Bone straight hair: Èlò ló bá dé, ibí tí wọ́n tí n ta àti ìbéèrè mí nípa irun àlàfẹ̀ yí

Bone Straight Hair:

Oríṣun àwòrán, Teni/Instagram

Àkọlé àwòrán, Olorin Teni naa ba wọn kọwọrin lati fi irun yi ṣakọ loju opo ayelujara rẹ

Bi wọn baa n darukọ awọn ohun ẹṣọ ati oge tawọn obinrin n ran lẹnu ni Naijiria lẹnu lọọlọ yi, o di dankan ka darukọ Bone Straight Hair Wig.

Bẹẹ ni, bẹrẹ lọdọ awọn Slay Queen to fi dori awọn Mama o ni gba, niṣe ni wọn n fi irun afikun yi da awọn eeyan lọrun lori ayelujara.

Ninu awọn to ba wọn kọwọrin irun oge yi ni Tenimakanaki, gbajugbaja akọrin ọmọ Naijiria wa.

Loju opo rẹ lori ayelujara, niṣe lo fi aworan ara rẹ han pẹlu irun yii to si pe akọle rẹ ni ''SUGARMUMMY''

"Bone Straight Hair" -Ki gaan lo n jẹ bẹ?

Irufẹ irun awọsori fawọn obinrin ni Bone straight jẹ to si gun daada bẹẹ lo tun lẹ lọwọ.

Nkan ta gbọ ni pe iru irun yi wa lorisirisi ni bo ti ṣe gun si. Awọn kan gun diẹ tawọn mii si gun gidi gaan.

Amọ ṣa ohun to jẹ iyalẹnu gẹgẹ bi aṣaraloge kan ti ṣe sọ fun BBC ni pe ''Bone Straight Hair'' ti wa tipẹ. Kii ṣe tuntun.

O ni ṣugbọn ''igba laye, asiko ti Bone Straight Hair lo de tawọn eeyan fi n ran ọrọ rẹ lẹnu.''

Ni ṣoki, gbogbo awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa irun afikun yi ree:

Elo ni wọn n ta Bone Straight Hair ni Naijiria?

Bi o ba ti ṣe gun si, irufẹ rẹ ati iwọn rẹ ni wọn fi n ta iru irun yi ni Naijiria.

O le ri irun yi ra ni nkan bi ẹgbẹrun lọna ọgọta Naira si ẹgbẹrun lọna ọọdunrun Naira tabi ju bẹẹ lọ.

Irufẹ irun Bone Straight Hair to wa

Teni di entertainer

Oríṣun àwòrán, tenimakanaki Instagram

Oloju kan Single Drawn[Bone Straight Hair]: Eleyi ni orisi irun ti wọn papọ ninu afikun irun naa.

Iru irun yi maa n ki dada lọwọ oke, bo ba de aarin, yoo diku to ba si wa kan isalẹ yoo tinrin gaan.

Owo tiẹ ko gunpa bi awọn irun Bone Straight to ku.

Alakanpọ meji Double Drawn [Bone Straight Hair]: Bakan naa ni iwọn gigun irun yi ṣe maa n ri.

Itumọ rẹ ni pe o kun loke, o kun laarin ati ni isalẹ sugbọn o wọn diẹ ju alakọkọ oloju kan lọ.

Onipele akanpọ Super Double Drawn [Bone Straight Hair]: Bi ẹ baa n gbọ pe o pọ, pọ pọ, irufẹ irun Bone Straight yi lo n jẹ bẹ.

Ninu ida ọgọrun, o kere tan o maa n ni ida marundinlaadọrun si ida aadọrun ti wọn gun bakan naa.

Bi o ba wọ iru irun taa n wi yii, yoo da bi ẹni pe irun rẹ gangan lo de sori. Ọga patapata awọn irun Bone Straight leyi jẹ.

Aworan Teni

Oríṣun àwòrán, Teni di Entertainer

Bi o ko ba si lowo lọwọ daada, ma ṣe ba wọn daṣa pe o fẹ ra iru irun yi.

Ibi to ti le ra irun [Bone Straight Hair] ni Naijiria?

O le ri irun yi ra lọdọ awọn to n ta irun paapa awọn to n gbe wa lati ilẹ Asia.

Lati ọdọ awọn to n gbe wa lati China, Vietnam ati awọn mii to wa ni Naijiria o le ri ra lọdọ wọn.

Ohun kan to maa n jẹ ki awọn obinrin maa fẹ ṣe ara wọn leṣe lori iru irun yi ni iye ti wọn n ta wọn.

Ibi owo rẹ ba mọ loo fi gbadun irun yii si lọrọ to wa nilẹ.