Biafra at 51: Àwọn àgbààgbà ní àwọn ohun tó pilẹ̀ ogun abẹ́le kò tí dópin ní Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Biṣọọbu ijọ Aguda nipinlẹ Sokoto, Alufa Matthew Kukah atawọn eekan ilu mii ti sọ pe, o ṣe e ṣe ki Naijiria tun koju ogun abẹle miran, ti ko ba ṣe awọn nkan to yẹ.
Wọn sọ eyi nibi ijiroro ori ayelujara kan to waye lati ṣami ọdun kọkanlelaadọta ti ogun abẹle Biafra pari, eyi to ko loni ọjọ Kẹẹdogun osu kinni.
Ọ̀dun 1967 si 1970 ni ogun Biafra waye laarin ijọba Naijiria ati awọn eeyan ẹya Igbo to n beere fun dida orilẹ-ede Biafra silẹ.
Ninu ọrọ rẹ, Kukah to jẹ oludanilẹkọ nibi ijiroro naa sọ pe, Naijiria ko ti i kọ ẹkọ kankan lara ogun abẹle naa.
Wọn fikun pe idẹyẹsi ati ifiyajẹni ti awọn ẹya kan ni Naijiria n pariwo lati igba ogun Biafra ṣi wa titi di oni.
Bakan naa ni oludije fun ipo igbakeji aarẹ ninu eto idibo ọdun 2019, Peter Obi sọ pe, oju ọna kan naa ni Naijiria ṣi n tọ.
Amọ ojuọna ọhun paapaa ti bajẹ ju bo ṣe wa ni atẹyinwa.
"Ti ẹ ba wo nkan to ṣẹlẹ nigba naa to gbe Naijiria de ikorita ogun Biafra, awọn nkan to n ṣẹlẹ bayii buru ju bẹẹ lọ."
Ẹwẹ, Olori ẹgbẹ Afẹnifẹre, Oloye Ayo Adebanjo naa sọ pe, ofin ti Naijiria n lo gan-an ni orisun iṣoro.
O ni idajọ ododo ti ko si, ko ṣẹyin aarẹ to n ri daju pe awọn eeyan Ariwa nikan lo wa ni awọn ipo to se pataki.
Ijọba àpàpọ̀ kìlọ̀ fẹ́gbẹ́ Mùsùlùmí láti máṣe lé àlùfáà kúrò ní Sokoto

Oríṣun àwòrán, @Gidi_Traffic
Ijọba apapọ ti kilọ fun awọn ẹgbẹ Musulumi kan pe wọn ko lẹtọ labẹ ofin lati le Biṣọọpu ijọ Katoliki fun ẹkun Sokoto, Mathew Kukah, kuro nipinlẹ naa nitori awọn ọrọ kan to sọ.
Ninu atẹjade kan ti olubadamọran pataki si Aarẹ Muhammadu Buhari lori ọrọ iroyin ati ipolongo, Garba Shehu fi ṣọwọ si awọn akọroyin, lo ti kede bẹẹ.
Atẹjade naa ni, bo tilẹ jẹ pe lootọ ni alufa ọhun ti ṣẹ awọn eeyan kan, ṣugbọn ko ba ofin mu ki wọn sọ fun pe ko kẹru rẹ kuro ni Sokoto.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Irú ẹ̀dá wo ni Lamidi Adeyemi? Aláàfin tó rí ìbẹ̀rẹ̀ àti opin sáà gómìnà mọ́kànlélógún l‘Oyo
- Seyi Makinde ní ọwọ́jà Covid-19 kò rinlẹ̀ bí NCDC se kéde èèyàn 120 tó ní àrùn lọ́jọ́ kan l‘Oyo
- Njẹ́ ẹ ti gbọ́ nípa àríyá oníhòhò àti ìbálòpọ̀ tó fẹ́ wáyé ní Kaduna lásìkò ọdún?
- Ìjọba gbé ilé ijó oníhòhò tì pa lórí ẹ̀sùn títàpá sí ìlànà àti dẹ́kun coronavirus
- Ilé aṣòfin Amẹ́ríkà yọ ààrẹ Donald Trump nípò fún ìgbà kejì
- Ìdí mẹ́fà rèé tí Instagram, Facebook le fi wọ́gilé ojú òpó ìkànsíraẹni rẹ
- Ìdí tí àwọn èèyàn kan kò fí le ni àrùn Coronavirus
O ni Alufa naa lẹtọ labẹ ofin lati ṣe ẹsin to ba wu ati lati ṣe oṣelu nibikibi to ba yan ni Naijiria.
Shehu ni o lodi si ofin Naijiria ki awọn eeyan kan gbe igbesẹ lati le alufa naa kuro ni Sokoto, nitori pe ohun to n ṣe ko dun mọ wọn ninu.

Oríṣun àwòrán, @Gidi_Traffic
O ni "Gbedeke ti awọn ẹgbẹ Musulumi kan fun Mathew Kukah pe ko tọrọ afiriji lọwọ awọn Musulumi lori ọrọ to sọ laipẹ yii, tabi ko fi ilu Sokoto silẹ jẹ eyii to to buru jọjọ, o si tun lodi si ofin orilẹ-ede Naijiria.
"Labẹ ofin ilẹ wa, gbogbo ara ilu lo lẹtọ lati sọrọ bo ṣe wu wọn, bakan naa ni wọn lẹtọ lati ni dukia ati lati rin nibikibi to ba wu wọn nilẹ Naijiria lai si pe awọn kan n dun mọhurumọhuru mọ wọn."
Bẹẹ lo tun sọ siwaju si pe lootọ ni pe alufa naa ti ṣẹ awọn eeyan kan nipa bo ṣe maa n sọrọ lodi si ijọba to wa lode ati si Aarẹ Buhari, ti awọn kan si ti fẹsun kan pe o n dana ija ẹsin, ṣugbọn suuru ni awọn adari maa ni niru akoko bayii.
Shehu ni ilu Sokoto ni ibaṣepọ to dan mọran pẹlu awọn eeyan to ni oniruru ẹsin, nitori naa ki awọn eeyan kan maṣe gbiyanju lati da iru ibaṣepọ bẹẹ ru lasiko yii.
Shehu pari atẹjade naa pe, ki awọn ẹgbẹ to ba n binu fi ọwọ wọnu, ki wọn si gba awọn ẹlomiran laaye lati sọ ohunkohun to ba wa ninu wọn.
Lẹyin naa lo rọ alufa Kukah pe ko bọwọ fun ẹtọ ati ẹsin awọn ẹlomiran ninu awọn ọrọ rẹ, yala ni gbangba tabi ni kọrọ inu ile rẹ.












