Ohun tó yọ kí ẹ mọ̀ nípa Gomina ipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola rèé...

Aworan Oyetola

Oríṣun àwòrán, Google

  • Isiaka Adegboyega ti wọn bi ni ilu Iragbiji, ni ijọba ibilẹ Boripe ni ipinlẹ Ọsun.
  • Gomina Oyetola lo si ile iwe girama ti Ifeoluwa Grammar School ni ilu Osogbo, ni ọdun 1972.
  • Lati ibẹ̀, O lọ si ile iwe giga ti Fasiti Ilu Eko, nibi ti o ti gba iwe ẹri ikẹkọgboye imọ ijinlẹ Bachelor of Science (Honours) ni imọ ẹkọ idojutofo ni ọdun 1978.
  • Ipinlẹ Yobe ni Oyetola ti sin ilẹ baba rẹ ni ọdun 1980 ni agbegbe Potiskum, ki o to bẹrẹ isẹ ti o yan laayo pẹlu ile isẹ adojutofo Leadway Assurance Company.
  • Ni ọdun 1990 ni Oyetola gba iwe ẹri imọ oye onimọ nipa eto ọrọ aje ni fasiti Eko kan naa.

Inyang Ekwo ni o yẹ ki olupẹjọ lo ilana ẹgbẹ lati fi aidunnu rẹ han lai wa si ileẹjọ lati wa damu wọn, to si da ẹjọ naa nu.

Iléẹjọ́ da ẹ̀sùn tó ní Oyetola kò kúnjúwọ́n láti díje gómìnà Osun lẹ́ẹ̀kejì, Ohun tó yọ kí ẹ mọ̀ nípa rẹ̀ rèé

Ileẹjọ giga ni ilu Abuja ti fagile ẹsun ti wọn pe mọ gomina ipinlẹ Osun, Adegboyega Oyetola ti ẹgbẹ oṣelu APC pe ko kunjuwọn lati dije du ipo nipinlẹ naa.

Adajọ Inyang Ekwo ni olupẹjọ, Alhaji Moshood Olalekan tẹ ofin ileẹjọ mọlẹ pẹlu ẹsun to pe naa.

O ni Adeoti to kopa ninu idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu naa to fidirẹmi , ko ni ẹsun to kunjuwọn lati sọ pe Oyetola ko pegede lati dije du ipo gomina.

Bi Oyetọla Adegboyega ṣe bẹ̀rẹ̀ Oṣelu niyii

  • Ọdun 1997 ni Oyetola darapọ mọ oselu to si pẹlu awọn to da ẹgbẹ oselu Alliance for Democracy (AD) silẹ, ni ọdun 1998, ki o to di alaga ẹgbẹ oṣelu ACN to di APC bayii.
  • Ọpọlọpọ eniyan lo ti sọ pe Oyetọla ni igi lẹhin ọgba fun isejọba gomina Rauf Aregbesọla lati ọdun mẹjọ sẹhin.
  • Oyetola to jẹ oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu APC naa lo jẹ onimọ nipa eto ìṣúná ati inawo, pẹlu ile isẹ adojutofo ti ti rẹ, Silvertrust Insurance Brokers Limited ti o da silẹ lati ọdun 1991, to si jẹ oludari fun ko o to di adari ajọ osisẹ fun gomina Aregbesola.
  • Ọdun 2018 to jẹ igba akọkọ ti yoo dije dupo labẹ ẹgbẹ oṣelu APC ni o jawe olubori gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Osun.