kẹru rẹ l si ile.
Elozonam wa lara awọn olugbe ti Big Brother fi kun awọn olugbe ile ẹlẹgbọn ti ko si lara wọn tẹlẹ.








