Kaduna sex party: Mọ̀ si nípa àríyá oníhòhò àti ìbálòpọ̀ tó yẹ́ kó wáyé ní Kaduna

Oríṣun àwòrán, ABDUL85 / TWITTER
Awọn ọlọpaa ti mu awọn to ṣe agbatẹru ariya ibalopọ ti wọn polongo rẹ pe yoo waye nipinlẹ Kaduna, lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2020.
Oluranlọwọ pataki fun gomina ipinlẹ Kaduna lori eto iroyin ati ibaraẹnisọrọ, Abdallah Abdallah fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fun BBC pe lootọ ni ọwọ tẹ awọn eeyan naa.
O ni "nọmba ẹrọ ibaraẹnisọrọ ti wọn fi si ori iwe ipolongo ariya naa ni wọn fi tọpasẹ wọn, ti ọwọ fi tẹ wọn".
Bakan naa ni agbẹnusọ un ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kaduna, ASP Mohammed Jagile sọ pe lootọ ni.
- Ta ló fipá bá Jennifer lò pọ̀?
- Èèmọ̀ rèé! Àṣírí ilé tí wọ́n ti ń fipá bá àwọn ọmọdékùnrin lò tú síta
- Ọdún méjì, wàhálà méjì lójúbọ Osun Osogbo,
- Wo bí o ṣe lè ṣe eré ìdárayá tí yóò fún ọ ní adùn àti okun fún ìbálòpọ̀
- Àráàlú yarí fún fásitì Babcock fún bo ṣe lé akẹ́kọ̀ọ́ tí wọn bá lòpọ̀ nínú fídíò
- Ìbálòpọ̀ ọ̀lọ́jọ́ méje mú kí ilé ẹjọ́ tú ìgbéyàwó ọdún mẹ́wàá ká ní Ibadan
Bawo lo ṣe yẹ ki eto naa lọ?
Gẹgẹ bi nkan ti wọn kọ si ori iwe ipolongo fun ariya naa, awọn ti yoo ba wa sibẹ gbọdọ wa ni ihoho goloto.
Oriṣiriṣi ere idaraya lo yẹ ko waye
Ounjẹ loriṣiriṣi.
Pabanbari ibẹ ni pe ibalopọ yanturu ni gbangba ati kọọrọ naa yoo waye nibẹ.
'Iru nkan bayii ko ṣẹlẹ ri nipinlẹ Kaduna'
Habu Muazu, to jẹ ọmọ jayejaye, to tun jẹ olugbe nipinlẹ Kaduna lati bi ọdun mẹẹdọgbọn, sọ fun BBC pe, igba akọkọ niyii ti oun ri iru nkan bẹ ẹ ri lati igba ti oun ti n lọ sile ijo.
"Ko si ile ijo alaalẹ ti mi o mọ ni Kaduna. Ko si si iru ariya ti mi o ti i lọ lati bi ogun ọdun, amọ iru eyi ti awọn eeyan naa fẹ ṣe kan fẹ ba orukọ rere ti iru awọn eeyan bi temi to n fi iwa ọmọluabi jaye ori wa, jẹ ni."
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìjà àgbà méjì! Àlàyé rèé lórí ááwọ̀ Femi Fani-Kayode àti Tunde Bakare
- Ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn mẹ́ẹ̀dógún wọ gàù ọlọ́pàá ségí ní Eko
- Àwọn àjàkálẹ-àrùn tó ti wáyé rí ṣáájú Coronavirus
- Ta ni Ọ̀jọ̀gbọ́n àkọ́kọ́ nípa ìmọ̀ ọ̀daràn ní Nàíjíríà, Femi Odekunle tí Covid-19 pa?
- Ikú Adewole Oniluola, tó ní ẹ̀bùn ìlù lílù jùlọ lágbàyéé, yóò nípa lórí Yorùbá - Tunde Kelani
- Ayinla Ọmọwura, orin èébú àti oríyìn lo fi di ọ̀rẹ́ àwọ̀n obìnrin
- Ẹ wo ojú àwọn afurasí tí yóò rojọ́ ẹ̀ṣùn àjẹbánu lọ́dún 2021
- Bí Nàíjíríà bá fẹ́ kí ọdún 2021 dára, ohun tí yóò ṣe rèé - Obasanjo
- Ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ méjì fìjà pẹẹ́ta, ẹ̀mí kan bọ́, ọ̀pọ̀ farapa
O ni o dara bi ijọba ati awọn ọlọpaa ṣe tete gbe igbesẹ, nitori pe eto naa ko ba fun awọn eeyan mii ni igboya lati tun ṣe bẹ ẹ.
Ọrọ ariya naa si ni ọpọ eeyan n jẹ l'ẹnu lori ayelujara, pe o dara bi ijọba ṣe dawọn duro.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1

End of X post, 2

End of X post, 3