Buhari, Minisita f'ọrọ okeere nilẹ Amẹrika, Tillerson n ṣe'pade lọwọ

Aare Buhari ati Ọgbẹni Rex Tillerson

Oríṣun àwòrán, STATE HOUSE

Àkọlé àwòrán, Tillerson wa lẹnu abẹwo rẹ akọkọ si ilẹ Afirika
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Minisita fun ọrọ ilẹ okeere lorilẹede Amẹrika, Ọgbẹni Rex Tillerson yoo lo n se ipade lọwọ pẹlu aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari lnile ijọba.

Ipade na bẹrẹ ni kete ti Aarẹ Buhari dari lati abẹwo rẹ si ipinlẹ Benue.

Bashir Ahmad oluranlowo si Aare lori ibanisọrọ ayẹlujara lo fi iroyin lede loju opo twita re.

Aare Buhari ati Ọgbẹni Rex Tillerson ninu ipade naa

Oríṣun àwòrán, STATE HOUSE

Àkọlé àwòrán, Ọgbẹni Rex Tillerson ti de ni Ethiopia, Kenya ati Chad
Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Minisita fun ọrọ ilẹ okeere lorilẹede Amẹrika, Rex Tillerson ti wa lẹnu abẹwo si ilẹ Afirika lati bi ọsẹ kan sẹyin.

Lara awọn orilẹede ti Ọgbẹni Rex Tillerson ti de ni Ethiopia, Kenya ati Chad.

Aare Buhari ati Ọgbẹni Rex Tillerson ninu ipade naa

Oríṣun àwòrán, STATE HOUSE

Àkọlé àwòrán, Ọgbẹni Rex Tillerson n pada si America lojo isegun

Ileeṣẹ iroyin Reuters wi pe ọgbẹni Rex Tillerson nge abẹwo rẹ kuru si ilẹ Africa ti yoo si pada si Washington DC ni ọjọ iṣẹgun.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: