Peter Cech agbabọọlu Arsenal ṣe ohun t'ẹnikan o ṣe ri

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aṣọle ikọ agbabọọlu Arsenal, Peter Cech lo ti ṣe ohun ti ẹnikan o ṣe ri ninu iwe itan bayi o.
Cech ti di aṣọle akọkọ ninu itan liigi premiership ilẹ Gẹẹsi ti bọọlu ko ni wọ awọn rẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ igba.
Cech to ti figbakanri sọ ile fun ikọ Chelsea fi orukọ ara rẹ sinu iwe itan pẹlu ifẹsẹwọnsẹ to waye lọjọ aiku ninu eyi ti Arsenal ti fagba han Watford pẹlu ami ayo mẹta si odo.

- Cech gba ifẹsẹwọnsẹ akọkọ ni liigi premiership ni ọjọ kẹẹdogun oṣu kẹrin ọdun 2004 ninu ifẹsẹwọnsẹ Chelsea ati Man United.
- Ni ifẹsẹwọnsẹ Chelsea ati Sunderland lọjọ kini oṣu kọkanla ọdun 2007 ni Cech ti gba ifẹsẹwọnsẹ ọgọrun lai gba goolu wọ awọn rẹ.
- Ni ifẹsẹwọnsẹ Chelsea ati Bolton lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kejila ọdun 2011 ni Cech ti gba ifẹsẹwọnsẹ aadọjọ lai gba goolu wọ awọn rẹ.
- Ni ifẹsẹwọnsẹ Chelsea pẹlu Man United, lọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹjọ ọdun 2013 ni Cech gba ifẹsẹwọnsẹ igba lai gba goolu wọ awọn rẹ.

Peter Cech darapọ mọ ikọ agbabọọlu Chelsea ni ọdun 2004 nibiti o ti gba bọọlu fun ọdun mọkanla, mejilelọgọjọ ifẹsẹwọnsẹ to gba pẹlu Chelsea lo jẹ wi pe awọn agbabọọlu alatako rẹ ko ri inu awọn rẹ gba bọọlu si.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni ọdun 2015 ni Peter Cech darapọ mọ ikọ Arsenal nibi ti o ti gba ifẹsẹwọnsẹ mejidinlogoji bayii laisi alatako to gba bọọlu wọ awọn rẹ.
Awọn aṣọle to di awọn wọn pa julọ ni liigi premiership
Peter Cech darapọ mọ ikọ agbabọọlu Chelsea ni ọdun 2004 nibiti o ti gba bọọlu fun ọdun mọkanla, mejilelọgọjọ ifẹsẹwọnsẹ to gba pẹlu Chelsea lo jẹ wi pe awọn agbabọọlu alatako rẹ ko ri inu awọn rẹ gba bọọlu si.
Ni ọdun 2015 ni Peter Cech darapọ mọ ikọ Arsenal nibi ti o ti gba ifẹsẹwọnsẹ mejidinlogoji bayii laisi alatako to gba bọọlu wọ awọn rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ifẹsẹwọnsẹ okoolerinwo ati mẹta ni Peter Cech ti gba bayii ni liigi premiership ilẹ Gẹẹsi, ninu eyi to ti gba asọle to pegede julọ fun saa liigi mẹrin ọtọọtọ.
David James, agbabọọlu ilẹẹ Gẹẹsi lo n ṣe ipo keji pẹlu ifẹsẹwọnsẹ mọkandinlaadọjọ.
Nigba to n sọrọ lẹyin ifẹsẹwọnsẹ ikọ Arsenal pẹlu Watford, Czeck ni 'Lootọ ni inu ohun dun ṣugbọn jijawe olubori ti ikọ naa jawe olubori mu inu ohun dun ju eyi lọ nitori fun igba diẹ bayii, nkan o rọgbọ fun ikọ naa".