Orisabunmi: Elebuibon ní àfọwọ́fà wà lára nǹkan tó n fa Àkúfà nílẹ̀ Yorùbá

Laipẹ yii ni gbajugbaja oṣerebinrin, Folake Aremu, ti ọpọ eeyan mọ si 'Oriṣabunmi' kú, ṣugbọn ti ẹgbọn ati aburo rẹ naa tun kú laarin ọjọ mẹta pere.
Eyi si ti mu ki ọpọ eeyan o ma a beere, paapaa awọn ọmọ ilẹ Yoruba pe, ṣe o ṣe e ṣe ko jẹ Akufa ni ọrọ iku wọn to waye ni tẹle n tẹle yii?
Ọ́na lati wa idahun si iwoye awọn eeyan naa lo mu wa pe baba awo, Ifayemi Elebuibon lati mọ ohun to n jẹ akufa, idi to fi le waye ati ọna abayọ si isoro naa.
Bakan naa, awọn eeyan miran lero pe arun idile le sokunfa iku tẹle n tẹle, idi si ree ta tun fi tọ dokita oloyinbo lọ lati mọ boya ootọ ni, ka le se ọtun ati osi lai ba ibikan kan jẹ.
Kini Yoruba n pe ni Akufa?
Gẹgẹ bi akọsilẹ to wa ni ori ayelujara ifayemisielebuibon.blogspot.com, Akufa ni ki iku aitọjọ o waye lera-lera lẹyin iku eeyan kan ninu ẹbi kan, agboole tabi ilu.
Ọmọbinrin Araba ilu Oṣogbo, Oloye Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn, ni Ifayẹmisi Ẹlẹbuibọn to ni oju opo ayelujara naa.
O ni igbagbọ Yoruba ni pe, ẹni to kọkọ ku naa ko da kú, ṣugbọn o fa awọn eeyan mii dani lati sin in lọ si ọrun.
Ki lo maa n fa Akufa?
Oloye Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ninu ifọrọwanilẹnu kan woye pe, o ṣe e ṣe ko jẹ akufa ni iṣẹlẹ iku tẹle n tẹle to waye ninu ẹbi gbajugbaja oṣere-binrin naa.
O ṣalaye pe akufa ti wa tipẹ, to ba si jẹ pe ni aye atijọ ni, aṣiri iṣẹlẹ naa yoo ti tu sita, ko to o ṣẹlẹ.
- Wo ọ̀nà tí Yoruba ń gbà dá ọmọ àlè mọ̀ nínú ìdílé- Elebuibon
- Àlàyé rèé lórí bo ṣe le è dá Emèrè mọ̀ tàbí dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ wọn
- Afeez Ọwọ: Èmi kọ́ ni mo kọ́kọ́ làwòrán Orisabunmi, ẹ ti ṣe wá rangun mọ́ mi?
- "Ikọ́ lásán ló pa Orisabunmi"
- Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọba tó kọ ifá sílẹ̀ gbé Bíbélì àti Kùránì
- Ọdún méjì, wàhálà méjì lójúbọ Osun Osogbo,
- Njẹ́ o mọ̀ pé bíi ọdún 700 sẹ́yìn ni wọ́n ti ń bọ Osun-Osogbo? Mọ̀ síi nípa ìtàn ojúbọ̀ nàá
O ni nigba mii, ẹni to kọkọ ku le jẹ pe oun ni okun to so ẹbi ro, ti iran yoo si jade si ẹbi naa pe ki wọn o sẹ etutu ki okun ẹbi naa ma ja. Nitori pe iku ọwọọwọ lo ma n tẹle iku iru eeyan bẹ ẹ.
Ti wọn ba ṣe etutu, iku naa yoo re danu, amọ ti wọn ko ba ṣe e, ewu ni.
Ẹlẹbuibọn sọ pe oriṣiriṣi nkan lo ma n fa akufa ninu ẹbi kan. O ni o ṣe e ṣe ko jẹ pe awọn ẹlẹyẹ lo ti leri lati ma a pa wọn.
Itakun agbaye ifayemisielebuibon.blogspot.com tun ṣalaye pe, Akufa le waye ti ẹlẹda oku to ku ko ba ni isinmi tabi to ba n binu si awọn alaaye.
Yatọ si eyi, Akufa tun le waye ti ẹbi ko ba ṣe awọn etutu to yẹ ni sise tabi wọn ko ṣe e daadaa, nigba ti ẹni akọkọ ku gẹgẹ aṣa.
Itan bi Ilẹ ṣe di ẹni ti ko le sọrọ mọ nitori Akufa:
Elebuibon wa lo itan bi Ilẹ ṣe di ẹni ti ko le sọrọ mọ, eyi to da lori awọn ọmọ iya mẹta to pa ẹranko agbọnrin, ti wọn si fi nkan di i bi oku wọ aarin ilu, nitori ki wọn o ma ba fun ẹnikẹni jẹ lara ẹran naa.
Nibi ti wọn ti n lọ, ni wọn ba awọn ẹlẹyẹ lọna to n ṣe ipade. Sugbọn, ẹsẹ oku ẹran naa lo yọ silẹ, ti awọn ẹlẹyẹ fi ri pe, kii ṣe oku eeyan ni wọn di.
Eyi lo ki awọn ẹlẹyẹ pinnu le wọn lori, lati pa wọn ni ẹyọ kọọkan, orukọ wọn si ni Kutannle, Oleegba, ati Tẹtẹrẹgun.
Ṣugbọn ṣa, iyawo Ọrunmila, tii se Ilẹ, gbọ lasiko ti awọn ẹlẹyẹ ṣe imulẹ naa.
Gẹgẹ bi itan naa ti sọ, ko pẹ ti wọn jẹ ẹran naa, ti akọbi fi bẹrẹ si ni ṣe aisan, eyi to mu ki iya wọn salọ si ọdọ Ọrunmila fun iwosan ọmọkeji to tun bẹrẹ aisan.
Ṣugbọn ọmọ naa ku, ko to o de ile.
Ko ju ọjọ mẹta ti wọn sin oku akọbi, ni ọmọ keji naa bẹrẹ aisan, ti iya wọn tun sare lọ sọdọ Ọrunmila, ṣugbọn ọmọ naa tun ku.
Ki ọmọ kẹta ma ba ku, lo tun mu ki iya wọn pada si ile Ọrunmila, ṣugbọn iyawo rẹ, Ilẹ lo ba nile.
Nibẹ ni Ilẹ ti sọ fun pe, ọrọ ẹran ti awọn ọmọ rẹ di bi oku eeyan, nitori ki wọn o ma ba a fun ẹnikẹni jẹ lara rẹ, lo n fa akufa.
O sọ fun iya wọn pe, ko pa odidi ẹran kan, ko si ko gbogbo ifun ati ẹjẹ rẹ fi ṣe etutu, ko si gbe e lọ si orita awọn ẹlẹyẹ, ti ko ba fẹ ki ọmọ kẹta naa o ku.
O ni ko gbe ọrun rẹ lọ si idi Eṣu.
Igbesẹ ti ilẹ gbe yii, lo mu ki awọn ẹlẹyẹ gba ohùn lẹnu rẹ ti ko fi le sọrọ mọ.
Elebuibon fikun pe, "Nkan to ma n fa akuba le jẹ nipasẹ nkan ti obi se, tabi awọn ọmọ.
Ti wọn ko ba si ti ri eeyan sọ fun wọn, iku naa yoo tẹsiwaju ni."
Kini ọna abayọ kuro ninu Akufa?
Lori nkan ti awọn eeyan to kù ninu ẹbi naa le ṣe lati dena tabi fi opin si akufa, Baba Ẹlẹbuibọn sọ pe wọn yoo difa, lati mọ nkan ti wọn yoo fi ṣe etutu.
Yatọ si eyi, o ni niwọn igba to jẹ pe ẹsin Kristiẹni ati Islam ti wa bayii, ẹbi ti ọrọ ba kan le gbadura nilana ẹsin wọn.
Njẹ o ni nkan to le fa Akufa nilana iṣegun oyinbo?
Dokita Ikebese Wilson sọ fun BBC Yoruba pe iwadii imọ sayẹnsi nipa ohun to se okunfa iku to pa awọn eeyan ẹbi Orisabunmi (Post mortem) nikan lo le fihan boya orisun kan naa ni iku wọn ti wa.
O ni yatọ si pe o le jẹ aarun Covid-19 to wa nita, o ni iwadii yoo da lori iru aisan tabi awọn ami aisan ti gbogbo wọn fihan ṣaaju iku wọn.
Dokita Ikubese ṣalaye pe, iku awọn eeyan yii tun le jẹ awọn aisan ajogunba bi ẹjẹ riru ati itọ ṣuga, ṣugbọn ayẹwo oku naa lo le sọ nkan to jẹ.





















