ASUU: NASU gùnlé ìwọ́de torí ẹ̀ṣùn pé owó tí ìjọba àpapọ̀ pín fún ASUU pọ̀jù

SANU

Oríṣun àwòrán, @TheNationNews

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ fasiti Naijiria ti kii ṣe olukọ, NASU, ti tako ijọba apapọ lori bo ṣe pin ogoji biliọnu naira to gbe fun awọn fasiti.

Bo tilẹ jẹ pe Aarẹ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ fasiti to jẹ olukọ, ASUU, Ọjọgbọn Biodun Ogunyemi, ti sọ fun awọn akọroyin pe bi ijọba apapọ ṣe fẹ pin owo naa dara.

Ṣugbọn NASU ti fesi pe ijọba kan n wa ọna lati da arin ẹgbẹ mejeeji ru ni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

NASU fi aidunu wọn han nigba ti wọn bẹrẹ ifẹhonuhan lori pinpin ogoji biliọnu naira naa, ati ọna ti ijọba apapọ n gba san owo oṣu wọn pẹlu ilana IPPIS.

SANU

Oríṣun àwòrán, @vanguardngrnews

Ṣaaju ni ijọba apapọ ti kọkọ tọwọ bọ'we adehun pẹlu ASUU lọjọ kejilelogun, oṣu Kejila, ọdun 2020, to si ṣeleri ogoji biliọnu naira fun wọn gẹgẹ ajẹmọnu owo wọn.

Bakan naa ni owo yii jẹ ara owo to jẹ wọn sẹyin, eyi to mu ki wọn fopin si iyanṣẹlodi wọn oloṣu mẹsan an.

Ṣugbọn NASU faake kọri pe bi ijọba apapọ ṣe pin owo ọhun ko tẹ awọn lọrun.

Wọn ni ko bojumu to ki ijọba fun ẹgbẹ ASUU ni ọgbọn biliọnu naira ninu ogoji biliọnu naira, ko si sọ pe ki awọn ẹgbẹ to ku pin iwọnba owo perete to ṣeku.

Àkọlé fídíò, Itaniji: Oluwo sọ ìtàn bí Orunmila ṣe jìyà nílùú Iwo àti ayọ̀ tó gbẹ̀yìn rẹ̀ torí sùúrù

NASU sọ pe obitibiti owo ti ijọba apapọ pin fun ASUU yoo fa iwa ajẹbanu laarin ẹgbẹ naa.

Akọwe agba ẹgbẹ ọhun, ọgbeni Adeyemi Peters sọ fun awọn akọroyin pe ikuna ijọba apapọ lati pin owo naa gẹgẹ aba awọn onimọ nipa eto iṣuna lo fa iwọde ti wọn n ṣe ati rogbodiyan to n waye laarin ẹgbẹ memeji.

Peters sọ pe yatọ si pe ijọba fun ASUU ni ida marundinlaadọrun owo naa, bi igab to ba n kin iwa jẹgudujẹra lẹyin ni igbesẹ naa ri.

O ṣalaye pe "lati ọdun 2013 ni ijọba ti maa n gbe owo kalẹ fun awọn fasiti, ṣugbọn ASUU lo maa n gba eyii to pọ ju ninu rẹ."

Àkọlé fídíò, Nigeria Car Innovator: Olatunde Ibitoye ní ọdún mẹ́ta ní òun fi ṣe ọkọ̀ náà torí ọ̀dá owó

Akọwe naa sọ pe ẹgbẹ NASU ko ni inunibini kankan si ASUU, ṣugbọn bi ijọba ṣe pin owo naa ko tẹ awọn lọrun.

NASU wa sọ pe wọn ti gbiyanju lati yanju ọrọ naa pẹlu ijọba apapọ, ṣugbọn gbogbo igbiyanju wọn ko so eso rere, eyii lo idi iwọde ti wọn n ṣe.