Adejare Adeboye: Àwọn kan ní ṣé ọ̀nà láti gba owó oṣù àkọ́kọ́ lọ́wọ́ ọmọ ìjọ kọ́ ní ìkéde ààwẹ̀ ọlọ́jọ́ 63

Oríṣun àwòrán, @PastorEAAdeboye
Awọn eeyan lori ayelujara ti ko ẹnu bo Pasitọ igba fun ijọ Redeemed, RCCG, Olusọagutan Enoch Adeboye lori aawẹ ọlọjọ mẹtalelọgọta to kede .
Pasitọ Adeboye paṣẹ lọjọ Aiku, ọjọ kẹwaa oṣu kini ọdun 2021 pe ki gbogbo awọn ọmọ ijọ naa lagbaye gba awẹ ọjọ mẹtalelọgọta naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kí ló ma n fa Àkúfà nílẹ̀ Yorùbá, àti ọ̀nà àbáyọ?
- Ìgbákejì ààrẹ, tètè yọ Trump nípò, bí bẹ́ẹ̀ kọ́... Ilé aṣòfin Amẹ́ríkà yarí
- Ìwádìí BBC rèé lórí ìjà APC tó fẹ́ gbẹ̀mí Sẹ́nátọ̀ l‘Osun
- Ìlú tuntun tó kún fún ohun àdáyébá láìsí ọkọ̀ tàbí òpópónà ń bọ̀ ní Saudi Arabia
- Mo ti gba ọmọ Igbo tó ń wá bàbá rẹ̀ bí ọmọ, kó má ba à pa ara rẹ̀ - Iba Oluyole
- Lẹ́yìn ọgọ́rùn ún ọjọ́ tí wọn ti Lekki Toll Gate pa, ẹ wo owó gọbọi tíjọba Eko ń pàdánù
- Ẹ́ ràgà bo ìṣọ̀kan Nàíjíríà, ìyàpà le mú ìṣẹ́ àwọn akọni wa já sásán - Osinbajo
- August Agboola Brownie, ọmọ Yorùbá tí wọ́n n wárí fún ní Poland
Gẹgẹbi iransẹ Ọlọrun naa ṣe sọ, ọpẹ ni ọjọ mọkanlelogun akọkọ ti wọn ba aawẹ naa yoo da le lori, ọjọ mọkanlelogun keji yoo da lori adura fun idile and bibeere fun aanu.
Pasitọ Adeboye ni ipele kẹta awẹ naa yoo wa lati gba adura fun ijọ, idile ati ara wọn.

Oríṣun àwòrán, @PastorEAAdeboye
Amọ ọpọ ọmọ Naijiria ko jẹ ki ikede naa balẹ loju opo Twitter, bi wọn ṣe n ka ikede naa, ni wọn n fesi loniruuru le lori.
Fun awọn kan, bi eto oselu orilẹde Naijiria ṣe dagun lo mu ki ijọ maa kede awẹ ọlọjọ gbọọrọ bii eyi ti ijọ RCCG kede naa.

Oríṣun àwòrán, @PastorEAAdeboye
Bi o tilẹ jẹ pe awon kan dahun pe ṣaaju iṣejọba to wa lode bayii ni ijọ naa ti n seto awẹ ati adura ibẹrẹ ọdun.

Oríṣun àwòrán, @PastorEAAdeboye
Ẹwẹ, awọn kan naa n beere pe ṣe kii ṣe ara ọna ati maa gba owo osu akọkọ lọwọ awọn ọmọ ijọ ni wọn se kede aawẹ naa, gẹgẹ bi awọn ijọ kan ti maa nṣe.













