'Ìdí tí mo fi rán àwọn afurasí àjíǹigbe láti jí Páṣítọ́ mi gbé, mo sì ń bèrè fún owó ìtúsilẹ̀

Akẹhinsi Obinrin

Awọn afurasi ajinigbe meji ni ọwọ ileeṣẹ ọlopaa ipinlẹ Ogun ti tẹ fun ẹsun ijinigbe eyi ti wọn ṣe si Olusọ kan ti oruko rẹ n jẹ Mapai Samuel ti ijọ Zoe Family International Church, Odo Eran niluu Abeokuta.

Obinrin afurasi ajinigbe naa ti oruko rẹ jẹ, Ibikunle Opeyemi pẹlu akẹgbẹ rẹ ninu iwa ibajẹ, Kadiri Jamiu ni ileeṣẹ olopaa ṣe afihan wọn lọjọbọ ana lẹyin ti awọn olopaa gba ipe lati ofisi wọn, Aregbe divisional Headquaters pe wọn ti ji Pasitọ naa gbe.

Alukoro Ileeṣẹ olopaa, DSP Abimbola Oyeyemi ninu atésita kan ti o fi ransẹ si awọn akoroyin ni awọn afurasi ajinigbe mejeeji ni wọn wọ asọ ologun lati ma jẹ ki ọwọ olopaa tẹ wọn.

O salaye pe awọn afurasi naa ni wọn ṣe isẹ buruku lọjọru oṣe yii ni ago mẹjọ alẹ, ti ọwọ olopaa si tẹ wọn ni arọ ọjọ kẹji.

Oyeyemi ni awọn olopaa gbo pe awọn okunrin meji ninu asọ ologun, ti obinrin kan si tẹlẹ wọn nigbati wọn ṣe ikọlu si ilejọsin nigba ti pasitọ ṣe iwasu lọwọ lọjọru, ti wọn si fi tipatipa gbe pasitọ naa kuro ninu ile jọsin, ti wọn si gbe lọ si ibi ẹnikẹni ko mọ

Aworan ajinigbe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

“Ko pe ti gbe Pasitọ naa lọ ni awọn ajinigbe naa pada wa latti wa bẹrẹ fun owo itusilẹ.”

“Kete ti awọn olopaa agbegbe naa gbo si iṣẹlẹ, CPS Ikechukwu Gabriel ati awọn ọtẹlẹmuyẹ rẹ mo rile ibi iṣẹlẹ naa ti wọn ri awọn afurasi naa ni agbegbe Adigbe niluu Abeokuta.“

“Kete ti ileeṣẹ ganni wọn ni awọn afurasi ajinigbe ti o wọ asọ ologun si f’ẹsẹ fẹẹ sugbọn ọwọ tẹ meji lara wọn.”

“Ninu iforowero pẹlu wọn ni Arabinrin naa jẹwọ pe oun ati pasitọ jẹ onisowo kana, ti pasitọ si yan oun jẹ, ti o si binu lati tansẹ pẹ awọn ajinigbe naa mẹta lati wa ran lọwọ lati ji pasitọ naa gbe lati kọ lẹkọ.”

Alukoro ileeṣẹ olopaa ni kọmisana fun ieeṣẹ olopa ti paa lasẹ pe ki wọn gbe awọn lọ si ẹka to n risi ilodi si ijinigbe fun iwadi.