UI: Ọwọ́ àjọ DSS tẹ òṣìṣẹ́ méje tó ṣàyídáyidà ìdánwò

Fasiti Ibadan

Oríṣun àwòrán, @UIbadan

Ọga agba Fasiti Ibadan, Ọjọgbọn Idowu Olayinka ti fa meje lara awọn oṣiṣẹ ile iwe ọhun le ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS lọwọ, lori ẹsun ṣiṣe magomago lati ran awọn akẹkọọ lọwọ lasiko idanwo.

Alukoro Fasiti naa, Tunji Oladejo sọ fun BBC pe, ọwọ tẹ awọn oṣiṣe ọhun lẹyin ti wọn ṣe ayidayida si ẹrọ ayelujara ti wọn fi n ṣe idanwo lọna lati fi ran awọn akẹkọ kan lọwọ.

Wọn a ko iwe esi si idahun to wa ninu idanwo wọn, wọn a si yọlẹ gbe e wọle fun awọn akẹkọọ ninu kilaasi idanwo.

Oladejo ni Fasiti Ibadan ko tii gbe iwadi tirẹ kalẹ lori ọrọ naa, ṣugbọn o gbagbọ pe ajọ DSS yoo ṣe iwaadi okodoro lori ọrọ ọhun.

O tẹsiwaju pe, ajọ DSS yoo tun fi panpẹ ọba mu awọn mẹrin mii ti ọrọ naa kan, yatọ si awọn meje to ti wa ni ahamọ.

Fasiti Ibadan

Awọn oṣiṣẹ naa ti kii ṣe olukọ, jẹ oṣiṣẹ Fasiti Ibadan, ni ẹka miiran bii ẹka to n risi ẹrọ ayelujara ati eto ibaṣepọ ọmọ ile-iwe.

Gẹgẹ bi ọrọ to sọ, o to ọjọ mẹta ti awọn eeyan kan ti n fẹjọ awọn afurasi naa sun ile iwe ọhun ko to di pe ọwọ tẹ wọn.

Oladejo ṣalaye pe ko tii si ọmọ ile iwe kankan ti ọrọ naa kan, sugbọn lẹyin iwaadi ajọ DSS ni Fasiti ọhun yoo gbe igbesẹ to kan.

Àkọlé fídíò, Kengbe Ilorin: Àṣà ẹ̀yà Fulani, Bariba àti Gambari tó dàpọ̀ mọ́ ti Yoruba