Pregnancy cravings: Ìgbésẹ̀ wo ní aláboyún lé gbé láti dẹ́kun ìjẹkújẹ nínú oyún?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awon obinrin le ma jẹ awon ounjẹ kan bi wọn ba loyun, yala ki wọn fẹ ma jẹ awọn ounjẹ to sara loore lati tele ilana dokita, paapaa julọ lori awon nkan bi Sushi jijẹ, ẹran ati awọn ounjẹ miran.
Asiko iloyun tumọ si asiko ti ko si ẹni to le da obinrin lẹbi ti o ba n ṣa ounjẹ jẹ.
Erongba lati jẹ awon nkan didun ti a fi iyefun ṣe tabi ṣokoleeti tabi nkan dindin, o le bẹrẹ lati ara ero lasan ti yoo si maa dagba ti yoo fi di ko see ma ni ti yoo si di nkan ti obinrin naa o le se ko ma jẹ.
Ohun to ba wu ọ jẹ ninu oyun, to ba ti le ṣe ara rẹ loore dara ni jij.e
Eyi to ba maa ṣe akoba fun iwọ tabi ọmọ inu rẹ ni ko dara lati jẹ ti o si gbọdọ gbe igbesé lati dẹkun jijẹ wọn.
Ni pataki julọ, o ni lati gbiyanju ipa rẹ lati kọ ara rẹ lati igba diẹ sẹyin, ti o ba ti fi ọkan si i pe, wọn o ni fun ọ laaye lati jẹ iru awọn ounjẹ kan, o nira lati ko ara rẹ ni ijanu ni igbakuugba ti o ba ri iru ounjẹ bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nitori naa lẹyin ti o ba jẹ akara oyinbo, kaka ti o fi mu ọkan rẹ kuro ki o si tesiwaju, yoo tun jẹ ẹ bi ẹmẹẹta si.
"Asa yii tumọ si awọn asiko ti aaye wa fun obinrin lati jẹ awọn nkan ti o yẹ ko maa saa fun bi Hormes se sọ.
Oriṣiiriṣi awọn nkan lo maa n saaba wu oloyun jẹ nipo iloyun.
Hormes gba wọn niyanju pe ti o ba n ṣe ọ bi ko maa jẹ șokoleeti saa, jẹ eyi ti o dara, ki o si jẹ̀ ẹ niwọnba loojọ, ki o si tẹsiwaju ninu igbe aye rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọna kan lati mu ọkan kuro nibi asajě ni lati wa nkan ti wa a maa se lati gbe okan rẹ kuro nibẹ, iwadii kan fihan pe lolo awin nkan ti a le foju ri ati oorun didun.
Fifi okan si ati sise asaro naa tun jẹ ọna miran lati fopin si iru nkan wọnyii,
Imọran fun ọ ni pe ki o maa ro asaro lori rẹ ko si gbe ọkan rẹ kuro nibẹ ni kia.
Eso dara pupọ fun oloyun.
O san ki o maa ran ara rẹ leti pe fun igba diẹ naa ni waa fi gbe oyun naa.
Ati pe ayọ ti o ba ri ọmọ rẹ ko wa laaye ati ni alaafia yoo jẹ ki o gbagbe awọn ounjẹ tabi nkan didun to wu ọ jẹ tẹlẹ ṣugbọn to le ṣe akoba fun oyun inu rẹ nigba naa.
To ba di ọrọ asajẹ ninu oyun, o ṣeeṣe ko ni aṣa to rọ mọọ: Oyun kii se nkan to rọrun rara, o si maa n gba asiko eniyan, o tun jẹ ohun to nira lati la kọja ti ko ba si oluranlọwọ nitosi eeyan.














