Bauchi Sex Party: Ọlọ́pàá mú afurasí 22 lórí ṣíṣe aríyá ìbálòpọ̀

Afurasi onihooho

Oríṣun àwòrán, jaguda

O dabi ẹni pe bi wọn se n ge awọn ọdọ lapa oke ọya lọwọ nidi sise ariya ibalopọ ati onihooho, se ni wsn tun n bọ oruka.

Idi ni pe lẹyin ọsẹ diẹ ti ijọba ipinlẹ Kano dena sise ariya ibalopọ, ti wọn si wo ile ti wọn ti fẹ se ariya naa, se ni awọn ọdọ nipinlẹ Bauchi seto ariya tiwọn.

Amọ lẹyin ariya naa, abamọ lo gbẹyin ọrọ wọn nitori ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ naa, ti sawari ọdọ mejilelogun to kopa ninu ariya naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lara awọn afurasi ti ọwọ tẹ naa pe wọn kopa ninu ariya onihooho to waye nilu Dass, la ti ri ọdọlangba mẹsan.

Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa ni Bauchi, Wakil Ahmed lo sisọ loju ọrọ yii lasiko to n safihan awọn afurasi naa fawọn akọroyin lọjọru.

Awọn afurasi to se ariya ibalopọ ati onihooho

Oríṣun àwòrán, Bauchi Police Command

Ahmed ni "Ninu igbiyanju wa lati fopin si iwa ọdaran, wiwọ asọ to fi ara silẹ,iwa jagidijagan ati ole jija, ọwọ wa tẹ awọn eeyan to n da omi alaafia ilu ru.

Sara Suka tii se afurasi gbajumọ tọọgi, ajifoonu atawọn iwa ọdaran miran to fi mọ sise ariya ibalopọ ni ọwọ wa tẹ nilu Dass, ti yoo si foju wina ofin."

Ẹ ṣọ́ra o, àwọn kọ̀lọ̀rọ̀sí kan ń múra láti dá ìjà ẹ̀sìn sílẹ̀ ní Naijiria - DSS figbe ta

DSS

Oríṣun àwòrán, @OnwardNG

Ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ti ke gbajare pe awọn kọlọrọsi ẹda kan ti n gbaradi lati da ija ẹsin silẹ kaakiri Naijiria.

DSS lo fi ikede naa sita ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Peter Afunanya fọwọ si.

Afunanya darukọ awọn ipinlẹ mejila to ṣee ṣe ki ija ẹsin naa ti waye, o si rọ awọn ọmọ Naijiria lati yago fun gbogbo ohun to le fa ipaya ati iwa ipa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Atẹjade naa ni "ajọ DSS fẹ fi akoko yii sọ fun awọn eeyan nipa awọn kọlọrọsi kan to n gbiyanju lati da ija ẹsin silẹ kaaiiri Naijiria."

"Lara awọn ipinlẹ to ṣeṣe ki wọn dojukọ ni Sokoto, Kano, Kaduna, Plateau, Rivers, Oyo, Eko atawọn ipinlẹ kan ni Guusu ila oorun Naijiria."

dss

Oríṣun àwòrán, @channelstv

Atẹjade ọhun tẹsiwaju pe lara awọn ọna ti wọn yoo lo lati da ija ẹsin naa silẹ ni ṣiṣe akọlu si awọn ile ijọsin, awọn adari ẹsin ati awọn agbegbe to ṣe pataki.

Afunanya tun rọ awọn eeyan ilu lati ṣọra fun awọn ọgbọn alumọkọrọyi ti awọn kọlọrọsi naa yoo lo lati da rukerudo silẹ.

Àkọlé fídíò, LASU Best Graduating Student: Wákàtí kan péré ni mo fi ń kàwé lójúmọ́, èmi kìí ṣe igi ìwé

O ni ajọ DSS yoo fọwọ sowọpọ pẹlu awọn ileeṣẹ eto abo miran lati dabo bo awọn ara ilu, lẹyin naa lo rọ awọn ẹni ibi to n dana rogbodiyan naa pe ki wọn jawọ ninu erongba wọn lati da ilu ru.

Ikilọ DSS yii lo n waye lasiko ti eto abo mẹhẹ kaakiri Naijiria.