Tunde Bakare: Irọ́ ni, mi ò sọ pé mọ fẹ di Ààrẹ ní 2023

Tunde Bakare

Oríṣun àwòrán, Twitter

Àkọlé àwòrán, Tunde Bakare tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́ta ti ma ń sọ ní ọ̀pọ̀ ìgbà nípà ẹ̀ròǹgbà rẹ̀ láti dí Ààrẹ oriílẹ̀èdè Nàìjíríà.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Pasitọ ati Olori Ijọ Latter Rain Assembly, Tunde Bakare ti ni irọ patapata ni iroyin ẹlẹjẹ wi pe oun lo ma a gba ipo aarẹ ni ọwọ Aarẹ Muhammadu Buhari.

Bakare sọ eyi lasiko to n ba awọn ara ijọ rẹ ni agbeegbe Ọgba ni ipinlẹ Eko, sọrọ ni Ọjọ Isinmi.

O sọ wi pe fidio ti oun fi sita lati bi ọdun diẹ sẹyin ni awọn eniyan miran ṣẹṣẹ n gbe jade lati fi ba oun lorukọ jẹ.

O ni Olorun fi osumare han oun nipa Naijiria, eleyii to fi han wi pe ayipada yoo deba orilẹ-ede Naijiria.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Bakan naa lo ni Igbakeji Aarẹ, Yemi Osinbajo yoo bori awọn ẹni ibi to n sọrọ kobakungbe nipa rẹ, ati pe awon ọta Oṣinajo yoo pofo.

Pasito Tunde Bakare fikun un wi pe Osinbajo ni yoo rẹrin igbẹyin lori awọn ọta rẹ, nitori naa ki o lọ sinmi pẹlu ifọkanbalẹ.