Christmas Message: Wo bí o ṣe lè dáàbò bo ara rẹ lásòkò ọdún Keresimesi

Afiwe itakete sira ẹni nibi inawo
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Lẹyin ti ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri si eto abo abẹle, DSS, kede pe awọn kọlọrọsi kan n mura ati ṣakọlu sawọn agbegbe kan bi ọdun ṣe n pari lọ, ọpọ awọn awọn eeyan lo ti n woye ohun to yẹ ki wọn ṣe.

Yoruba bọ wọn ni oju ni alakan fi n ṣọri, eyii lo mu BBC Yoruba kan si akọṣẹmọṣẹ kan nipa eto abo, lori awọn ohun to yẹ ki eeyan ṣe fun abo ara wọn bi ọdun ṣe n pari lọ yii.

Babatunde Akande, to jẹ alaṣẹ ileeṣẹ eto abo aladani Europa Security Guard, sọ awọn ohun to yẹ ki awọn ara ilu ṣe atawọn nnkan ti ko yẹ ki wọn ṣe fun abo ara wọn.

Akande kọkọ gba awọn eeyan niyanju lati maa tọju awọn ọlọde to n ṣọ ile wọn.

People wearing Christmas hats and opening presents online

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, WHO ta bayar da shawarar mutane su gana da juna ta intanet

O ni "Ẹma fi ebi pa ọlọdẹ to n ṣọ ile yin lọdun yii o, ẹ ma sọ pe ṣebi o n gba owo oṣu."

Bakan lo kilọ pe ki awọn eeyan maṣe rinrin ajo ti ko ba ṣe pataki.

O ṣalaye pe "kii ṣe gbogbo irinajo ni eeyan n lọ lasiko yii."

"Ẹ le fi owo ranṣẹ si ẹni to ba yẹ ki ẹ ṣabẹwo si ti abẹwo naa ko ba pọn dandan."

Àkọlé fídíò, 'Ọ̀lọ́pàá shátà mi láti Mowe dé Magboro dé Shagamu, wọ́n ní ṣé mi ò mọ̀ pé ìjọ́ba ni mo ṣiṣẹ́ fún'
Itakete siraeni

Bẹẹ lo ni ki awọn eeyan ṣora nipa ohun ti wọn a maa sọ ni gbangba.

"Ẹni to wa nile ọti to n dan ẹnu nipa iye owo to wa ninu apo banki rẹ kan n fi ara rẹ sinu ewu ni, nitori ko mọ irufẹ eeyan to wa layika rẹ nigab to n sọrọ."

Amoye nipa eto abo naa tun ṣalaye pe ki awọn eeyan maa gbiyanju lati maa pa iye owo to wa ninu apo ifowopamọ banki wọn rẹ lori ẹrọ alagbeka wọn.

Àkọlé fídíò, 'Pásítọ̀ ló sọ fún mi pé Ọlọ́run pè mí láti di Olokun tó ń bọ omi'

O ni ki awọn eeyan ṣora nipa iye owo ti wọn yoo maa da nibi ipade adugbo, bi wọn ṣe nawo nibi ariya ati awọn aṣọ to maa n ṣafihan bi wọn ṣe lowo si.

Ni ti ori ayelujara, Akande sọ pe "ẹ ṣọra fun irufẹ ohun ti ẹ o maa fi lede loju opo Facebook."

"Ẹlomiran yoo maa fi gbogbo igbesi aye rẹ sori Facebook."

"Fun apẹrẹ, awọn kan maa n fi ibi ti wọn wa ati ibi ti wọn n lọ sori Facebook, eyii ko daa to."

Wo àwọn ọ̀nà mẹ́fà tí o lè gbà dáàbò bo ara rẹ bí ọdun ṣe ń lọ sópin

Security

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG

Ni bayii ti ọdun keresimesi ati ayẹyẹ opin ọdun ku ọjọ perete, ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti kede awọn ohun mẹfa to yẹ ki awọn ara ilu ṣe lati dabo bo ara wọn lopin ọdun.

Ọjọ Iṣẹgun ni ọọfisi ileeṣẹ ọlọpaa to n ri si ọrọ iroyin fi atẹjade naa lede niluu Abuja.

Ninu atẹjade ọhun ni wọn ti ṣalaye awọn ohun ti awọn eeyan le ṣe fun abo ara wọn, paapaa awọn to n rinrinajo ile ọdun, ni ibudokọ, papakọ ofurufu ati ibudokọ oju irin.

Wo awọn nnkan ti ọlọpaa ni ki o ṣe lasiko ti ọdun n lọ sopin yii fun abo ara rẹ:

  • Jẹ ki baagi rẹ da yatọ
  • Gba apo ilewọ rẹ mu daadaa
  • Maṣe jẹ ki awọn to wa layika rẹ gbọ ohun ti o ba n sọ lori ẹrọ ibanisọrọ
  • Maṣe gba ounjẹ tabi ohun mimu lọwọ ẹni ti o ko ba mọ ri
  • Maṣe ba ajeji sọrọ nipa awọn ohun to ṣe koko tabi aṣiri nipa ara rẹ
Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa fi ọrọ naa lede tan ni wọn tun fi fido yii lede pẹlu.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2