PTF Nigeria Covid-19: Ààrẹ Buhari ní iṣẹ́ sí wà nílẹ̀ tí ìgbìmọ̀ yóò ṣé kí wọ́n sì wá níbẹ̀ dì 2021

Aworan aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Aarẹ orileede Naijiria Muhammadu Buhari ti fontẹ lu ki igbimọ amuṣẹya lori kikoju arun Covid-19 ni Naijiria PTF maa ba iṣẹ wọn lọ di ọdun 2021.

Eyi ni koko to jẹyọ lyin abajade ipade aarẹ Buhari pẹlu igbimọ yi lọjọ Iṣẹgun nile ijọba lAbuja.

O ni nitori pe itankalẹ arun Covid-19 ti wa n peleke si ti Naijiria ṣi n gbiyanju lati ri abẹrẹ ajẹsara, o di dandan ki igbimọ yi si wa nibẹ di oṣu Kẹta ọdun 2021.

Yatọ si eyi, o ni asiko yi ni '' a gbọdọ ṣa gbogbo ipa ti mo si rọ awọn lọba lọba ati olori sin lati polongo si etigbọ awọn eeyan wa''

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ni ọjọ Aje ni aarẹ Buhari gbẹnu igbimọ naa kede pe ki awọn oṣiṣẹ ijọba apapọ wa joko sile fun ọṣẹ marun un lati le koju itankalẹ arun yi .

Bẹẹ naa ni igbimọ amuṣẹya yi ni ki awọn ileewe wa ni titi pa fun oṣu marun naa.

NCDC

Oríṣun àwòrán, @NCDCgov

Pẹlu bi aarẹ ti ṣe ni ki igbimọ yi tẹsiwaju iṣẹ wọn, o tun ni ki awọn ọmọ Naijiria maa ṣe jafira ki wọn si daabo bo ara wọn paapa lasiko ọdun to de yi.

''Awọn aṣeyọri wa laarin oṣu mẹsan to kọja yi ko gbọdọ ja si asan tori naa mo wo ọrọ yi daada to si dami loju pe yoo kọdi itankalẹ arun yi ati iku awọn eeyan wa''

aWORAN IGBIMỌ PTF

Oríṣun àwòrán, PTF

Ìlànà tuntun ìjọba nítóri Covid-19 yóò pa iṣẹ́ wa lára ṣùgbọ́n ayé ò parẹ́ - Àwọn adarí ayẹyẹ

Segun

Oríṣun àwòrán, Instagram/pauldgoodguy

Àkọlé àwòrán, Olukoni

Lẹyin ti ijọba apapọ kede ilana tuntun lọna ati kawọ ipadabọ ajakalẹ arun Covid-19 ni Naijiria, awọn to n maa n dari ayẹyẹ kan ti sọ pe awọn yoo tẹlẹ ilana ti ijọba gbe kalẹ.

Lara awọn eeyan naa to ba BBC Yoruba sọrọ ni Segun Paul to jẹ adẹrin poṣonu loju opo Instagram, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Olukọni.

Gẹgẹ bi Segun to ni eto kan lati ṣe ni ipinlẹ Eko lọjọ kẹtalogun, oṣu Kejila, ọdun 2020 ṣe sọ, o ni oun ti ṣe adinkun si iye eeyan ti yoo wa nibi eto naa.

Adari ayẹyẹ naa sọ fun BBC pe "ootọ ni pe ilana tuntun ọhun yoo pa iṣẹ wa lara, ṣugbọn idi niyẹn ti a fi din iye ero ti yoo wa nibi eto naa ku".

Segun

Oríṣun àwòrán, @pauldgoodguy

Àkọlé àwòrán, Ilana naa yoo pa iṣẹ wa lara ṣugbọn aye o parẹ

Segun tẹsiwaju pe oun atawọn oṣiṣẹ oun yoo rii daji pe gbogbo awọn to wa nibi eto naa ni wọn tẹle ilana ti ajọ NCDC gbe kalẹ lati dena ajakalẹ arun ọhun.

Àkọlé fídíò, Ṣé ẹ mọ̀ pé àṣà nílẹ̀ Yorùbá ni ìwà ọmọlúàbí?

O ni "oun ti a fẹ ṣe ni lati ṣe faaji ati wẹjẹ-wẹmu pẹlu awọn eeyan, kii ṣe pe a n reti ero pupọ."

"Gbogbo oun to yẹ ni ṣiṣe ni a maa ṣe ni ibamu pẹlu ilana Covid-19."

Lẹyin naa lo gba ijọba apapọ niyanju lati ṣe ohun ti yoo rọ awọn ara ilu lọrun ni gbogbo igbesẹ to ba n gbe lati kapa arun naa nitori igbele akọkọ ko rọrun fun awọn eeyan.

Àkọlé fídíò, 'Pásítọ̀ ló sọ fún mi pé Ọlọ́run pè mí láti di Olokun tó ń bọ omi'

Kóníléógbélé ọlọ́sẹ̀ márùn ún gbáko ni ìjọba Nàíjíríà gbé kalẹ̀ fàwọn oṣìṣẹ́ lábẹ́ ìlànà Covid-19 tuntun

aWORAN IGBIMỌ PTF

Oríṣun àwòrán, PTF

Ijọba Naijria ti kede konileogbele ọlọsẹ marun un gbako fawọn oṣiṣẹ ijọba apapọ lọna ati dẹkun itankalẹ Covid-19.

Yatọ si awọn oṣiṣẹ ijọba to wa ni ipele Kejila lọ si oke, ko ni si awọn oṣiṣẹ mii ti yoo wa si ibiṣ lasiko yi.

Bakan naa ni ikede yi sọ pe ki awọn ile ẹkọ gbogbo ti wọn yoo ti gba isinmi lati ọjọ Kejidinlogun oṣu Kejila wa ni titi pa fun ọsẹ marun lati asiko yi lọ.

Labẹ ikede ilana tuntun yi ti alaga igbimọ to n mojuto kikoju arun Covid-19 ni Naijiria Boss Mustapha sọ, gbogbo ile ounjẹ, ile igbafẹ ni wọn ni ko wa ni titi pa.

O ni igbimọ PTF ti ṣe agbeyẹwo gbogbo nkan to n lọ lagbaye ti awọn si ti fi aba to yẹ sọwọ si aarẹ fun ibuwọlu ni kiakia

Awọn nkan miran ti ilana tuntun yi mu iyipada ba ni:

  • Didin iye eeyan ti yoo wa nibi ayyẹ eyikeyi tabi apejọ si pe kop ma ju eeyan aadọta lọ
  • Awọn ile ounjẹ gbogbo ni yoo wa ni titi pa ayafi awọn to baa n ta ounj fun ile itura tabi ti awọn eeyan yoo ra ounjẹ lati lọ jẹ nile
  • Awọn ero ti yoo kopa ninu ijọsin ile isin ko ni ju idameji iye eeyan to y ki o wa nibẹ lọ
  • Awọn ọlọkọ ero ko gbọdọ ko ju ida meji dedee iye eeyan to yẹ ki wọn ko lọ
  • Ki awọn eeyan yago fun gbogbo irinajo eyi ti ko ba ti pọn dandan lasiko yi