Water Theraphy: Àwọn àmi méje tó ń tọ́ka sí pé oò kí ń mu omi bí ó ti tó

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Yemisi Oyedepo
- Role, Broadcast Journalist
Omi labuwẹ, omi labumu, omi naa ni wọn lo so aye ro, koda ọrọ Yoruba a maa sọ pe ẹnikan kii ba omi se ọta.
Awọn onimọ isẹgun a maa kilọ pataki ki eniyan maa mu omi, ati pe bi eniyan ko ba mu omi to, o le koba awọn eroja kan ninu ara.
Iye omi ti o yẹ ki eniyan maa mu loojọ niṣe pẹlu ilera ara.
- Ṣé o mọ iye òṣèré fíìmù Yorùba àti olórin tó bá ọdún 2020 lọ?
- 'Mo máa tó dìde lórí àìsàn', Muyiwa Ademola sọ̀rọ̀ látorí àkéte àìsàn rẹ̀
- Kóo tó gbàlejò láti UK, South Africa, wo àwọn kọ̀ndísọ̀n tí ikọ̀ PTF fi lélẹ̀
- Àwọn Tíṣà Oyo kó owó tó wà fún àkóso iléèwé jẹ, ni wọ́n fi ń fọwọ́ kọ ìdánwò pẹ̀lú ṣọ́ọ̀kì - Seyi Makinde
- Wo àwòrán bí ọdún Keresimesi ṣe ń lọ káàkiri àgbàyé
- Ṣé òótọ́ ni àwọn ará Amẹ́ríkà máa ń hán an lọ́wọ́ kan tí wọ́n bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀?
Gẹgẹ bi ẹgbẹ awọn onimọ sayẹnsi ilẹ Amerika ṣe sọ (U. S National Academies of sciences, Engineering and Medicine) o yẹ ki obinrin maa mu omi lita meji ati kọbu meje, nigba ti ọkunrin gbudọ maa mu omi lita mẹta ati kọbu meje.

Oríṣun àwòrán, VCG
Ṣugbọn ọpọ ni kii mu omi deede yala nitori pe ko si aaye tabi ni ọpọ igba ko si aaye igbọnsẹ iṣẹju-iṣẹju layika wọn, ẹwẹ ẹlomiran ko tilẹ mọ pe omi ti oun n mu ko kun oju osuwọn to.
Kini awọn apẹrẹ to n safihan pe eniyan ko mu omi to.
1. Ẹnu eniyan yoo maa run: omi dara pupọ lati pese itọ, bakan naa ni o maa n ṣan awọn kokoro aigojuri inu ẹnu si isalẹ, eyi si maa n jẹ ki eniyan ni eyin ati erigi to ji pepe.

Oríṣun àwòrán, NurPhoto
2. Irẹwẹsi ninu agọ ara: ti eniyan ko ba mu omi to, eyi maa n jẹ ki omi dinku ni agọ ara nitori naa ara yoo maa rẹwẹsi, nitori pe iṣẹ pupọ ni fun ọkan gẹgẹ bi a ṣe mọ pe oun lo pọn ẹjẹ si ara, omi maa n pese afẹ ninu ara pẹlu, nitori naa ti iṣẹ ba ti poju fun ọkan irẹwẹsi yoo baa.
Nitori naa ti ara rẹ ba n fa tikọ nigbogbo igba kọda lẹyin ti o sun daada doju ami, o se pataki ki moju to dede omi ti o n mu.
3. Eniyan yoo maa ṣe aisan nigba gbogbo: Omi maa n ran ara lọwọ lati fọ idoyi ati awọn majele to wa ninu ara kuro, o si maa n fun eroja to maa n gbogun ti aarun lara lagbara.
Ti omi ko ba to lagọ ara, o ṣeeṣe ki eniyan maa dubulẹ aisan ni gbogbo igba nitori ko si nkan ti yoo ba awọn kokoro to n fa aisan ja.
4. Ounjẹ ko ni da ninu: Omi maa n jẹ ki ounjẹ da ni kiakia, bakan naa ni o maa n jẹ ki eniyan maa lọ ile igbọnsẹ loorekoore.
Ti eniyan ko ba mumi bi o ti yẹ, omi to wa ni ara igbẹ eniyan ni agọ ara yoo mulo, eyi yoo si mu ki igbẹ iru ẹni bẹẹ le koko. Maa mu omi dede lati jẹ ki igbẹ rẹ rọ, ki ounjẹ si da lasiko ti o yẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
5. Ara rẹ ko ni jọlọ daada: Omi maa n jẹ ki ara tutu to si maa mu ki awọn sẹẹli awọ ji pepe, ki si dabi ti ọmọ tuntun.
Sugbọn ti omi mimu ko ba to o ma njẹ ki awọ ara ṣe rakọrakọ ti o si yi bi ara agiliti. Iṣẹ to saba maa n se ni lati fọ idọti to le fa idiwọ kuro ninu ara, ti o ba n lo ipara olowo nla lati mu ki awọ rẹ jọlọ to si dabi ẹni pe ko ṣiṣẹ, gbiyanju omi Mimu deede.
6. Oo nifẹ lati maa mu tabi jẹ nkan didun ni gbogbo igba: Ti omi o ba to ni ara, ara ko ni le lo okun to nilo lasiko too nilo rẹ nitori naa yoo maa wa ohun amuṣagbara kiakia eyi ti o le ri ninu ṣuga ati awọn nkan didun miran.

Oríṣun àwòrán, Per-Anders Pettersson
7. Itọ rẹ yoo dinku: Ti ara ba gbẹ fun omi to nilo, ọkan yoo gba gbogbo omi to ri ni ayika lati le mu iṣẹ pipọ ẹjẹ tẹsiwaju, nitori naa ko ni si omi pupọ to ṣẹku ni ara fun itọ bi o ti yẹ.
Ti eniyan ko ba mu omi to, itọ eniyan le ni awọ ti ko ba oju mu to, ki o maa pọn tabi ki o ni oorun to lagbara ju bi o ṣe yẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bakan naa eniyan le ni aarun to niṣe pẹlu oju ara (UTI). O o mọ pe oun mu omi bi o ti yẹ ti o ba n lọ ile igbọnsẹ looree koore ti itọ rẹ si mọ, ti ko pọn ti ko si tun ni oorun.
Nitori naa to ba jẹ pe iwọ kii mu omi bi o ti tọ, bi ọdun ṣe n lọ si opin yii jẹ ki o jẹ ipinu ọdun tuntun rẹ lati maa mu omi bi o ti tọ ati bi o ti yẹ.

















