Komla Dumor: Solomon Serwanjja ọmọ Uganda jáwé olúborí nínú Àmì ẹ̀yẹ BBC

Àkọlé fídíò, Komla Dumor: Solomon Serwanjja ọmọ Uganda jáwé olúborí nínú Àmì ẹ̀yẹ BBC

BBC àgbáyé fẹ́ kí ìtẹ̀síwájú túbọ̀ dé bá iṣẹ́ àwọn akọ̀ròyìn nílẹ̀ Adulawọ.

Solomon Serwanjja ọmọ ilẹ Uganda lo gba ami ẹyẹ akọni akọroyin to wa fun iranti Komla Dumor tọdun 2019.

Solomon ni bi wọn ṣe ki oun ku oriire jẹ iyalẹnu nla fun oun pe oun ni akọni ilẹ Adulawọ tọdun 2019.

Solomon ọmọ Uganda to gba tọdun 2019 yii ni ami ẹyẹ yii jẹ ami ẹyẹ yii to niyi julọ nilẹ Afrika yoo jẹ iwuri fawọn akọroyin ilẹ Adulawọ.

O ni gbogbo awọn eniyan Uganda ni ayọ wọn kun lori ami ẹyẹ to wa si Uganda lọdun yii.

Komla Dumor jẹ agba ọjẹ akaroyin lori BBC Focus of Africa TV ki ọlọjọ too de fun un.

O maa n sọ iroyin iṣẹlẹ ilẹ Adulawọ bi ọmọ ogidi ọmọ Adulawọ ni.