Third Mailand Bridge: Ìjọba àpapọ̀ yóò ṣí afárá Third Mainland Bridge lẹ́yìn tó tìí pa lóru ọjọ́ Kérésìmesì

Oríṣun àwòrán, The guardian nigeria
Ijọba apapọ sọ pe afara Third Mainlainland Bridge ti wọn gbe ti pa lati oru ọjs Kersimesi mọjumọ ọjọkeji ọdun yoo di ṣiṣi silẹ pada lati oru ọjọ Aiku, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kejila ọdun 2020.
Ijọba ti ṣaaju kede pe wakati mejilelaadọrin, iyẹn ọjọ mẹta ni wọn yoo fi ti afara naa pa lati lee fun awọn kọngila to n ṣiṣẹ atunṣe lori rẹ lanfani ati ṣe awọn atunṣe ti wọn nilo lati ṣe laisi idiwọ tabi idena lilọ bibọ ọkọ.
Amọṣa, alakoso opopona ijọba apapọ lẹkun Eko, Olukayọde Popoọla ṣalaye pe wọn ni lati ṣii ṣaaju ọjọ ti wọn kede tẹlẹ fun ṣiṣi rẹ nitori bi awọn kọngila ti ṣe tete pari iṣẹ naa ni.
Idi ti wọn fi kede titi pa rẹ ni ki wọn lee dẹkun gbogbo mimi ati gbigbi-gbagba ti awọn ọkọ to ba n lọ lee maa fa lasiko ti wọn fi n ṣe awọn iṣẹ kan nibẹ.
Lati oṣu keje ọdun 2020 ni wọn ti bẹrẹ iṣẹ atunṣe lori afara Third Mainland Bridge ti wọn si kọkọ ni yoo gba oṣu mẹfa ki wọn to pari rẹ ki wọn to sun un siwaju pẹlu oṣu kan leyi to tums si pe oṣu keji ọdun 2021 ni iṣẹ atunṣe lori rẹ yoo pari, dipo oṣu kini ọdun 2021.








