2020 in Retrospect: 'Mummy Calm down', 'Sọrọ soke were' àtàwọn àṣà tó milẹ̀ lọ́dún 2020

Aworan Ooreoluwa ati ami idamọ Sorosoke

Oríṣun àwòrán, Getty Images/ooreoluwa

Ni ọdun 2020, ko si ẹni ti ko mọ pe ilẹ rọ, paapaa julọ pẹlu ajakalẹ aarun COVID-19 ati awọn oniruuru wahala miran to waye kaakiri agbaye.

Lara awọn laasigbo naa la ti ri Black lives matter ati ENSARS amọ sibẹ sibẹ, ko ṣai si awọn asiko tabi idi diẹdiẹ fun idaraya ati idaraẹni ninu dun ninu ọdun yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lara awọn idaraya to waye lọdun 2020 lawọn aṣayan aṣa to gbode laarin rẹ, eleyi to mu ẹrin ati ipenija dani, bẹẹ ni awọn miran mu ijigiri dani pẹlu.

Ẹ jẹ ka mu diẹ lara awọn aṣa wọnyii ni ṣisẹ n tẹle:

Mummy Calm down:

Mummy Calm down

Hmmm, bi eniyan ba wo bi aṣa yii ṣe bẹrẹ, bi ẹrin bi ere naa ni.

Ọmọdekunrin kan Ooreoluwa, ni iya rẹ n ba wi fun aigbọran to hu, amọ ṣa nibi ti ọmọ naa ti n gbiyanju ati bẹẹ iya rẹ, lo ti n pariwo "Mummy calm down".

Iya rẹ lo ya fidio ẹbẹ rẹ yii, to si fi ransẹ si ẹgbọn rẹ lati jẹ ko mọ iru alawada ti Ooreoluwa jẹ.

Gomina Babajide Sanwo-Olu ati Ooreoluwa

Oríṣun àwòrán, Instagram/babajidesanwoolu

Ẹgbọn iya rẹ naa si lo gbe fọnran aworan ọhun sori ayelujara eleyi to tan kaakiri agbaye, to fi sọ ọmọdekunrin naa di ilumọọka, koda, gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu gan kan si ọmọdekunrin naa.

Lati igba naa ni "Mummy calm down" ti di aṣa to gbajugbaja.

Koda awọn oloṣelu lo o fun ipolongo ibo, bẹẹ ni awọn ileeṣẹ kaakiri lo aṣa naa fun ipolowo ọja ati itaniji paapaa lasiko ti ajakalẹ arun COVID-19 gbalẹ kan.

"Sọrọ soke were, maa disguise":

Obinrin kan gbe ami idamọ Sorosoke lọwọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ara awọn aṣa to milẹ lasiko iwọde #EndSARS niyi.

Koda, asa naa lo di ọrọ akọmọna fun awọn oluwọde to n pe fun iwọgile ikọ ọlpaa SARS naa kaakiri orilẹede Naijiria ati loke okun nigba naa.

Gbogbo oluwọde, koda awọn ti ko gbọ ede Yoruba, gan pẹlu n pariwo sọrọ soke' nigba ti iwọde ọhun fọnna soju to bẹẹ gẹẹ, to si wa di ohun apejuwe fun iran ọdọ iwoyii.

Awọn oluwọde EndSARS kan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ọrọ akọmọna naa, eyi to n se iwuri fun awọn ọdọ lati mase dakẹ tabi panumọ lori iwakiwa lo mu ki wọn maa pe iran iwoyi ni "Sọrọsoke generation" bayii.

Kwarantain tabi Qurantine lede oyinbo:

Awọn oṣiṣẹ ilera kan n fin ilẹ

Oríṣun àwòrán, Anadolu agency

Aṣa yii jade lasiko ti ajakalẹ aarun COVID-19 wọ orilẹede Naijiria, ti ijọba si n ko awọn to ba ṣẹṣẹ ti ilẹ okeere de pamọ si igbele, eleyii ti wọn n pe ni Qurantine lede Gẹẹsi.

Ẹ jẹri awọn ọmọ Naijiria, ko pẹ pupọ ti wọn fi gba eyi gẹgẹ bi aṣa lati maa lo fun ẹni ti wọn ba fẹ pa ti si ẹgbẹ kan.

Fun apẹẹrẹ wọn lee ni, "Mo ma ti Kwarantain (qurantine) ọrọ yẹn.

Ma ko paliatifu (Palliative) mi:

Awọn eeyan kan n ko apo iresi

Oríṣun àwòrán, Twitter/oluwaseunfunmi

Lara awọn aṣa to gba ibi ajakalẹ arun COVID-19 lorilẹede Naijiria yọ naa leyii, bi o tilẹ jẹ wi pe lẹyin ti ọwọ kini ajakalẹ arun naa ti n rọlẹ lo waye.

Bakan naa lo tun nii ṣe pẹlu iwọde #EndSARS to waye loṣu kẹwaa ọdun 2020.

"Palliative' lawọn ohun arẹmọlẹkun ti awọn ileeṣẹ aladani pa owo pọ ra fun mimu aye dẹrun diẹ fun araalu lasiko igbele COVID-19 nigba naa.

Amọṣa, lasiko ti iwọde #EndSARS gba ibomiran yọ, tawọn janduku ja a gba mọ awọn to ṣeto rẹ lọwọ, lawọn eeyan fi bẹrẹ si ni ja awọn ile ikẹrusi kaakiri nigba naa.

Eyi lo mu ki aṣa yii jẹyọ pe "Ma ko Palliative mi" O tumọ si ma ko mi ni nnkan lọ. Fun apẹrẹ, "Alaye ko fi ọgbọn ko paliative mi jọọ."

We move:

Awọn oluwọde EndSARS kan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Lasiko iwọde #EndSARS ni eyi jẹyọ.

Lasiko ti iwọde naa ṣi n lọ ni irọwọrọsẹ, ti awọn oluwọde n bẹ awọn ile ijọba wo lati fi ẹhonu wọn han si aye familete n tutọ awọn ọlọpaa kogberegbe SARS.

Asiko naa si ni awọn ọdọ to n sewọde maa n pariwo "We move" ti wọn ba ti fẹ kuro ni ibudo kan si ikeji.

Amọ ṣa, lẹyin iwọde yii lawọn eeyan kuku sọ ọ di aṣa, ti aṣa "We move" fi gberassọ titi de aarin awọn ọmọ Naijiria to wa loke okun pẹlu.

Mad o:

Shoprite Ilorin

Eyi tun ni aṣa miran to gbaye kan lọdun 2020 yii, aṣa yii si jẹ ọrọ iyanu.

Asiko ti wọn maa n lo aṣa yii ni igba ti nnkan iyanu ba ṣẹlẹ, ti awọn eeyan lee ṣe haa si.

Dipo ki wọn pariwo haa, ni wọn a maa pariwo "mad o".

Diẹ lara awọn aṣa to la'lẹ hu jade lọdun 2020 ree, ewo lẹyin mọ ti ẹ lee fi kun un?