Tunde Ednut: Ìdí mẹ́fà rèé tí Instagram, Facebook le fi wọ́gilé ojú òpó ìkànsíraẹni rẹ

Tunde Ednut: Idi mẹfa re ti Instagram, Facebook le fi gbegile oju opo ikansiraẹni rẹ

Oríṣun àwòrán, Tunde ednut

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọpọlọpọ igba ni awọn alaṣẹ oju opo ikansiraẹni lori ayelujara ma n gbegile awọn oju opo awọn eniyan laimọ nkan ti wọn ṣe lai dara, ki wọn to

gbegile oju opo wọn.

Nigba miran, awọn eniyan kii ka awọn ofin to rọmọ lilo awọn oju opo wọnyii ni igba de igba, lati mọ ohun ti wọn le ṣe, to le mu ki wọn gbegile oju opo ikansiraẹni wọn.

Bẹẹ ni ọrọ ri nigba ti oju opo ikansiraẹni Instagram ati Twitter bẹrẹ si ni gbona jainjain, lẹyin ti awọn alaṣẹ ikanni Instagram gbegile oju opo Tunde Ednut nigba ti o ni awọn alatilẹyin bii miliọnu kan laarin ọjọ meji.

Àkọlé fídíò, Itaniji: Oluwo sọ ìtàn bí Orunmila ṣe jìyà nílùú Iwo àti ayọ̀ tó gbẹ̀yìn rẹ̀ torí sùúrù

Bakan naa ni awọn alaṣẹ Facebook ati Twitter gbegile oju opo aarẹ orilẹede Amerika, Donald Trump lẹyin ti ikanni naa ni o tapa si awọn aṣẹ to de lilo oju opo naa.

Ni ti Tunde Ednut ni tirẹ igba keji ree ti awọn alaṣẹ Instagram yoo pa oju opo rẹ de.

Tunde Ednut: Idi mẹfa re ti Instagram, Facebook le fi gbegile oju opo ikansiraẹni rẹ

Oríṣun àwòrán, Instagram

Tunde Ednut: Idi mẹfa re ti Instagram, Facebook le fi gbegile oju opo ikansiraẹni rẹ

Oríṣun àwòrán, Twitter

Eyi ni akojọpọ ohun mẹfa to le fa ki wọn wọgile oju opo Instagram, Twitter ati Facebook;

Ninu osu keje ọdún 2019 ni ile iṣẹnaa gbe awọn fin yii jade pe ẹnikẹni to ba lugbadi rẹ yoo geka abamọ jẹ.

•Ki ẹgbẹgbẹrun eniyan bẹrẹ si ni tẹle ẹ loju opo ikansiraẹni rẹ lai gba aṣẹ to de, nitori o ni iye eniyan to le tẹlẹ tabi fẹran ohun to ba gbe jade laarin wakati kan. Wẹrẹ ti eniyan ba ti kọja ala iye eniyan to le ni wọn yoo gbegile oju ọpọ rẹ.

•Ti eniyan ba n gbe iroyin jade ju bo ṣe yẹ lọ lori ikanni rẹ, o ṣeese ki wọn gbegile, nitori o ti ni iye nkan ti eniyan le gbe jade laarin wakati ti ko tako alakalẹ ikanni naa lọ, amọ ti eniyan ba n gbe iroyin jade lemọlemọ kọja alakalẹ, wọn a gbẹsẹle oju opo naa.

•Ẹnikẹni to ba lo aworan, fidio tabi akọsilẹ ẹlomiran lai gba aṣẹ lọwọ ẹni ti o nii le fa ki wọn gbegile oju opo rẹ, ti oni nkan ba fi ẹjọ rẹ sun wi pe o lo ọgbọn ati aroko oun lai gba aṣẹ.

•Instagram, Facebook ati Twitter le e gbegile awọn aworan tabi fidio to ba lodi si aṣẹ to rọ mọ awọn fidio to tọna. Eewọ ni wiwo fidio to ba ṣe afihan ibalopọ tabi ihoho ni awọn oju opo naa.

•Ti awọn eniyan ba n tọkasi oju opo rẹ pe o lewu, wọn le e gbegile fun igba diẹ, ki wọn fi ṣe iwadii boya lootọ ni awọn nkan ti eniyan n gbe jade loju opo ikansiraẹni rẹ lewu fun awujọ.

•Bakan naa ni awọn oju opo ikansiraẹni le gbegile oju opo rẹ ti o ba n lo orisirisi ẹrọ bii foonu, computa lati fi wo oju opo rẹ, ti 'IP address' ti oluwarẹ ba fi n wọle ba ti pọju bo se yẹ lọ, wọn le e gbegile oju opo naa.

Kini idi ti wọn fi ti oju opo Tunde Ednut pa?

Ọpọlọpọ ẹsun lo n lọ lori ayelujara paapaa julọ lọju opo Instagram pe wọn yọ kuro nitori pe awọn nkan to n gbe soju opo naa ko ba ofin Instagram mu.

Botilẹ jẹ pe ko si igba kankan ti Instagram fi atẹjade sọwọ pe nkan bayii ni Tunde Ednut ṣe sibẹ, ìgbà meji ọtọọtọ ni wọn ti gbọn yọ loju opo naa.

Tunde Ednut: Idi mẹfa re ti Instagram, Facebook le fi gbegile oju opo ikansiraẹni rẹ

Oríṣun àwòrán, Tunde ednut

Diẹ lara nkan ti awọn eniyan n sọ loju opo twitter nitori oju opo Instagram ti wọn ti pa ree

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Skip X post, 2

End of X post, 2

Skip X post, 3

End of X post, 3