Yemi Elebuibon: Babaláwo èké kò le è kii ẹsẹ mẹ́rin nínú odù ifá

EFCC ati Babalawo

Oríṣun àwòrán, Ile-ifa.org

Àkọlé àwòrán, Ní ìlú Ibadan ni Àjọ EFCC ti fi pańpẹ́ ọba mú ayédèrú babaláwo pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ dúkìá tí wọ́n ti lù ní jìbìtì.

Agbaọjẹ nipa eto isegun ati ẹsin ibilẹ ni ilẹ Yoruba, Baba awo Yẹmi Ẹlẹbuibọn, ti se apejuwe awon ayederu babalawo ati awọn ọna ta fi lee da wọn mọ.

Baba Ẹlẹbuibọn la awọn eeyan lọyẹ nitori bi ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria, EFCC, se fi panpẹ ọba mu ayederu babalawo kan ni ilu Ibadan.

Ọpọlọpọ dukia ati ile to ti fi ọna eru gba lọwọ awọn eniyan to lu ni jibiti si ni wọn ka mọ lọwọ, tijọba si ti gbẹsẹle.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹlẹbuibọn, ninu ọrọ rẹ salaye lẹsẹẹsẹ nipa ba se le e mọ gbajuẹ babalawo, ta ba n sọrọ nipa eto isegun ati ẹsin ibilẹ.

Afurasi gbajuẹ babalawo

Oríṣun àwòrán, EFCC

Ọna marun to fi lee mọ eke Babalawo:

  • Awọn babalawo ayederu kii le ki ifa ati awọn odu ijinlẹ to wa ninu rẹ
  • Awọn ayederu babalawo ko farabalẹ kọ ẹkọ bi o ti yẹ nitori ẹkọ isẹ babalawo muna doko ju tawọn onisegun lọ
  • Asọ awọn ayederu babalawo ma n pọn ni , nitori pe wọn yoo jẹ iya ni aye, wọn a tun jẹ ni ọrun
  • Iya ati isẹ lo ma n gbẹyin awọn ayederu babalawo
  • Gbajuẹ babalawo kii sọrọ ko sẹ tabi se iwosan to muna doko.

Ẹlẹbuibọn, to jẹ eekan ni idi isegun ati ẹsin ibilẹ wa parọwa sawọn eniyan lati ma sakiyesi finifini, nipa ẹni ti wọn yoo tọ lọ bi babalawo.