Habits that damage brain: Wo àwọn ìṣesí ojoojúmọ́ mẹ́wàá tó le ṣàkóbá fún ọpọlọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwọn ìṣesí mẹwàá tó lè ṣakoba fún ọpọlọ wà ni a n gbe yẹwo ni oni.
Ọpọlọ eniyan ṣe pataki pupọ ninu ẹyà ara eniyan ni eyi to jẹ pe ti o ba ni iyọnu kankan, yoo fa wahala nla fun irufẹ eeyan bẹẹ.
Bi ori ba n fọ eeyan lasan, wọn a ní ko lọ lo oogun ori fifọ tabi ko lo oogun ara riro ti ara eeyan ba n ṣe bakanbakan.
Ṣugbọn kini ki a wa sọ fún ẹni ti nkan n ṣe lọpọlọ pe ki o lo?
Ìdí ree ti a fi gbọdọ kiyesara nipa awọn ìṣesí to lè ṣakoba fún ọpọlọ wa. Asiko ti to ki gbogbo eeyan kiyesi i awọn ihuwasi to le ṣakoba fun ọpọlọ wa.
Díẹ ree ninu wọn:
1)Kikọ lati maa jẹ ounjẹ aarọ:
Pupo ninu wa lo maa n huwa aibikita yii paapa julọ lawọn ilu nla nla nibi ti kirakita atijẹ atimu kii jẹ ki awọn eeyan rántí lati je ounjẹ aarọ lasiko.
Koda, awọn eeyan miran kii ranti jẹun rara ni aarọ.
Awọn mii ko tiẹ ki ń jẹ ounjẹ aaro rara ti o si jẹ pe aijẹun yii a máa ṣe àkóbá fún ọpọlọ wa.
Glucose to wa ninu ounjẹ ni ipa to n ko ki ọpọlọ wa le ṣiṣẹ bo ti ṣe yẹ. Ti eeyan ba feran ko ma ma jẹ ounjẹ aarọ,akoba ọlọjọ pipẹ ni eyi lè mu ba ọpọlọ rẹ.
2. Ai k;í ń le maa sun daadaa fun iye wakati to yẹ:
Njẹ o tí ṣẹlẹ sí yin ri wípé ẹ gbagbe ibi ti ẹ fi kokoro ile yin sí tàbí kí ẹ tí ẹ gbagbe ona lati dé ilé pada.
Áí ma le e sun deedee ati ai ki n sun fun odiwọn wakati to pọ to lo maa n fa iru igbagbe bayi.
Eyi ko ṣẹyin nitori pe ọpọlọ ko ri ibi sinmi bo ti ṣe yẹ.
Bi eeyan ko ba sun deedee awọn 'cell' ọpọlọ wa yoo máa ku diẹ diẹ.
Ti eyi ba n waye lera lera o le ṣakoba fún ara wa.Tori naa o kere tan o yẹ ki a máa sún wakati meje lojumọ fún ìlera ọpọlọ wa.
- Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àrùn Coronavirus àti ìbálòpọ̀ akọ àt'abo
- Wo bí àwọn obìnrin kan ṣe n sọ ara wọn di 'fágìn' lẹ́ẹ̀kejì
- Coronavirus: ''Ìjọba kò tíì pàṣẹ ìlànà ìtakété-síra-ẹni padà nínú BRT la ò ṣe máa tẹ̀le''
- Ìjọba gbé ilé ijó oníhòhò tì pa lórí ẹ̀sùn títàpá sí ìlànà àti dẹ́kun coronavirus
3. Ounjẹ ajẹju ko dara rara fun ọpọlọ eeyan:
Gbogbo nkan lo ni iwọn-tun-wọn-si laye, eyi kọ yọ odiwọn ounjẹ ti eeyan n jẹ silẹ ati irufẹ ounjẹ ti eeyna n jẹ.
Aijẹun to ati aijẹun lasiko a maa ṣe akoba fun ọpọlọ, bakan naa ni ounjẹ aranju jẹ le ṣakoba fún ọpọlọ, ki ato ṣẹṣẹ sọ nipa ounjẹ ajẹju naa ni eyi to nipa buruku tó n ko lara ọpọlọ wa.
Ounjẹ ajẹju a máa ba ọpọlọ wa jẹ.
Arun Alzheimer wa lara arun ti ounjẹ ajẹju le ko ba ọpọlọ wa nitori na ki a jẹun ni ìwọnba ni imọran awọn oniṣegun fun itọju ara.
4. Jíjẹ oúnjẹ tó ní Ṣuga pupọ ninu:
Ọ̀pọlọpọ wa la jẹbi esun yii.
Awọn kan a máa mọọmọ je ounjẹ ti suga pọ ninu rẹ nigba ti awọn miran kò sí ni mọ pe awọn ti tẹri sinu rẹ.
Suga pupo a máa kọ di ọpọlọ lati le gba ounjẹ protein sara ati awọn eronja miiran.
Akoba to n se ni pe o le ko irẹwẹsi ọkàn bá onitohun tabi ko máa tètè gbagbe nkan tabi ko sí ma le kẹkọọ bo ti ṣe yẹ.
Nitori naa bi ẹ ba fẹ fi igo ọtí ẹlẹrindodo le ounjẹ ti e jẹ tan, e ranti pe suga pupọ lẹ fẹ dá sí inú yin ti eleyi sile ṣakoba fún ọpọlọ.
- Coronavirus: ''Ìjọba kò tíì pàṣẹ ìlànà ìtakété-síra-ẹni padà nínú BRT la ò ṣe máa tẹ̀le''
- Wọ́n ní kí ọ̀gá àgbà "Ede Poly" lọ rọ́kún nílé lórí ẹ̀sùn pé 'ó kan bẹ́ẹ̀dì sí ọ́fíìsì'
- Ẹ̀yà kòkòrò Covid-19 míràn jáde ní ọgọ́ta agbègbè nílẹ̀ Gẹẹsi, àjọ eletò ìlera ni k'ára ìlú má fòyà
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Kaduna gbé iléèwé tì pa nítorí ọ̀wọ́ kejì àjàkálẹ̀ COVID-19
5. Siga fifa tabi Mimu:
Ọkan gboogi ninu ọna ti a fi n se àkóbá fún ọpọlọ wa leyi jẹ.

Oríṣun àwòrán, others
Yato sí pe siga mímú n koba ẹdọ fooro eniyan, o tún máa n mú kí ọpọlọ ma ṣiṣe to bo ti ṣe yẹ.
Siga fifa le mu ki eeyan ni arun to n mu ọpọlọ kuru bi Dementia ati Alzheimer.
Koda, o le se iku pa ẹni tó bá n mu Siga amupara.
Awọn nkan miiran to tun le ṣakoba fún ọpọlọ ni wọnyi:
6. Dídá aṣọ bo ori ti a ba n sun
7. Kikọ lati ṣe eré ìdárayá niwọn ti o yẹ fun agọ ara ati lasiko to yẹ.
8. Ọtí mímu
9. Gbigbọ orin kikan pẹlu 'earphones'.
10 Aifọkanbalẹ tabi gbigbẹ ọkan ara ẹni gbóná lai nidi.
- Ogun abẹ́lé tó ń ja Akeredolu l'Ondo, òní la ó mọ̀ bóyá yó borí rẹ̀
- Ìjọba Amẹrika yọ orúkọ Sudan kúrò nínú ìwé orílẹ̀-èdè tó ń ṣagbátẹrù ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí
- Èyí ni bí èèyàn 538 ṣe ń yan ààrẹ lé èèyàn mílíọ̀nù 331 ní Amẹ́ríkà
- Wo àwọn Adelé-Ọba aládé méje tó jẹ́ obìnrin nílẹ̀ Yorùbá
- Rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ọlọ́kadà àti àwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Ibadan





















