Ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọdé tí wọ́n bá fipá bálòpọ̀ nìyíí....

Oríṣun àwòrán, Google
Onimọ nipa eto ilera obinrin, Dokita Michael Gbala ti salaye ohun to ma n ṣẹlẹ si awọn ọmọde paapaa obinrin ti wọn ba fi ipa balopọ.
Dokita Gbala ni ewu pupọ lọ wa fun ọmọbinrin ti wọn ba fi ipa ba lopọ.
O salaye pe ọgba ti o ma n da si wọn lara pin si ọna mẹta.
Akọkọ ni ọgbẹ ni oju ara obinrin, ọgbẹ ni ọkan ati ọgbẹ yoo da silẹ ni awujọ.
Ohun tó ma ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọdé tí wọ́n bá fipá bálòpọ̀ nìyíí...
- Nigba miran oju ara ọmọde naa a faya ti yoo si nilọ iṣẹ abẹ lati di oju abẹ rẹ pada.
- A ti dagba maa lera fun ẹnikẹni ti wọn ba fi ipa ba lopọ
- Aisan kokoro le gba oju ara naa wọle, to si le farahan ni ẹṣẹkẹṣẹ abi ni ọjọ iwaju.
- Oju ara to ya lasiko ifipabanilopọ le fa ki ibalopọ ṣoro ni ọjọ iwaju
- O le fa airiọmọ bi tabi ki atibimọ ṣoro ni ọjọ ikunlẹ
- Inu awọn ọmọde naa kin n dun
- Ko kii le fi ọkan tan eniyan, paapaa ọkunrin to fi mọ ọkọ ti wọn ba fẹ
- A ti ba awọn eniyan ṣere ma n lera
- Wọn ki n ṣe daadaa ni ileewe, eleyii tun le dena ki wọn fi ileewe silẹ nitori ijakulẹ leralera.
Ki wa ni ọna abayọ si ifipabalopọ ni awujọ?
Ọnimọ nipa eto ilera naa ti ni o dara lati sakiyesi awọn ọmọde daradara ti wọn ba n dagba.
Amọ o ni o ṣeni laanu pe nigba miran, awọn to ba sun mọ awọn ọmọde wọnyii lo ma n fi ipa ba wọn lọpọ.
Nitori naa o rọ awọn obi lati tọju ọmọ wọn, ki wọn si maa farabalẹ lati gbọ wọn.
Talo kọ ọmọkunrin to dagba to bẹrẹ si ni fi ipa ba obinrin lọpọ kiri?
Bakan naa ni dokita Gbala fikun un pe o pọn dandan lati kọ ọmọ ọkunrin lati kekere ki wọn le ṣe ohun to tọ̀.
''Talo kọ ọmọkunrin to dagba to bẹrẹ si ni fi ipa ba obinrin lọpọ kiri?''
''Talo kọ ọkọ to n lu iyawo rẹ ninu ile?''
Dokita naa fikun un pe awọn obi gbọdọ ko ipa to dara lati tọ ọmọ wọn ni ọna to yẹ lati kekere.
O ni ti awọn ọmọkunrin ba gba ẹkọ, ti wọn ni ibẹru Ọlọrun ti wọn si mọ lati ṣe ohun to tọ lawujọ, ayipada yoo de, ti ihuwasi buruku yoo si dopin lawujọ.












