Trump Impeachment: Aṣòfin 232 ló dìbò yọ ààrẹ nígbà tí 197 tako ìgbésẹ̀ náà

Ile asofin tawọn asoju lorilẹede Amẹrika ti dibo yọ aarẹ Donald trump nipo fun igba keji lori ẹsun pe o se koriya fun iwa idaluru lọsẹ to kọja.
Awọn asofin mẹwa latinu ẹgbẹ oselu Republican, tii se ẹgbẹ oselu Trump, lo darapọ mọ ẹgbẹ oselu alatako rẹ, Democrat lati yọ nipo.
Apapọ iye ibo ti wọn fi yọ aarẹ Trump nipo 232-197, eyi to tumọ si pe ibo awọn eeyan to fara mọ pe ki wọn yọ nipo jẹ ojilerugba o din mẹjọ nigba ti ibo awọn ti ko fara mọ igbesẹ yii jẹ mẹtadinnigba.
Niba yii, aarẹ Trump yoo foju wina igbẹjọ lọdọ awọn asofin agba, to ba si jẹbi, a jẹ pe wọn yoo fofin de e lati kopa ninu oselu titi aye.
Amọ ko si ewu fun lati kuro nile ijọba titi ti saa rẹ yoo fi buse ni ọsẹ kan si asiko yii nitori o see se kawọn asofin agba ma tete joko pada lati wa gbọ igbẹjọ rẹ.
Wo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Trump tó mú kí alátakò ilé darapọ̀ mọ́ tìta láti yọ nípò

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe awọn aṣofin kan latinu ẹgbẹ oṣelu Republican, ti Donald Trump ti wa, ti n darapọ mọ ti ẹgbẹ oselu alatako Democrat, lori igbesẹ lati yọ aarẹ orilẹ-ede Amẹrika naa nipo.
Eekan ọmọ ẹgbẹ oṣelu Republican nile aṣoju-ṣofin ilẹ Amerika, Liz Cheney sọ pe, oun ṣetan lati dibo yọ Trump nipo lori iṣẹlẹ ikọlu to waye nile aṣofin to wa ni Capitol lọsẹ to lọ.
Ẹwẹ, Aarẹ Trump ko gba pe oun lọwọ si ikọlu ọhún lọna kọna.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹlẹ́tàn ni ọkùnrin, tó bá rí nkan tó n wa lára obìnrin, yóò yí ìwà padà - Bimpe Oyebade
- A kò le gbà kí ASUU gba ₦30bn nínú ₦40bn tíjọba gbé kalẹ̀ - NASU yarí
- Ẹ̀yin adarí Nàíjíríà, ẹ dẹ́kun àwáwí asán lórí ètò ààbò tó mẹ́hẹ - Ààrẹ àṣòfin àgbà
- Ẹ dákẹ́ àhesọ ọ̀rọ̀, ohun tó pa ẹ̀gbọ́n àti àbúrò Orisabunmi rèé - Mọ̀lẹ́bí gbarata
- Wo àdánù tó wà nínú gbígba ayédèrú áápù fún ìforúkọsílẹ̀ NIN lórí ayélujára
- Àmúlò ẹ̀rọ POS fun òwò ṣíṣe, ṣé ó tọ̀nà nínú Islam àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?
- Ìjọba ń ṣapá rẹ̀ lórí ìdènà Covid-19 àmọ́ àwọn awakọ̀ Eko ya aláìgbọràn - Ìjọba
- "Ẹ̀yin tẹ̀ ń parọ́ ẹlẹ́yà-mẹ̀yà mọ́ Amotekun Oyo, Seyi Makinde lẹ̀ ń dojú ìjà kọ"
- Kí ló ma n fa Àkúfà nílẹ̀ Yorùbá, àti ọ̀nà àbáyọ?
Lonii Ọjọru nile yoo dibo lati fẹsun kan Trump pe o ṣokunfa ikọlu to waye nile aṣofin.

Kinni ẹgbẹ oṣelu Republican sọ?
Arabinrin Cheney to jẹ ọmọ igbakeji aarẹ Amẹrika tẹlẹ rí, Dick Cheney fi aake kọri, o ni oun yoo gbaruku ti Democrat lori àti yọ Trump nipo.
Eyi ni igba akọkọ ti eekan ninu ẹgbẹ oṣelu Republican yoo gbaruku ti ẹgbẹ alatako lati yọ aarẹ to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu rẹ nipo, lati aye Aarẹ Richard Nixon.
Arabinrin Cheney sọ pe "Aarẹ Trump ti da ilẹ Amerika, o si tun ti tapa si iwe ofin orileede naa pẹlu ihuwasi rẹ lọfiisi "
O ni Trump lo ko awọn ero to ṣe ikọlu sí ile aṣofin ni Capitol jọ.
Awọn aṣofin Republican meji miiran, John Katko ati Adam Kinzinger sọ pe awọn ṣetan lati dibo yọ Trump nipo.
Iroyin kan tiẹ sọ pe, olori ẹgbẹ Republican nile, Kevin McCarth to jẹ ọkan lára ọwọ ọtun Trump ti ni oun ko ni sọ fawọn ọmọ ẹgbẹ Republican to ba fẹ dibo yọ Trump nipo, pe kí wọn maa ṣe bẹẹ.

Iwe iroyin New York Times tun fi iroyin kan lede pe, olori aṣofin Republican nile igbimọ aṣofin agba, Sẹnẹtọ Mitch Mcconnell ti sọ fawọn to sún mọ ọ pe, inu oun dun pe ẹgbẹ oṣelu Democrat fẹ yọ Trump nipo.
O ni igbesẹ naa yoo ran ẹgbẹ Republican lọwọ lati yọ Trump kuro ninu ẹgbẹ naa.
Ọgbẹni Mcconnell gbagbọ pe Trump ti ṣe nnkan to le mu ki awọn aṣofin yọ ọ nipo.
Nibayii, ile aṣoju-ṣofin ti dibo pe ki igbakeji aarẹ, Mike Pence yọTrump nipo, bi ko ba si se bẹẹ, awọn asofin funra wọn ti setan lati yọ nipo.
Awọn asofin okoolerugba ati mẹta, 223 lo dibo pe ki wọn yọ Trump laarọ ọjọru nigba ti asofin marunlerugba 205, ko fara mọ̀ igbesẹ naa.
Amọ awọn sẹnẹtọ naa gbọdọ buwọlu igbesẹ naa, ki Trump to le lọ.Àwọn aṣòfin Republican ti ń darapọ̀ mọ́ Democrat lórí àti yọ Trump nípò

Kinni Trump sọ?
Aarẹ Trump ni oun ko fẹ iwa ipa ati jagidijagan.
"Eto lati yọ mi nipo ti wọn n ṣe yii n fa ibinu, nnkan to buru jai ni wọn n ṣe," Trump lo sọ bẹẹ.
Trump ni ohun to jẹ iṣoro gan an ni ọrọ ti ẹgbẹ oṣelu Democrat sọ lasiko ifẹhonuhan "Black Lives Matter" lọdun 2020.
Ọrọ ti Trump sọ fawọn ololufẹ rẹ níwájú ilé aṣofin, k'awọn ero naa to kọlu ile aṣoju-ṣofin lo mu ki wọn fẹ yọ ọ nipo.
Trump sọ fawọn ololufẹ rẹ pe eru wa ninu ibo aarẹ Amẹrika ninu eyi to ti fidi rẹmi.
Lẹyin naa lo sọ fawọn ero to n ba sọrọ pe, ki wọn yabo ile aṣofin nibi ti wọn ti n fi ontẹ lu Joe Biden gẹgẹ bi aarẹ tuntun, ti Amerika ṣẹṣẹ dibo yan.
Ìgbákejì ààrẹ, tètè yọ Trump nípò, bí bẹ́ẹ̀ kọ́... Ilé aṣòfin Amẹ́ríkà yarí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Olori ile aṣofin ilẹ Amẹrika, Nancy Pelosi ti bẹrẹ igbesẹ lati mu ki igbakeji aarẹ, Mike Pence ṣiṣẹ lori yiyọ aarẹ Donald Trump nipo.
Igbesẹ yiyọ aarẹ naa nipo ko sẹyin ipa to ko ninu wahala to waye nile aṣofin apapọ orilẹede Amẹrika lọsẹ to kọja.
Ireti wa pe awọn aṣofin yoo gbe aba kan kalẹ ninu eyi ti wọn yoo ti rọ igbakeji aarẹ Mike Pence pe, ko gbe igbesẹ yiyọ aarẹ nipo ni ibamu pẹlu alakalẹ atunṣe ofin ikarundinlọgbọn ilẹ Amẹrika.
Atunse ofin naa, ti wọn pe ni 25th amendment lo kede pe aarẹ ko si ni ipo ilera to tọ lati maa tukọ orilẹede naa.
Amọṣa, iroyin n sọ pe ọgbẹni Mike Pence ko fara mọ aba naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Amọ bi Pence ba kọ lati ṣe bẹẹ, awọn aṣofin latinu ẹgbẹ oṣelu Democrat yoo dibo lati yọ Aarẹ Trump, nitori bo se sọ fawọn ololufẹ rẹ lati wọde lọ si ile aṣofin apapọ orilẹede naa, ti wọn si kọlu ibẹ lọsẹ to kọja.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kí ló ma n fa Àkúfà nílẹ̀ Yorùbá, àti ọ̀nà àbáyọ?
- Ìwádìí BBC rèé lórí ìjà APC tó fẹ́ gbẹ̀mí Sẹ́nátọ̀ l‘Osun
- Ìlú tuntun tó kún fún ohun àdáyébá láìsí ọkọ̀ tàbí òpópónà ń bọ̀ ní Saudi Arabia
- Mo ti gba ọmọ Igbo tó ń wá bàbá rẹ̀ bí ọmọ, kó má ba à pa ara rẹ̀ - Iba Oluyole
- Lẹ́yìn ọgọ́rùn ún ọjọ́ tí wọn ti Lekki Toll Gate pa, ẹ wo owó gọbọi tíjọba Eko ń pàdánù
- Ẹ́ ràgà bo ìṣọ̀kan Nàíjíríà, ìyàpà le mú ìṣẹ́ àwọn akọni wa já sásán - Osinbajo
- Orí kó Sẹ́nátọ̀ Orilowo yọ lọ́wọ́ ikú lọ́jọ́ Àìkú
- Kí ló ń pa ẹbí Orisabunmi lọkọ́ọ̀kàn, àkúfà ni àbí àmúwá Ọlọ́run?
- August Agboola Brownie, ọmọ Yorùbá tí wọ́n n wárí fún ní Poland
Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Democrat ati awọn miran lẹgbẹ oṣelu Republican n na ika alebu si Aarẹ Trump pe, oun lo wa nidi ikọlu naa nipa awọn ọrọ to sọ nibi ipade itagbangba kan to ti n fi ẹsun eru ibo kan, laini ẹri kan pato to daju.
Eeyan marun un lo ku nibi ikọlu naa, ninu eyi ti ọlọpaa kan wa.
Ogunjọ oṣu kini ọdun yii ni Donald Trump yoo fi ipo aarẹ silẹ, ti Joe Biden yoo siwọle. Ọgbẹni Trump si ti sọ pe oun ko ni fara han nibi eto iburawọle sipo fun Biden.















