Olusegun Obasanjo: Ẹ máṣe bú Ọlọ́run torí ọrọ̀ ajé tí kò dára àti òṣì tó gbalẹ̀ ní Nàíjíríà

Olusegun Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Olusegun Obasanjo Presidential Library

Aarẹ ana ni Nigeria, Olusegun Obasanjo ti woye pe orilẹede yii ko se awọn ohun to tọ lati mu mu agbega ba ọrọ aje rẹ to mẹhẹ, ko si mu adinku ba isẹ ati osi.

Oloye Obsanjo woye ọrọ yii ninu isẹ to fi ransẹ fun ibẹrẹ ọdun tuntun, to si wa n sekilọ pe kawọn asaaju Naijiria dẹkun didi ẹbi isẹlẹ aisi eto aabo to peye, ọrọ aje ti ko dara, osi atawọn ipenija miran to n ba ilẹ yii finra, ru Ọlọrun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Pẹlu ọpọ ohun alumọni to wa lorilẹede yii, ko yẹ ki Naijiria wa lara awọn otosi orilẹede, bẹẹ si ni ko yẹ ki awo ijọba abi ọmọ Naijiria kankan sun ninu ebi.

Olusegun Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Olusegun Obasanjo Presidential Library

Mo fẹran akọmọna ileewe kan to ni sisẹ ko si gbadura, sugbọn fun awọn eeyan miran, gbadura ko to sisẹ ni, bi o tilẹ jẹ pe ọna tẹ gba gbe ọrọ yii kalẹ kọ ni koko.

Ohun to se pataki ni pe kẹ sisẹ, isẹ sise ati adura gbigba gbọdọ lọ papọ ni."

Obasanjo wa tẹnumọ pe o yẹ ka sisẹ lorilẹede yii, gẹgẹ ba se n gbadura ninu ọdun tuntun 2021, ko le jẹ ọdun ologo fun wa, amọ lai jẹ pe a sisẹ, eyi ko le ri bẹẹ.

Àkọlé fídíò, 2020 in Retrospect: Ìjàmbá iná, ilé tó dàwó, ìwọ́de àti àrùn Covid-19 wà lára ìṣẹ̀lẹ̀ 2020

Aarẹ tẹlẹ ni Naijira naa wa fikun pe, awa ara wa lo yẹ ka bu nitori ipo ti orilẹede wa wa bayii, kii se Ọlọrun, ohun tawọn alasẹ ati ero ẹyin ni Naijiria yan ree.

Obasanjo wa gbadura pe Ọlọrun yoo mu ki ọdun tuntun 2021 dara fun wa amọ isẹ sise nikan ni amin rẹ.

Ìdí rèé tí ẹ̀mí mi kò fi bọ́ sínú ìdìtẹ̀ gbàjọba tó pa Muritala Muhammed - Obasanjo

Olusegun Obasanjo ninu asọ ologun ati ọkọ ti wọn fi pa Muritala

Oríṣun àwòrán, Olusegun Obasanjo Presidential library

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe, Aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹri, Ọgagun Oluṣẹgun Obasanjọ, ti salaye bo ṣe jajabọ lọwọ ogun iditẹ gbajọba to waye lọdun 1976, ti ọgagun Buka Dimka dari rẹ.

Ọbasanjọ ni Ajagunfẹhinti Olu Bajọwa lo gba oun la lọwọ awọn aditẹgbajọba naa, lọna ti Bajọwa fun ara rẹ ko mọ.

O sọ ọrọ yii lasiko ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọrin ọdun Olu Bajọwa to waye ni ilu Igbotako, ni ijọba ibilẹ Okitipupa, ni ipinlẹ Ondo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹri, Ọgagun Oluṣẹgun Obasanjọ wa sapejuwe Bajọwa gẹgẹ bi ẹni to ni irẹlẹ ọkan, to si n bọwọ fun agba.

Obasanjọ ni nigba ti ogun iditẹgbajọba Dimka waye ni ọdun 1976, ọpẹlọpẹ ipa ti Bajọwa ko lọjọ naa lọhun, lo ko oun yọ.

Baba Obasanjo ati Bajowa

Oríṣun àwòrán, TWITTER

''Lasiko ti iditẹgbajọba naa waye ni Bajọwa bi ọmọ ọkunrin jojolo, ti o si fẹ sọ ni orukọ mi, nitori naa o sọ wi pe, oun n bọ wa si ile ọdọ mi.

Eyi lo mu ki n tẹsẹ duro de, to si jẹ ki n pẹ ju asiko ti mo maa n jade kuro ninu ile lọ, owurọ ọjọ naa ni Dimka ṣọṣẹ."

Obasanjo fikun pe nigba ti Bajọwa de, to si beere pe oun fẹ sọ ọmọ tuntun naa ni orukọ oun, o ni oun fun aṣẹ lati lo orukọ oun.

"Nitori naa mi o gba ọna ti mọ ma n gba nitori mo ti pẹ, awọn sọja naa si ṣẹsẹ kọlu Reinumuje to gba ọna ti mo maa n gba tẹlẹ, wọn ro wi pe emi ni mo wa ninu ọkọ naa.'

Olusegun Obasanjo ninu asọ ologun

Oríṣun àwòrán, Olusegun Obasanjo Presidential library

Wọn yinbọn lu ọkọ rẹ, wọn si pa Murtala Muhammed ninu iditẹ-gbajọba to waye ọhun, bi Bajọwa ṣe gba mi la lọwọ awọn aṣekupani niyẹn.''

Baba Obasanjọ tun sapejuwe Olu Bajọwa gẹgẹ bi ẹni to jẹ akinkanju ologun, to si saaju ọwọ kọkanla ikọ ọmọ ogun ilẹ wa, 11 battallion, lasiko ogun abẹle to waye lorilẹede Naijiria.

Àkọlé fídíò, Jude Chukwuka: Wò ó bí òwé Yorùbá ṣe yọ̀ lẹ́nu ọmọ Igbo