2023 Election: Ìjọ Redeem figbe ta pé ẹbu ni ìròyìn tó ní Pásítọ̀ Adeboye faramọ́ ìyànsípò Tinubu

Tinubu ati Adeboye

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ìjọ Redeemed Christain Church of God ti jiyan ìròyìn tó gba orí ayélujára wí pé olórí ìjọ náà, Pásítọ̀ Enoch Adeboye ṣèpàdé pẹ̀lú olùdíje sípò Ààrẹ lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC, Bola Ahmed Tinubu.

Ìjọ náà ní irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni wí pé Pásítọ̀ Adeboye buwọ́lùú wí pé Tinubu ni kí àwọn ènìyàn dìbò fún níbi ètò ìdìbò ọdún 2023.

Nínú àtẹ̀jáde tí ìjọ Redeemed fi sórí ayélujára Twitter rẹ̀ ní Pásítọ̀ Adeboye àti ìjọ RCCG kò ní buwọ́lu olùdíje kankan fún ìdìbò 2023.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àtẹ̀jáde náà fi kun pé Redeemed àti Adeboye wà lábẹ́ àkóso ẹgbẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi CAN àti Pentecostal Fellowship of Nigeria, (PFN), fún ìdí èyí kò le gbẹnu àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi sọ̀rọ̀ lórí ètò òṣèlú.

Ní òpin ọ̀sẹ̀ ni ẹgbẹ́ CAN ti darí gbogbo àwọn ilé ìjọ́sìn ní Nàìjíríà láti gba àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ lámọ̀ràn láti má dìbò fún olùdíje sípò Ààrẹ kankan èyí tí wọ́n bá ti tọpinpin rẹ̀ wí pé ó lẹ́bọ lẹ́rù.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Wọ́n ní wọn kò gbọdọ̀ dìbò fún ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá ti rí pé ó ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn Boko Haram, tàbí ikọ̀ alákatakítí ẹ̀sìn kankan.

Wọ́n ní àwọn ohun tó yẹ kí àwọn ènìyàn lára ẹni tí wọ́n yóò bá dìbò fún ni wí pé ṣe olóòótọ́ ènìyàn ni, ṣe ó ní ìbọ̀wọ̀ fún òfin orílẹ̀ èdè, ṣe ẹlẹ́sìn tó le kó ara rẹ̀ ní ìjánu ni àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Àkọlé fídíò, Funke Felix Adejumo: Èmí kìí gba owó oṣù lọ́wọ́ ìjọ kankan, oníṣòwò gidi ni mi

CAN tún darí àwọn ènìyàn láti dìbò fún ẹni tí wọ́n bá rò wí pé ó le mú àyípadà òtítọ́ bá ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà.

Ẹ̀wẹ̀, àwọn ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ ọmọlẹ́yìn Kristi, YOUWICAN náà ti darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn tó ń bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú APC lórí bo ṣe yan Mùsùlùmí gẹ́gẹ́ bí olùdíje sípò Ààrẹ àti igbákejì rẹ̀.

Ní àná, ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kọkàndínlógún, oṣù Keje ni YOUWICAN ṣe ìwọ́de ní Abuja láti fẹ̀hónúhàn àti láti rọ àwọn ènìyàn láti máse dìbò fún APC.

Alaye wọn ni pe APC tí wọ́n yan mùsùlùmí ní olùdíje àti igbákejì rẹ̀, àti pé ẹgbẹ́ òṣèlú mìíràn tó bá yan ẹlẹ́sìn kan náà bí olùdíje àti igbákejì ni awn yoo kẹyin si.

Amin iyasọtọ kan

Ìyàwó Tinubu, Páṣítọ́ ni, kò lè sọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà di ilẹ̀ Mùsùlùmí - Shettima

Aworan Tinubu ati Shettima

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Igbakeji Aarẹ fun oludije ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress, Kashim Shettima ti sọrọ lori awuyewuye ti o n ja kiri lori bi ẹgbẹ oṣelu APC ṣe fa Musulumi meji kalẹ fun ipo Aarẹ ati igbakeji Aarẹ.

Shettima ni ẹni ti Asiwaju Bola Ahmed Tinubu kede gẹgẹ bi igbakeji rẹ fun eto idido Aarẹ ti yoo wa ye lọdun 2023.

Nigba ti o gba alejo fun àwọn Ọjọgbọn ninu ẹgbẹ oṣelu APC, o ni ikede oun gẹgẹ bi igbakeji Aarẹ ko le jẹ ohun ibẹru fun orilẹede Naijiria.

"Ọpọlọpọ ọrọ ni wọn ti sọ si Asiwaju Bola Ahmed Tinubu pe o ni erongba lati sọ orilẹede Naijiria di ilẹ Musulumi ni, ṣe o ti sọ idile rẹ gan di idile Musulumi na."

Àkọlé fídíò, Baba Ijesha Rape Case: Yomi Fabiyi ní òun nìkàn lòun rí ara òun tó dúró tí Baba Ijesha

Ṣugbọn ikede naa ni ko dun mọ ọpọlọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ati awọn ara ilu Naijiria ninu paapa julọ awọn ẹlẹsin Kristẹni.

Shettima ni oun ni igbagbọ pe oludije Bola Ahmed Tinubu ko ni fi aye gbaa ki orilẹede jẹ ilẹ Muslumi nikan nitori oun gan ẹlẹsin meji ni.

O wa rọ awọn ọmọ Naijiria lati ma fi ọrọ ẹsin wo Tinubu ṣugbọn ki wọn wo awọn nnkan ribiribi ti o fẹ gbe ṣe lorilẹede Naijiaria.

"Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, otitọ ni pe igbakeji rẹ jẹ Musulumi ṣugbọn iyawo rẹ Pasitọ ile ijọsin Redeemed Christian Church of God ni."

" Ko fi tipatipa mu awọn ọmọ rẹ lati ṣe ẹsin Musulumi. O jẹ gomina akọkọ ti o kọkọ gbe ile iwe fun awọn ẹlẹsin Kristẹni ti o si ran ọpọlọpọ lọwọ pẹlu."

"A ni lati wo awọn nnkan ti o wa niwaju wa, ti o si jẹ bi a ṣe gbe orilẹede Naijiria lọ siwaju."

"A gbọdọ gbe papọ lai wo ẹsin kankan, pẹlu ifẹ ni a fi gbọdọ jọ gbe papọ."

Shettima ti fi igba kan ri jẹ gomina ni ipinlẹ Borno ni apa Ila Oorun-Ariwa orilẹede Naijiria, ti o si tun jẹ Sẹnẹtọ to ṣoju ẹkun Aarin gbungbun ipinlẹ naa niluu Abuja.

Aworan Shettima

Oríṣun àwòrán, Screenshot