Oyo: Inú òbí dùn sí ìgbẹ́sẹ̀ ìpínlẹ̀ Ọyọ láti bẹ̀rẹ̀ ilé-ìwé tí àwọn akẹkọ̀ọ́ ń gbé

Oyo

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán, Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọyo kéde wí pé àwọn ti setán láti tún bẹ̀rẹ̀ ilé-iwé tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń gbé ní ìpínlẹ̀ náà.

Inu awọn obi ipinlẹ Oyo dun lẹyin ti ijọba ipinlẹ Oyo ni gbogbo eto ti to lati ri pe awọn da ile iwe ti awọn akẹkọọ maa n gbe inu rẹ pada si ipinlẹ naa.

Sola Ibidokun to jẹ obi fun awọn omo ile iwe lo sọ bẹẹ fun BBC Yoruba.

Ogbẹni Ibidokun sọ eyi lẹyin ti komisọnna fun eto Eko ni ipinlẹ Oyo, Ọjọgbọn Kehinde Sangodoyin fi ikede naa lede ni ilu Ibadan, ni ipinlẹ Ọyo.

Ibidokun ni eto ẹkọ ile-iwe ti awọn akẹkọọ maa n gbe ma n fi aaye silẹ fun awọn ọmọ lati kọ ẹkọ to yanju fun aseyege.

Bakan naa ni ọgbẹni Ogundokun ni wọn maa n kọ awọn akẹkọọ ni ẹkọ ile, ati wi pe igbakigba ti awọn akẹkọọ ba wale, iyatọ maa n wa laarin wọn ati awon omo ti ko gbe ile iwe.

Fun idi eyi, o gboriyin fun ijoba to ṣetan lati gbe igbese naa, ti o si ki won ku iṣe takuntakun.

Ipinlẹ Oyo ti kede pe wọn ti pari igbesẹ lati tun bẹre eto ile iwe ki awọn akẹkọọ yoo maa gbe ni ile iwe.

Wọn ni ida mẹrindinlọgbọn ọmọ ti ko si nile iwe tẹlẹ lo ti pada wa sile iwe nsiyi.

Ni opin ọsẹ yii ni kọmiṣọnna fun eto ẹkọ sọ ipinnu ijoba Oyo yii di mimọ lasiko ti wọn n ṣi iṣẹ akanṣe ti awọn akẹkọọ jade ile iwe Ibadan City Academy ṣe ni Ibadan.

Koda, ọjọgbọn Kehinde sọ pe awọn olukọ oni ipele mẹrindinlogun si mẹtadinlogun ni wọn yoo maa ṣamojuto wọn.

Bakan naa lo menuba igbesẹ ijọba Oyo lati pese aga ijokoo yatọ si owo ina awọn ọga ile iwe alakọbẹrẹ ati girama ti ijọba Oyo ṣẹṣẹ san fawọn ọga ile iwe kọọkan.