France police shootings:: Agbébọn yìnbọn pa ọlọ́pàá mẹ́ta ní Saint-Just

Iroyin sọ pe agbebọn kan ti ta ọlọpaa mẹta nibọn ti wọn si gba ibẹ ku nitori pe wọn ki wọn wa yanju iṣoro abẹle kan to ṣẹlẹ.
Arabinrin kan lo lọ sapamọ sori aja ile ni abule kan to n jẹ Saint- Just l'Ọjọru ọsẹ yii.
Ni ẹkun arin gbungbun orileẹde Faranse ni iṣẹlẹ naa ti ṣẹ ti wọn si sare pe awọn ọlọpaa.

Ṣaadede ni agbebọn kan yinbọn to pa ọlọpaa kan ti ekeji si farapa. Lo ba tundana sun ile naa to si tun ọta ibọn rẹ ki to yin in pa ọlọpaa meji mii to ṣẹṣẹ wọle. Amọ wọn ri obinrin naa doola.
Nibayii, awọn ọlọpaa ṣi n wa ọna lati mọ ibi ti afurasi ẹni ọdun mejidinlaadọta ọhun wọlẹ si tori wọn ni awọn alaṣẹ mọ bi ni mọ owo lori pe awọn ọmọde kan wa ni ikawọ rẹ.
Olootu ilu Saint-Just, François Chautard sọ pe ile naa ti jona raurau bayii ti awọn ọlọpaa si n gbiyanju lati mọ boya afunrasi ọhun jona mọ ile tabi na papa bora.
Amọ eeyan kan to ta ọlọpaa lolobo sọ fun ile iṣẹ iroyin BFMTV pe awọn gbagbọ pe o ti sa lọ.
Awọn ọlọpaa atawọn oṣiṣẹ panapana ṣi wa nibi iṣẹlẹ ọhun ni ilu to ti ṣẹlẹ.
Minisita ọrọ abẹle Gerald Darmanin ti fi orukọ ọlọpaa akọkọ to ku sita gẹgẹ bii Brig Arnol Mavel, ni ọdun mọnkanlelogun atawọn meji to ku lẹyin rẹ, Lt. Cyrille Morel, ẹni ọdun marundinlaadọta ati Adjutant Rémi Dupuis, to jẹ ẹni ọdun mẹtadinlogoji.
Ọgbẹni Darmanin banujẹ gidi lori iku awọn ọlọpaa naa to si fi ọrọ ibanikẹdun ranṣẹ si ẹbi, ọrẹ atawọn alabaṣiṣẹpọ wọn.
O ni "iku wọn tun n ṣafihan ewu ti awọn ọlọpaa n da aya kọ lojoojumọ lẹnu iṣẹ wọn.
Ẹwẹ, ọlọpaa eyi to farapa fi ẹsẹ gba ọta ibọn ni amọ ẹmi rẹ ko si ninu ewu.


















