Trump yóò gbàlejò Buhari nílé ìjọba

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ààrẹ Mùhámádù Bùhárí yóò bá akẹgbẹ́ rẹ̀ lórílẹ̀èdè Améríkà, Donald Trump lálejò ní ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù kẹrin ní ilé funfun báláú White House nílùú Washington DC.Lásìkò àbẹ̀wò náà, àwọn olórí orílẹ̀èdè méjèèjì yóò jíròrò lórí ìdàgbàsókè ètò ọrọ̀ ajé àti gbígbógun ti wàhálà ìdúnkukùlajà mọ́ni.Ilé funfun báláú White House ni ìpàdé Bùhárí ati Trump yoo mẹ́nuba àwọn ohun tí yóò mú àǹfàní bá orílèèdè kóówa wọn.
- Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Buhari, OBJ, IBB yo fojukoju nilu Abuja
- Rex Tillerson ṣe'pade pẹlu Aarẹ Buhari
- Ààrẹ Buhari yóò ṣèbẹwò sí ìlu Ọba
Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù kẹ́rin ni Buhari kéde pé òun yóò díje lẹ́ẹ̀kejì lọ́dún 2019.








