Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ọkùnrin tó ń pe ara rẹ̀ ni Ahmed Musa

Oríṣun àwòrán, Kano Police Command
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kano ti tẹ ọkunrin kan to n pe ara rẹ ni balogun ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles, Ahmed Musa.
Wọn ni ọkunrin ọhun ti orukọ rẹ n jẹ Gambo Yakubu ti gba owo ti iye rẹ to ₦700,000 lọwọ awọn eeyan, lẹyin to fi da wọn loju pe oun yoo ba wọn ṣeto ati gba bọọlu loke okun.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, DSP Abdullahi Haruna lo fidi iroyin naa mulẹ fun akọroyin.
O ni "ootọ ni pe afurasi ọhun n ṣiṣe pẹlu ileeṣẹ Ahmed Musa tẹlẹ ki wọn to le danu, lẹyin naa lo lọ ṣe ayederu iwe lati maa fi lu awọn eeyan ni jibiti."
Ṣaaju ni oludari ileeṣẹ ti Ahmed Musa da silẹ ọhun ti kọkọ ta ọlọpaa lolobo nipa afurasi naa nitori bi ọpọ ero ṣe maa n wa sile iṣẹ wọn lati bere owo to gba lọwọ wọn.
Gẹgẹ bi ọrọ ti alukoro ọlọpaa naa sọ, nnkan bii eeyan marundinlogun ni afurasi naa ti lu jibiti lẹyin ti wọn ti fun ni ẹgbẹrun marun un owo fọọmu lati lọ gba bọọlu niluu oyinbo.
Haruna sọ pe "apapọ iye owo to ti gba lọwọ awọn eeyan jẹ ₦ 700,000 to si sọ pe oun ti na owo naa fun awọn ọrẹbinrin oun."









