Femi Odekunle: Àwọn ohun mánigbàgbé ti ọ̀jọ̀gbọ́n náà gbé ile ayé ṣe rèé

Ọjọgbọn Femi Odekunle

Oríṣun àwòrán, @agbahor_aghogho

Iroyin iku Ọjọgbọn akọkọ lori imọ nipa iwa ọdaran lorilẹede Naijiria, Femi Odekunle, lo ja ranyin-ranyin lori ayelujara, lẹyin to lugbadi arun Coronavirus.

Ọjọgbọn Odekunle ni iroyin sọ pe o dagbere faye ni ibudo iyasọtọ fun awọn alarun Coronavirus to wa ni Gwagwalada ni ilu Abuja.

Odekunle si lo jẹ ọkan lara awọn ikọ olubadamọran fun Aarẹ Buhari lori igbogun ti iwa jẹgudujẹra lawujọ, Presidential Advisory Committee Against Corruption, PACAC.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọpọlọpọ eniyan to fi mọ aarẹ Buhari lo n ṣe idaro ẹni nla to re ibi agba n re naa, ni ẹni ọdun mẹtadinlọgọrin.

Ọjọgbọn Femi Odekunle

Oríṣun àwòrán, @agbahor_aghogho

Ọjọgbọn Odekunle nigba aye rẹ rọ awọn ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ, lati ri wi pe wọn ṣewadii awọn adari to fi mọ awọn ologun lai yọ ẹni kankan silẹ.

Eyi ni awọn nkan to yẹ ko mọ nipa Ọjọgbọn Femi Odekunle:

  • Ọjọgbọn Femi Odekunle lọ si ileewe alakọbẹrẹ ni Otapete Methodist School ni ọdun 1955 ati ileewe girama ni Ilesha Grammar School ni ọdun 1962
  • Odekunle lọ si ile iwe giga fasiti ti Ibadan ni ọdun 1965 si 1968, ki o to lọ kawe ni ọke okun ni fasiti Ivy League's University of Pennsylvania, Philadelphia, USA (1969-1974), to si kẹkọ imọ oye nipa iwa ọdakan ati ihuwasi ọmọ eniyan
  • Lẹyin ti wọn ti ṣiṣẹ olukọ fasiti fun ọdun meji ni orilẹede Amerika ni fasiti, Lincoln, lo wa pada wa si Naijiria ni ọdun 1974 nibi to ti ṣiṣẹ olukọ ni Fasiti Ahmadu Bello University
  • Ọgbọn ọdun ni Odekunle fi ṣiṣẹ gẹgẹ bi ọjọgbọn to si ṣiṣẹ karakara ni awọn ipo to dimu
  • Gẹgẹ bi onimọ nipa iwa ọdaran,, o ti kọ iwe lorisirisi lori ọna ati mu adinku ba iwa ọdaran lawujọ ati bi itẹsiwaju ṣe le ba awọn eniyan lawujọ
  • Lasiko ijọba ologun Sani Abacha ni ọdun 1993- 1998 ni Odekunle di olubadamọran pataki fun ọgagun ọhun, to si ṣiṣẹ ni ọfiisi igbakeji Abacha, iyẹn Ọgagun Diya
  • Nitori naa lasiko ti idukoko iditẹgbajọba gbode kan laarin Abacha ati Diya, Femi Odekunle di ero ẹwọn pẹlu ọpọlọpọ ifiyajẹni
  • Oṣu Kejila, ọdun 1997 ni wọn gbe e lọ si ẹwọn, ti ko si jade kuro nibẹ titi di ọjọ Karundinlogun, Osu Keje, ọdun 1998, lẹyin ti Abacha jade laye.