Xmas Cuisine: Wo àwọn oúnjẹ oúnjẹ aládùn 10 tó gbayì lásìkò Kérésì

Oríṣun àwòrán, www.eatdrinklagos.com
Igba ọdun jẹ asiko tawọn eeyan maa n pejọ lati yọ ayọ ẹmi to rẹyin ọdun.
Lasiko ọdun 2020 ti ọpọ ewu ree awa taa ṣẹku kọja ko si ohun to yẹ ju ki a pe apejẹ pẹlu awọn ẹbi ọrẹ ati ojulumọ.
Njẹ ẹyin ni ipalẹmọ kankan ti ẹ n ṣe lati gbalejo lasiko ọdun yi, ki si ni iru ounjẹ ti ẹ fẹ fi dawọn lọrun?
Bi ko ba tii mọ ounjẹ tẹ fẹ se, ẹ jẹ ki a ya yin lawọn ounjẹ aladun mẹwaa kan ti o jẹ arimalejẹ paapa lasiko ọdun yi
Jollof Rice
Bi wọn ba ni ka pe ogunagbongbo ounjẹ tawọn eeyan yan laayo lasiko ọdun yi, oke tente ni jọlọọfu yoo wa.
Kaakiri Naijiria ati lawọn orileede miran ni ilẹ Afrika ni ounjẹ yi ti jẹ gbajumọ ounjẹ ti awọn eeyan a maa fi ṣe inawo tabi ki wọn kan se fun jijẹ ni ile.

Oríṣun àwòrán, @EarlJoey_.
Bi ẹ ko ba ti ni awọn eronja lati fi ṣe jọlọ yin ti yoo maa fi ta sansan, ẹ tara ṣaṣa lọ si ọja lati lọ ra ki ọrọ ma ba di gobe lọjọ ọdun.
Bi ẹ ba ti ṣe tan, ẹ ma gbagbe lati fi tiwa naa ranṣẹ!
Ila alasepọ
Bẹẹ ni. Ti o ba ti to ọjọ mẹta ti ẹ ti jẹ okele kẹyin nitori pe iṣẹ ko gba yin laaye lati peelo rẹ, asiko ọdun yi dara lati se ila alasepọ.
Bo ba ṣe amala lẹ fẹ fi lo ni tabi iyan ko si eleyi ti ko lọ pẹlu rẹ.

Oríṣun àwòrán, TPC
Lasiko taa wa yi, ila ko wọn pupọ lọja ṣugbọn awọn isọmọgbe ti yoo jẹ ki ila alasepọ yin ta lẹnu daada le fẹ gunpa diẹ.
Amọ ko si bo ti ṣe le wu ko jẹ, eeyan yoo ri tiẹ ra lọja.Bo ṣe ẹja gbigbẹ ni tabi aṣamọ ẹgun, bo si jẹ bokọtọ tabi adiẹ lẹle fi se ni, ko si eyi ti ko lọ.
- Àwọn ohun tó yẹ kí o ṣe àti èyí tí kò yẹ kí o ṣe lásìkò ọdún Keresimesi rèé
- Kíló kàn lẹ́yìn tí ẹgbẹ́ ASUU àti ìjọba fẹ́nu ọ̀rọ̀ jóná lẹ́yìn oṣù mẹ́sán-an?
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ayédèrú Ahmed Musa tó ń lu àwọn èèyàn ní jìbìtì
- Wo ìdí tí Teni, ọ̀dọ́mọdé olórin obìnrin kìí fi ń ṣí ìhòhò rẹ̀ silẹ̀
- NIMC registration portal: Wo ọ̀nà tí o le gbà rí fọ́ọ̀mù ìforúkọsílẹ̀ fún NIN rẹ gbà àti àwọn ibùdó ìforúkọsílẹ̀ lágbáyé
Egusi
Bo se eleyi to di ti ẹ ko ni nilo ẹran ninu ọbẹ lẹ fẹ ni tabi eyi to toro mọ ẹfọ, ko si iru ẹgusi ti ẹ se lasiko ọdun ti awọn eeyan ko ni jẹ igbadun rẹ.
Iyan lawọn eeyan maa n saba fi jẹ ẹgusi paapa lasiko ọdun ṣugbọn awọn ẹlomi ko kọ lati fi jẹ Sẹmo tabi ẹba.

Oríṣun àwòrán, @others
Koda mo mọ eeyan kan to ṣe wi pe o le fi ẹgusi jẹ amala. Gbogbo rẹ lo lọ ko si wahala.
Ẹfọ a maa lọ pẹlu ẹgusi naa plu adiẹ tabi ogunfe.
Asaro elepo rẹdẹrẹdẹ
Orin Orlando Owoh lo wa si ọkan bi a ti ṣe mẹnu ba asaro ninu apilẹkọ yi.
Iṣu la fi n se asaro sugbọn gegẹ bi gbogbo ounjẹ, eronja ta ba fi sinu rẹ la maa mu ki adun rẹ jade ju ara wọn lọ.
Awọn kan a maa fi ede sinu asaro ti wọn ko si ni fọ iṣu inu rẹ pupọ.

Oríṣun àwòrán, thepretendchef.com
Ninu idile miran ẹja tabi ẹran pẹlu ẹfọ ni wọn a maa fi se asaro.
Bi o ba ti to ọjọ mẹta ti ẹ farabalẹ se asaro, asiko ọdun yi jẹ igba ti ẹ le fi ṣapọnle awọn tiyin ti wọn a si maa pọnu la lẹyin ti wọn ba jẹ ẹ tan.
Iresi Ọfada
Ọba ni Jọlọọfu jẹ ninu ounjẹ ṣugbọn lọdọ awọn eeyan kan nilẹ kaarọ o jiire ori irẹsi ọfada ni wọn gbe Ade ounjẹ iyi le lori.
Lati agbegbe Ọfada ni ipinlẹ Ogun ni wọn ti kọkọ gbin in ki o to di kari aye.
Irẹsi ọfada jẹ ti ibilẹ to maa n ṣara loore pupọ gẹgẹ bi awọn kan ti ṣe sọ.

Oríṣun àwòrán, Others
Bi eeyan ba lọ si ibi ṣiṣe ti wọn n pin ounjẹ, witiwiti lawọn eeyan maa n du iresi ọfada ti ki si saba to laarin awọn alejo.
Nitori ifẹ tawọnm eeyan ni si iresi ọfada yoo mu ina awọn mọlẹbi rẹ dun ti o ba le dawọn lọrun pẹlu ofada lasiko ọdun yi.
Bi ẹ ko ba mọ bi wọn ti se n se iresi yi, ẹ wo fidio to wa ni isalẹ yi fun ẹkunrẹrẹ alaye nipa ounjẹ́ aladun yi.
Ekuru ati Ila
Awọn eeyan wa nilẹ Igbomina ni yoo mọ adun to wa nibi ounjẹ yi.
Ekuru nilẹ Yoruba jẹ ounjẹ tawọn eeyan maa n gbadun pẹlu ọbẹ ila tabi ọbẹ ata.
Bi o ba ṣe ẹni to mọ ọbẹ ata yi ṣe daada ni, o yẹ ki ẹ ba awọn eronja bi ẹja ọfọọrọ, pọnmọ ati nkan inu ẹran bi shaki pade ninu ọbẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Others
Adun to wa ninu ekuru jijẹ yala bi ẹ ba fi ẹkọ jẹ tabi ki ẹ jẹ lasan ko la fiwe.
Lasiko ọdun yi, ẹ le yan ounjẹ yi laayo lati fi mu inu awọn mọlẹbi yin dun.
Awọn ounjẹ miran ti ẹ le gbadun lasiko yi ree:
Egbo ati ẹwa

Oríṣun àwòrán, Others
Ikọkọrẹ

Oríṣun àwòrán, Others
Iyan ati Egusi

Oríṣun àwòrán, PuldeNg


















